Ọ̀dọ́
Ìṣẹ́gun nípasẹ̀ Jésù Krístì
Mo ní ìṣòro kan pẹ̀lú àjẹjù. Àwọn jíjẹun lemọ́lemọ́ mi yọrísí ọ̀pọ̀ ìyọnu ìdálẹ́bi, ìbàjẹ́, àti ìjákulẹ̀. Mo ní ìmọ̀ara àìlera nígbàtí mo tiraka láti borí ìṣòro mi.
Fún ìgbà pípẹ́ mo pa òtítọ́ náà tì pé Ètùtù ti Olùgbàlà kò gbà wá là nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ó ràwápadà ó sí ṣe wá ní pípé, àti pé èyí pàápàá wúlò fún ìwà àìpé ti àjẹjù mi tí ó hàn gbangba.
Mo pinnu láti fi ara mi fún Olùgbàlà mi. Mo gbàdúrà. Mo gba àìlera mi àti nínílò oore ọ̀fẹ́ mọ́ra ní òdodo, nígbànáà mo bèèrè lọ́wọ́ Bàbá Ọ̀run láti bùkún mi pẹ̀lú àtìlẹhìn Rẹ̀ ti ọ̀run ní ọjọ́ tí ó ńbọ̀. Ní alẹ́ náà mo ní ìmọ̀ara ìdánilójú ti Bàbá onífẹ̀ẹ́ pé Ó fẹ́ láìní òsùnwọ̀n láti ràn ọmọ Rẹ̀ lọ́wọ́ àti ti agbára tó dájú láti mú ìfẹ́ Rẹ ṣẹ.
Láti alẹ́ náà, oúnjẹ kò ní ipá ìbòmọ́lẹ̀ kannáà lórí mi mọ́. Mo mọ̀ pé Jésù Krístì ni èrèdí fún àṣeyege mi. Gẹ́gẹ́ bíi Páùlù, Mò ńkọ́ ẹ̀kọ́ pé “Èmi lè ṣe ohun gbogbo nínú Krístì ẹnití ó ńfi agbára fún mi” (Philippians 4:13). Èmi sì ńtiraka kí nmáṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ míràn láti ọ̀dọ̀ Paul: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹnití ó fi ìṣẹ́gun fún wa nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Krístì” (1 Corinthians 15:57).