2014
Iṣẹ́ Rírán ti Ọ̀run Jésù Krístì: Ìmọ́lẹ̀ ti Ayé
Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2014


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2014

Iṣẹ́ Rírán ti Ọ̀run Jésù Krístì: Ìmọ́lẹ̀ ti Ayé

Fi tàdúràtàdúrà ṣàṣàrò ohun èlò yí àti pé kí o ṣàwárí láti mọ ohun tí oó pín. Báwo ni lílóye ti ayé àti iṣẹ́ rírán ti Olùgbàlà yíò ṣe mú ìgbàgbọ́ rẹ nínú rẹ̀ pọ̀ si. Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Ìgbàgbọ́, Ìdílé, Ìrànlọ́wọ́

Bí a ti ńwá láti lóye pé Jésù Krístì ni ìmọ́lẹ̀ ti Ayé, a ó lè mú ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀ pọ̀ si àti pé a ó di ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Krístì ti jẹ́rí iṣẹ́ Rẹ̀ bí ayé náà” (D&C 93:2) àti pé e bèèrè kí e “gbé ìmólè yin sókè kí ólè tàn sí ayé” (3 Nephi 18:24).

Àwọn wòlíì wa bákannáà ti jẹ́rí ìmọ́lẹ̀ ti Krístì. Ààrẹ Henry B. Eyring, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú àjọ Olùdarí Gbogboògbò, ti sọ: “Ìgbà kọ̀ọ̀kan tí ẹ bá yàn láti gbìyànjú àti gbé bíi ti Olùgbàlà síi, ẹ ó lè fún ìjẹ́rí yín lókun. Ẹ ó wá ní àsíkò láti mọ̀ fúnra yín pé Ó jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ ti ayé. … Ìwọ yíò fi Ìmọ́lẹ̀ ti Krístì nínú ayé rẹ̀ han àwọn ẹlòmíràn.1

Alàgbà Quentin L. Cook ti Àpapọ̀ Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ ti jíjẹ́ ìmọ́lẹ̀ wa kan sí ayé: “A nílò láti dáàbò bo àwọn ẹbí wa, kí a sì wà ní ọ̀gangan iwájú papọ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ti onínúre ní ṣíṣẹ ohun gbogbo tí a lè ṣe láti ṣètọ́jú ìmọ́lẹ̀, ìrètí, àti ìwà ní àwọn agbègbè wa.”2

Látinú Àwọn ìwé Mímọ́

Johanu 8:12; Doctrine and Covenants 50:24; 115:5

Látinú Ìtàn Wa

Àwọn arábìnrin Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn lóní ti tèsíwájú láti di ìmọ́lẹ̀ wọ́n mú sókè.

Ní ọgọ́rin àkàsọ ti high-rise ní Hong Kong, China, arábìnrin àpọ́n kan pẹ̀lú àwọn àìlera ara—ènìyàn mímọ́ ìgbà ìkẹhìn kanṣoṣo nínú ẹbí rẹ̀—dá ilé kan sílẹ̀ tí ó jẹ́ ibi àbò èyítí òun àti àwọn àlejò ti lè ní ìmọ̀lára ti agbara ẹ̀mí. Ó tọ́jú àwọn ìwé mímọ́ rẹ̀, àwọn ìwé kíkà Ẹgbẹ́ Arannilọ́wọ́ rẹ̀, àti ìwé orin rẹ̀ sítòsí. Ó rìrìnàjò lọ sí tẹ́mpìlì láti ṣe ìlànà fún àwọn Bàbáńlá rẹ̀.3

Ní Brazil olódodo ìyá kan ńtọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ ti ìhìnrere. Àwọn orin alákọ́bẹ̀rẹ̀ kúnnú atẹ́gùn nínú ilé bíríkì pupa rẹ̀, àti àwọn àwòrán látinú Liahona ti àwọn tẹ́mpìlì, àwọn wòlíì Ọlọ́run, àti pé Olùgbàlà náà borí gbogbo ògiri. Òun àti ọkọ rẹ̀ rúbọ láti lè fi èdidi di nínú tẹ́mpìlì kí wọ́n lè bí àwọn ọmọ wọn sínú májẹ̀mú. Àdúrà rẹ̀ lemọ́lemọ́ ni pé kí Olúwa ràn án lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nínú ìmọ́lẹ̀, àti okun ti ìhìnrere.4

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Henry B. Eyring, “A Living Testimony,” Ensign or Liahona, May 2011, 128.

  2. Quentin L. Cook, “Let There Be Light!” Ensign or Liahona, Nov. 2010, 30.

  3. Àwọn Arábìnrin ní Ìjọba Mí: Ìtàn àti Iṣẹ́ ti Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ (Ọdún 2011), 20–21.

  4. Àwọn Arábìnrin ní Ìjọba Mí.

Tẹ̀