2014
Ìkórè ti Ọlọ́run
August 2014


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Gbogbogbòò, Oṣù Kẹ́jọ Ọdún 2014

Ìkórè ti Ọlọ́run

Àwòrán
Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf

Arábìnrin kan tí à ńpè ní Christa ṣiṣẹ́ fún ilé-iṣẹ́ èso kékeré kan nígbà kan rí. Ó fẹ́ràn iṣẹ́ rẹ̀ Ó jẹ́ orísun ti ìyanu ńlá gidi pé ìkọ̀kan èso tíntín tí ó ti ní okun láti yí ara rẹ̀ padà sí nkan míràn tó jẹ́ ìyàlẹ́nu gan an — kárótì kan, kábéjì kan, tàbí igi óàkì alágbára kan.

Christa fẹ́ràn láti jókó sí ìdí ẹ̀rọ kọ̀mpútà ní gbígba àwọn ìpè fún rírà àwọn èso náà àti dídáhùn àwọn ìbèèrè. Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kan ó gba ẹ̀sùn tí ó rú u lójú.

“Àwọn èso náà kò ṣiṣẹ́,”ni olùbárà náà sọ. “Mo rà wọ́n ní oṣù méjì sẹ́hìn àti pé kò sí nkankan síbẹ̀síbẹ̀.”

“Njẹ́ o gbìn wọ́n sí ilẹ̀ rere kí o sì fún wọn ní omi tì ó tó àti ìmọ́lẹ̀ òòrùn bí?” Christa bèèrè.

“Rárá, ṣùgbọ́n mo sa ipa tèmi,” olùbárà náà fèsì. Mo ra àwọn èso náà. Lẹ́hìn gbogbo èyí, wọ́n jẹ́ olùgbọ̀wọ́ láti hù.”

“Ṣùgbọ́n o kò gbìn wọ́n?”

“Ọ̀run mọ̀. Pé yíò túmọ̀ sí mímú ọwọ́ mi dọ̀tí.”

Christa ronú nípa èyí ó sì gbèrò pé a ní láti kọ àwọn ìtọ́nisọ́nà gbígbìn rẹ̀ sílẹ̀. Ó pinnu ohun tí ìtọ́nisọ́nà àkọ́kọ́ yíò jẹ́: “Ó gbọ́dọ̀ tẹ̀lé àwọn àṣẹ ọ̀gbìn fún àwọn èso náà láti gbèrú. O kò lè gbé wọ́n ka órí pẹpẹ kí o sì retí kí wọ́n hù.”

Kò pẹ́ púpọ̀ kí ẹ̀sùn míràn tó rú u lójú fi wá.

“Àwọn èso náà kò so jáde,”ni ohun tí olùbárà kan sọ pé ó ṣẹlẹ̀.

“Njẹ́ o gbìn wọ́n sí ilẹ̀ rere bí?” Christa fèsì. “Njẹ́ o fún wọn ní iye omi tó tọ́ àti ìmọ́lẹ̀ òòrùn bí?”

“Ah, bẹ́ẹ̀ni,” olúbárà náà tẹnumọ. “Mo ṣe gbogbo èyínáà – bákannáà bí ó ti ṣe sọ lára ẹrù náà. Ṣùgbọ́n wọn kò ṣiṣẹ́.”

“Njẹ́ ohunkóhun ṣẹlẹ̀ rárá bí? Njẹ́ wọ́n gbèrú?

“Kò sí ohun tó ṣẹlẹ̀,”ni olùbárà náà sọ. “Mo kàn gbìn wọ́n gẹ́gẹ́bí ẹ ṣe darí mi. Mo ńnírètí láti ní àwọn tòmátò fún oúnjẹ alẹ. Nísisìyí mo ní ìjákulẹ̀ gidigidi.”

“Dúró,” Christa fèsì. “Ṣé ò ńsọ pé o gbin àwọn èso náà lóní?”

“Máṣe jẹ́ apanilẹ́rín,” olùbárà náà fèsì. “Mo gbìn wọ́n ní ọ̀sẹ̀ kan sẹ́hìn. Èmi kò retí láti rí àwọn tòmátò ní ọjọ́ àkọ́kọ́; Mo ní sùúrù. Jẹ́ kí n sọ fún ọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbọmirin àti dídúró láárín ìgbànáà àti ìsisìnyí ni ó ti wà.”

Christa mọ̀ pé òun yíò níláti ṣe àfikún pẹ̀lú ìtọ́nisọ́nà míràn: “Àwọn èso wọ̀nyí wà ní ìbámu sí àwọn òfin ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ààyè. Tí o bá gbin àwọn èso náà ní àárọ̀ tí o sì ńretí láti jẹ àwọn tòmátò lẹ́hìnnáà ní ọ̀sẹ̀ náà, ìwọ yíò ní ìjákulẹ̀. O gbọ́dọ̀ ní sùúrù kí o sì dúró fún iṣẹ́ àdánidá láti fara hàn níwájú rẹ.”

Gbogbo rẹ̀ ńlọ déédé títí tí Christa fi gba ẹ̀sùn míràn.

“Mo ní ìjákulẹ̀ gidigidi nínú àwọn èso rẹ,” olùbárà náà bẹ̀rẹ̀. “Mo gbìn wọ́n gẹ́gẹ́bí ara ẹrù náà ṣe sọ. Mo fún wọn lómí, mo ri dájú pé wọ́n ní ìtànṣán oòrùn, mo sì dúró títí wọ́n fi mú èso ìkórè jádé nígbẹ̀hìn.”

“Ó dàbí i pé o ṣe gbogbo ohun ní ọnà tí ó tọ́,”ni Christa sọ.

“Gbogbo ìyẹn dára gidigidi,” olùbárà náà fèsì. “Ṣùgbọ́n ohun tí mo rí ni zuchini!”

“Àwọn àkọsílẹ̀ mi fihàn pé àwọn èso tí o bèèrè fún nìwọ̀nyẹn,” ni Christa sọ.

“Ṣugbọ́n èmi kò fẹ́ zucchini; Mo fẹ́ àwọn elégédé!”

“Èmi kò tẹ̀lée.”

Mo gbin àwọn èso náà sí ibi tí mo yàn fún elégédé mi — ilẹ̀ kannáà gan an tí ó mú àwọn elégédé jáde ní ọdún tó kọjá. Mo ńyin àwọn ọ̀gbìn náà lójojúmọ́, ní sísọ fún wọ́n ohun ẹlẹ́wà elégédé tí wọn yíò jẹ́. Ṣùgbọ́n dípò àwọn elégédé títóbi, roboto, tí wón sì ní àwọ̀ orombó, mo rí zucchini gúngùn aláwọ́ ewé gbà. Ní ìwọ̀n wọn púpọ̀!

Christa mọ̀ nígbànáà pé àwọn ìtọ́nisọ́nà lè má tó àti pé ó ṣe pàtàkì láti sọ ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ kan: “Èso tí ẹ bá gbìn àti àsìkò ọ̀gbìn náà ńṣè ìpinnu ìkórè.”

Òfin ti Ìkórè Náà

Àpọ́stélì Páùlù kọ́ni nípa ìkórè ti Ọlọ́run:

“Kí a máṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúrúgbìn, òhun ni yíò sì ká.

Nítorí ẹni tí o bá ńfúrúgbìn sípá ti ara rẹ̀, nípa ti ara ni yíò ká ìdibàjẹ́; ṣùgbọ́n ẹnití ó bá ńfúrúgbìn sípá ti Ẹ̀mí, nípa ti Ẹ̀mí ni yíò ká ìyè àìnípẹ̀kun.

“Ẹ má sì jẹ́ kí agara dá wa ní rere íṣe: nítorí àwa yíò ká nígbàtí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀.” (Galatians 6:7–9)

Láìpẹ́ yìí, Olúwa ti fún wa ní àfikún ọgbọ́n àti ìbojúwò sínú òfin yí tí a kò lè yí padà:

“Òfin kan wà, tí a paláṣẹ ní ọ̀run ṣíwájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti ayé yí èyítí a kò lè yípadà, lórí èyítí a sọ gbogbo àwọn ìbùkún lé—

“Àti pé nígbàtí a bá gba ìbùkún kankan látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó jẹ́ nípa ìgbọ́ran sí òfin náà lórí èyí tí a sọ̀ọ́ lé.” (D&C 130:20–21)

Ohun tí a gbìn, ní a ó ká.

Ìkórè ti Ọlọ́run jẹ́ ti ológo tí a kò lè gbèrò. Sí àwọn tó ńbọ̀wọ̀ fún Un, àwọn ọ̀pọ̀ ìbùkún Rẹ̀ nwá ní “òṣùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti amìpọ̀, àti àkúnwọ̀ sílẹ: …Nítorí òṣùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ̀n, óun ni a ó padà fi wọ̀n fún yín (Luke 6:38).

Gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ayé ti ńfẹ́ akitiyan àti sùúrù, bẹ́ẹ̀ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún ti ọ̀run. A kò lè gbé ẹ̀sìn wa sórí pẹpẹ kan kí a retí láti kórè àwọn ìbùkún ti ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n tí a bá gbìn tí a sì ńtọ́jú àwọn ọ̀págun ìhìnrere nínú ìgbé ayé ojojúmọ́ ti ẹbí wa, àfàìmọ̀ tó ga wà pé àwọn ọmọ wa yíò dàgbà sókè láti ṣàmújáde èso ẹ̀mí tó níyì ńlá fún wọn àti fún àwọn ìran tó ńbọ̀.

Ìdáhùn ti Ọlọ́run sí àwọn àdúrà wa kìí fì ìgbàgbogbo wá kíákíá — nígbàmíràn wọn kò dàbíi pé wọ́n ńbọ̀ rárá — ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ohun tí ó dára jùlọ fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Dájúdájú, lọ́jọ́ kan a ó ríi kedere síi, àti pé lọ́jọ́ náà a ó mọ ìwàrere àti inúrere ti ọ̀run.

Ní báyíì, òpin ìje wa àti ayọ̀ ńlá ni láti rìn ní ìṣísẹ̀ ti Olùkọ́ wa Olùgbàlà àti láti gbé ìgbé ayé rere àti ayé àtúnṣe kí ìlérí náà àti ojúlówó ìkórè ti àwọn ìbùkún àìlóye ti Ọlọ́run lè jẹ́ tiwa.

Ohun tí a bá gbìn, ní a ó ká.

Òfin ti ọ̀run ni ìyẹn

Ìyẹn sì ni òfin ti Ìkórè Ọlọ́run

Tẹ̀