Ọ̀dọ́
Ìgbà Ẹ̀rùn ti Iṣẹ́ Ìsìn
Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àwọn ilé ayé ní Virginia, USA.
Ní ìgbà ẹ̀rùn kan mo lo àsìkò mi ní orílẹ̀ èdè àjèjì kan ní ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọdé tó jẹ́ abirùn. Nígbàtí tí mo kọ́ pàdé àwọn ọmọdé náà, ara mi ńgbọ̀n burúkúburúkú. Èmi kò sọ èdè wọn, ṣùgbọ́n mo nígbẹ́kẹ̀lé pé Ẹ̀mí yíò darí mi ní àwọn ìbálò mi. Gẹ́gẹ́bí mo ṣe wá mọ ọmọ kọ̀ọ̀kan, mo mọ̀ pé èdè kìí ṣe ìdènà rárá sí ìfẹ́. Mo ṣeré, rẹ́rín, àti pé mo ṣe àwọn iṣẹ́ ọnà pẹ̀lú àwọn ọmọdé náà, èmi kò lè ṣèrànwọ́ ṣùgbọ́n láti ní ìmọ̀ara ìfẹ́ pípé fún wọn. Mo rí fìrí ìfẹ́ tí Bàbá Ọ̀run ní fún àwọn ọmọ Rẹ̀, àti pé ayọ̀ náà tí ó kún ọkàn mi kò láfiwé.
Nìgbàkúgbà tí mo bá sin àwọn ẹlòmíràn, èmi kò ní ìmọ̀ara ìfẹ́ fún àwọn tí mò ńsìn nìkan ṣùgbọ́n fún Bàbá Ọ̀run pẹ̀lú. Nítòótọ́ mo ti wá mọ̀ pé “Nígbàtí ẹ̀yín bá wà nínú iṣẹ́ ìsìn arákùnrin yín, inú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run yín nìkan ni ẹ̀yin wà” (Mosiah 2:17). Èrò ti iṣẹ́ ìsìn mi, bóyá nínú àwọn iṣẹ́ ìsìn ńlá tógbòòrò tàbí nípa àwọn ìṣẹ́ kékèké ti inú rere,ti jẹ́ láti yin Ọlọ́run lógo. (rí Matthew 5:16). Mo nírètí pé bí mo ṣe ńsin àwọn ẹlòmíràn, àwọn ẹ̀nìyàn yíò jẹ́wọ́ ìfẹ́ mi fún Bàbá Ọ̀run àti Ìmọ́lẹ̀ ti Krístì tí ó ńjó nínú mi.