2014
Iṣẹ Ìránṣẹ́ Àtọ̀runwá ti Jésù Krístì: Mèssíàh
August 2014


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́jọ Ọdún 2014

Iṣẹ Ìránṣẹ́ Àtọ̀runwá ti Jésù Krístì: Mèssíàh

Fi tàdúrà tàdúrà ka ohun èlò yĩ kí o sì ṣàwárí lati mọ ohun ti ìwọ níláti ṣe àbápín. Báwo ni níní òye ìgbé ayé ati ojúṣe Olùgbàlà ṣe ńfikún ìgbàgbọ́ yin ninu Rẹ̀ ati kí ẹ bùkún awọn tí ẹ nṣe olùṣọ́ lé lórí nipasẹ̀ Abẹniwò kíkọ́ni? Fún iwifunni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org

Ìgbàgbọ́, Ìdílé, Ìrànlọ́wọ́

Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ pé a lè gbé níwájú Ọlọ́run “nípa àṣepé, àti àánú, àti oore ọ̀fẹ́ ti Mèsíàh Mímọ́”(2 Nephi 2:8). Messiah jẹ́ “ọ̀rọ̀ Aramic àti Hébérù kan tí ó túmọ̀sí ‘ẹni àmì òróró náà.’ …Nínú Májẹ̀mú Tuntun a pè Jésù ní Krístì, èyí tí ìbámu Gríkì rẹ̀ jẹ́ Mèssíàh Ó túmọ̀ sí Wòlíì ẹni àmì òróró, Àlùfáà, Oba, àti Olùgbàlà.”1

Alàgbà Jeffrey R. Holland ti Àpéjọpọ̀ àwọn Àpọ́stélì Méjìlá jẹ́rí pé: “Mo mọ̀ pé [Jésù Krístì] ni Ẹni Mímọ́ Ísraẹlì, Mèssíàh náà tí yíò wá níjọ́ kan lẹ́ẹ̀kansi nínú ògo ìparí, láti jọba lórí ayé bíi Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba. Mo mọ̀ pé kò sí orúkọ̀ míràn tí a fifúnni lábẹ́ ọ̀run nípa èyítí ọkùnrin kan [tàbí obìnrin] lè nígbàlà.”2

“[Jésù Krístì] ni Olùgbàlà àti Olùràpadà ti àgbáyé,” ni Alákóso Dieter F. Uchtdorf, Olùdámọ̀ràn kejì nínú Àjọ Alákóso Kínní sọ. “Óun ni Mèssíàh náà ti ṣe ìlérí rẹ̀. Ó gbé ìgbé ayé pípé, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Òun yíò wà lẹ́gbẹ́ wa títí láé. Òun yíò ja àwọn ogun wa. Òun ni ìrètí wa; Òun ni ìgbàlà wa, Òun ni ọ̀nà náà.”3

Àfikún Àwọn Ìwé Mímọ́

John 1:38–41; 4:25–26, 40–42; 2 Nephi 6:13; 25:16–17

Láti inú Àwọn ìwé Mímọ́

Àwọn ọmọ ẹ̀hìn obìnrin ti Krístì ti jẹ́ àwọn ẹlẹ́rí ti ojúṣe Rẹ̀ bíi Mèsíàh náà. Mary Magdalene jẹ́ ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì kan. Òun ni àkọ́kọ́ tó rí “òkúta tí a ti gbé kúrò ní ẹnu ibojì” ní àárọ̀ ọjọ́ Àjíìnde ti Krístì. Òun “dúró ní òde ibi ibojì, ó ńsọkún” lẹ́hìn tí ó ti ri pé ara Rẹ̀ kò sí nínú sàréè mọ́.

Nígbànáà “Ó yí ara rẹ̀ padà, ó sì rí Jésù tó dúró, kò sì mọ̀ pé Jésù ni.

“Jésù sọ fún un pé, Arábìnrin, èéṣe tí ìwọ fi ńsọkún? tani ìwọ ńwá? Òun ṣèbí olùṣọ́gbà ní íṣe, ó wí fún un pé, Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn, sọ ibití o gbé tẹ́ e sí fún mi, èmi ó sì gbé e kúrò.

“Jésù sì wí fún un pé, Maríà Ó sì yípadà, ó sì wí fún un pé, Rabboni; èyí tí ó jẹ́, Olùkọ́ni.” Màríà mọ̀ pé Òun kìí ṣe Olùṣọ́gbà ṣùgbọ́n Jésù Krístì, Mèssíàh náà. (Rí John 20:1–17.)

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Atọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́, “Mèssíàh”; scriptures.lds.org.

  2. Jeffrey R. Holland, “Ọlọ́run Òtítọ́ kan ṣoṣo náà àti Jésù Krístì Ẹnití Ó Rán,” Liahona, Nov. 2007, 42

  3. Dieter F. Uchtdorf, “Ọ̀nà ti Ọmọ Ẹ̀hìn Náà,” Liahona, May 2009, 78.

Tẹ̀