2014
Ìdáhùn kan sí Àdúrà Rẹ̀
Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2014


Ọ̀dọ́

Ìdáhùn kan sí Àdúrà Rẹ̀

Olùdásílẹ̀ náà ńgbé ní Gauteng, South Africa.

Ní alẹ́ ọjọ́ kan ọ̀rẹ́ kan ti ìgbàgbọ́ míràn bẹ̀ mí wò. Mo sábà máa ńdá ṣàṣàrò àwọn ìwé mímọ́, àti pé mo ti kó wọn jáde láti lọ ṣàṣàrò lálẹ́ ọjọ́ náà Mo ní ìṣílétí láti pè é láti darapọ̀ mọ́ mi fún àṣàrò ìwé mímọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀rù bà mí àti pé mo bẹ̀rẹ̀ sí ńdá ṣàṣàrò dípò èyí. Mo ti mọ̀ pé mo ti pa ṣíṣílétí ti Ẹ̀mí tì. Lẹ́hìn ìṣẹ́jú díẹ̀ mo fọgbọ́n bèèrè, “Njẹ o fẹ́ láti ṣàṣàrò àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú mi?” Láì ṣiyèméjì ọ̀rẹ́ mi fèsì, “Bẹ́ẹ̀ni.”

Nígbànáà a kà nínú Ìwé ti Mọ́rmọ́nì. Ó bèèrè àwọn ìbèèrè díẹ̀ lọ́wọ́ mi, àti pé mo lè ní ìmọ̀lára ti ìtọ́sọ́nà Ẹ̀mí bí mo ṣe dáhùn. Mo ṣe ìjẹ́rí mi nípa ti òtítọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Lẹ́hìn tí mo ti ṣe èyí, ó sọ fún mi, “Mo ti ńsọkún àti pé mo níbẹ̀rù ní gbogbo ọjọ́. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ nígbàtí o bèèrè pé kí nka àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú rẹ. Mo ní ìmọ̀lára dáradára síi báyìí. O ṣé.

Olúwa ti lò mí bí ohun èlò kan láti dáhùn àdúrà kan àti láti sin ọ̀kan tí ó ńṣe àìní lára àwọn ọmọ Rẹ̀. Mo mọ̀ pé ìṣílétí jẹ́ àṣe látọ̀dọ̀ ọlọ́gbọ́n kan, Bàbá ológo. Nígbàtí a bá gbé àwọn ẹrù wa tì sẹ́gbẹ́, à ńfàyè gbà Á láti fi agbára Rẹ̀ hàn nípa gbígbọ́ran wa.

Tẹ̀