Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kejì 2014
Iṣẹ́ Rírán ti Jésù Krístì: Olùṣọ́ Àgùtàn Rere
Fi tàdúrà tàdúrà kọ́ ohun èlò yí, kí o sì ṣàwárí láti mọ ohun tí òó ṣalábápín. Báwo ni lílóye ti ayé àti iṣẹ́ rírán ti Olùgbàlà ṣe ńmú ìgbàgbọ́ rẹ nínú Rẹ̀ pọ̀ si àti bíbùkún àwọn tí ò ńṣètọ́jú lórí nípa abẹniwò kíkọ́ni?’ Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org
Jésù Krístì, Olùṣọ́ Àgùtàn Rere, kọ́ pé:
“Ọkùnrin wo ni nínú nyín, tí ó ní ọgọ́rún àgùtàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yíò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rún ìyókù sílẹ̀ ní ijù, tí kì yíò sì tọsẹ èyí tí ó nù lọ, títí yíò fi ríi?
“Mo wí fún nyín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ni … ayọ̀ yíò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà” (Luke 15:4, 7).
Bí a bá ṣe ńwá láti ní òye pé Jésù Krístì ni Olùṣọ́ Àgùtàn Rere, ìfẹ́ wa yíò pọ̀ si láti tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ àti láti sin àwọn tí ó ṣe àìní. Jẹ́sù sọ pé: “Èmi ni Olùṣọ́ Àgùtàn Rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. … Mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùtàn” (John 10:14–15). Nítorí ti Ètùtù Krístì, kò sí ìkọ̀ọ̀kan lára wa tí yíò sọnù láéláé tí a kò ní wá ọ̀nà wa délé (rí Luke 15).
Ààrẹ́ Thomas S. Monson sọ pé, “Tiwa ni ojúṣe náà láti ṣètọ́jú fún agbo ẹran náà. … Njẹ́ kí ìkọ̀ọ̀kan lára wa gbéra sókè láti sìn”.1
Látinú Àwọn ìwé Mímọ́
Látinú Ìtàn Wa
Elizabeth Ann Whitney, tí ó lọ sí ìpàdé kíní ti Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́, ti sọ nípa ìyípadà rẹ̀ ní ọdún 1830; “Ní kété bí mo ṣe gbọ́ ìhìnrere gẹ́gẹ́bí àwọn alàgbà ṣe wàásù rẹ̀, mo ti mọ̀ọ́ láti jẹ́ ohun ti Olùṣọ́ Àgùtàn Rere.”2 Elizabeth tẹ̀lé ohùn ti Olùṣọ́ Àgùtàn Rere, ó ṣe ìrìbọmi, ó sì gba ìfẹsẹ̀múlẹ̀.
Àwa náà pẹ̀lú lè gbọ́ ohùn ti Olùṣọ́ Àgùtàn Rere, kí a sì ṣe àbápín àwọn ìkọ́ni pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ààrẹ Monson sọ pé, Àwa ni olùgbọ̀wọ́ Olúwa níbí lórí ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú àṣẹ láti sìn àti láti gbé àwọn ọmọ Rẹ̀ sókè.”3
Gẹ́gẹ́bí olùṣọ́ àgùtàn rere ṣe ńṣàwárí àgùtàn tó sọnù jáde, àwọn òbí lè ṣàwárí lẹ́hìn ọmọ kan tí ó ti ṣáko lọ. Ààrẹ James E. Faust (1920–2007), Olùdámọ̀ràn kejì nínú àjọ Olùdarí Kínní, sọ pé: “Sí àwọn òbí oníròbìnújẹ́ ọkàn tí ó ti jẹ́ olódodo, aláápọn, àti olùgbàdúrà ní kíkọ́ ti àwọn ọmọ wọn aláìgbọ́ran, a sọ fún yín, Olùṣọ́ Àgùtàn Rere ńṣe ìṣọ́ lórí wọn. Ọlọ́run ní ìmọ̀ àti òye ti ìjìnlẹ̀ ìbànújẹ́ rẹ. Ìrètí wà.4
© 2014 by Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. Tí a tẹ̀ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/13. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/13. Translation of Visiting Teaching Message, February 2014. Yoruba. 10862 779