2015
Wíwà Nínú Àkámọ́ Apá Àánú Rẹ̀
March 2015


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2015

Wíwà Nínú Àkámọ́ Apá Àánú Rẹ̀

Gẹ́gẹ́bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn, mo ti ńfi ìgbàkugbà ní ìmísí nípa àwọn iṣẹ́ ọnà ẹlẹ́wà àti orin. Irú àkókò kan bẹ́ẹ̀ jẹ́ nígbàtí mo dúró níwájú àwòrán kíkùn tí a ṣe lati ọwọ́ ayàwòrán ará Danish náà Frans Schwarz tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Ìrora náà nínú Ọgbà.1

Àwòrán kíkùn yí tí ẹwà rẹ̀ ní ìrora ṣe àpèjúwe Olùgbàlà ní orí ìkúnlẹ̀ nínú Ọgbà Gẹ́tsémánì. Bí Ó ṣe ńgbàdúrà, ángẹ́lì kan dúró ni ẹ̀gbẹ́ Rẹ̀, tí ó fi apá We mọ́ra jẹ́jẹ́, tí ó nfún ní ìtùnú, ìrànlọ́wọ́ ọ̀run, àti àtìlẹ́hìn.

Bí mo ṣe ńro ti àwòrán kíkùn yí pẹ́ sí, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn àti iyè mi ńwú pẹ̀lú ìmọ̀lọ́kàn ti ìkãnú àti ìmoore tí kò ṣẽ sọ. Mo lè fi ọgbọ́n gbée, ní apákan kékeré, ohun tí ó gbọ́dọ̀ ti jẹ́ lati wà níbẹ̀ bí Olùgbàlà ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìparí ńlá ti ayé ikú nípa gbígbé ẹ̀ṣẹ̀ ayé lé orí ara Rẹ̀. Ìfẹ́ àìlópin àti àánú tí Bàbá ní fún àwọn ọmọ Rẹ̀ yà mí lẹ́nu. Ìmoore tí ò jinlẹ̀ bò mí mọ́lẹ̀ fún ohun tí Ọmọ aláìlẹ́ṣẹ̀ ṣe fún gbogbo aráyé àti fún mi.

Ìrúbọ ti Ọmọ Ọlọ́run náà

Ní àsìkò yí ní ọdọọdún a ńṣe ìrántí a sì máa ńjíròrò ìrúbọ tí Jésù Krístì ṣe fún gbogbo aráyé.

Ohun tí Olùgbàlà ṣe láti Gẹ́tsémánì dé Gọ́lgótà ní ìtìlẹhìn wa kọjá agbára mi láti gbámú. Ó gbé àjàgà ẹ̀ṣẹ̀ wa lé órí ara Rẹ̀ Ó sì san ìdásílẹ̀ ayérayé ati dídè tí kìí ṣe fún ìrékọjá àtètèkọ́ṣe ti Ádámù nìkan ṣùgbọ́n bákannáà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá ti bíllíọ́nù lórí bíllíọ́nù àwọn ẹ̀mí tí ó ti gbé ilé ayé rí. Ìrúbọ ti ayérayé, mímọ́ yìí mú kí “àní Ọlọ́run, tí ó tóbi jù ohun gbogbo lọ, lati wárìrì nítorí ìrora, ati lati ṣe ẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ihò ara, ati lati fi ara àti ẹ̀mí jìyà bákannáà” (D&C 19:18).

Ó jìyà fún mi.

Ó jìyà fún yín.

Ẹ̀mí mi kún àkúnwọ́sílẹ̀ pẹ̀lú ìmoore nígbàtí mo ro ìtumọ̀ iyebíye ti ìrúbọ yí. Ó mú mi ní ìrẹ̀lẹ̀ láti mọ̀ pé gbogbo ẹnití ó bá tẹ́wọ́gba ẹ̀bùn yí tí wọ́n sì fi ọkàn wọn sí I ní wọ́n lè gbà ìdáríjì àti ìwẹ̀nùmọ́ ti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bí ó ti wù kí àbàwọ́n wọn dúdú tó tàbí bí ó ti wù kí àjàgà wọn nini lára tó.

A lè di àìlábàwọ́n àti mímọ́ lẹ́ẹ̀kan síi. A lè di ríràpadà nípa ìrúbọ ayérayé ti àyànfẹ́ Olùgbàlà wa.

Tani Yíò Tù Wá Nínú?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí nínú wa tí ó lè ní ìjìnlẹ̀ ìrírí ìjìyà tí Olúwa wa ní rárá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa yíò ní wákàtí dúdú àti ìkorò ti ara wa —àwọn àsìkò nígbàtí ìkorò àti ìbànújẹ́ wa yíó dàbíí pé ó tóbi ju èyí tí a lè gbà mọ́ra. Àwọn ìgbà míràn yíò wà nígbàtí wíwúwo àti àbámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wa yíò tẹ̀ wá mọ́lẹ̀ láìní àánú.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, tí a bá lè gbé ọkàn wa sókè sí Olúwa ní àwọn àsìkò yí, dájúdájú Òun yíò mọ̀ yíò sì ye. Òun ẹnití ó jìyà gan an láìmikàn fún wa nínú ọgbà àti lórí àgbélèbú kì yíò fi wa sílẹ̀ láì ní ìtùnú nísisìyí. Òun yíò fún wa lókun, gbà wá níyànjú, yíò sì bùkún wa. Òun yíò yí wa ká nínú apá àánú Rẹ.

Òun yíò ju ángẹ́lì lọ sí wa.

Òun yíò mú ìbùkún ìtùnú wa fún wa, ìwòsàn, ìrètí, àti ìdáríjì.

Nítorí Òun ni Olùràpadà wa.

Olùgbàsílẹ̀ wa.

Olùgbàlà aláánú wa àti Ọlọ́run olùbùkún wa.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Àlùfáà tí ó sọ̀rọ̀ ní ibi ìsìnkú ti Frans Schwarz sọ pé “iṣẹ́ ọnà rẹ̀ jẹ́ ìfifúnni ti ọ̀run ó sì dàbí pé ó yẹ ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwàásù lọ” (Emmilie Buchanan-Whitlock, “History of Artists’ Lives Gives Greater Context for Exhibit,” Deseret News, Sept. 29, 2013, deseretnews.com).