Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2015
Àwọn Ìhùwàsí ti Jésù Krístì: Ìpamọ́ra àti Sùúrù
Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yĩ kí ẹ sì wákiri lati mọ ohun ti ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní òye ìgbésí ayé ati ojúṣe Olùgbàlà yíò ṣe mú kí ìgbàgbọ́ yin nínú Rẹ̀ pọ̀ síi, ti yíò sí bùkún awọn wọnnì tí ẹ̀yin ńbójútó nípaṣẹ Ìbẹniwò Kíkọ́ni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.
Nígbàkugbà a máa ńro sùúrù bí ohun ìdákẹ́jẹ́, ìhùwà pẹ̀lẹ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí ohun tí Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf, Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ ààrẹ Ìkínní, sọ, “Sùúrù kìí ṣe fífi pẹ̀lẹ́ juwọ́sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ni kìí sìí ṣe kíkùnà láti ṣe ìṣe nítorí ti àwọn ìbẹ̀rù wa. Sùúrù túmọ̀ sí fífi aápọn dúró àti fífaradà. Ó túmọ̀ sí dídúró pẹ̀lú ohun kan … àní nígbàtí àwọn ìfẹ́ ti ọkàn wa bá fà ní ìfàsẹ́hìn. Sùúrù kìí ṣe fífaradà lásán nìkàn, ó jẹ́ fífaradà dáradára!”
Nínú ìgbé ṣaájú ayé ikú wa, Bàbá wa ọ̀run pèsè ètò kan fún wa—àwọn ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀—a sì kígbe fún ayọ̀ níti ànfàní láti wá sí ilẹ̀ ayé (wo Job 38:7). Bí a ṣe ńyàn láti mú ìfẹ́ wa wà ní ìbámu pẹ̀lú Tirẹ̀ nínú ìgbé ayé wa lórí ilẹ̀, Òun “yíò ṣe ohun èlò kan láti ara [wa] ní ọwọ́ [Rẹ̀] sí ìgbàlà ti àwọn ẹ̀mí púpọ̀” (Alma 17:11).
Ààrẹ Uchtdorf tẹ̀síwájú pé, “Sùúrù túmọ̀ sí títẹ́wọ́gba òhun èyí tí a kò lè yípadà àti dídojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìgboyà, oore ọ̀fẹ́, àti ìgbàgbọ́. Ó túmọ̀ sí níní ‘ìfẹ́ láti juwọ́ sílẹ̀ sí àwọn ohun gbogbo èyítí Olúwa ri pé ó tọ́ láti mú wá sí orí [wa], àní bí ọmọdé ṣe ńjuwọ́ sílẹ̀ fún bàbá rẹ̀’ [Mosiah 3:19]. Nígbẹ̀hìn, sùúrù túmọ̀ sí ‘dídúró gbọingbọin àti ṣinṣin, àti àiyẹsẹ̀ ní pípa àwọn òfin ti Olúwa mọ́’ [1 Nífáì 2:10] ní gbogbo wákàtí ti ojojúmọ́, àní nígbàtí ó le láti ṣe bẹ́ẹ̀.”1
Àfikún Àwọn Ìwé Mímọ́
Láti inú Àwọn Ìwé Mímọ́
Àwọn ìwé mímọ́ sọ fún wa pé ní ìgbé ayé wa lórí ilẹ̀ ayé, a níláti “ní sùúrù nínú àwọn ìpọ́njú, nítorí [a ó] ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn.” Nígbànáà Ọlọ́run fún wa ní ìlérí ìtùnú yí, “faradà wọn, nítorí, wòó, Èmi wà pẹ̀lú rẹ, àní títí di òpin àwọn ọjọ́ ayé rẹ” (D&C 24:8).
Ìtàn inú Bíbélì ìsàlẹ̀ yí ni àpẹrẹ kan ti sùúrù àti ìgbàgbọ́.
“Obìnrin kan tí ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá … ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ ti [Krístì]: lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ náà dá [dúró].
“Jésù sì sọ wípé, … Ẹnìkan ti fi ọwọ́ kàn mi: nítorí mo wòye pé agbára ti kúrò lára mi.
“Nígbàtí obìnrin náà ri pé òun kò sí ní ìpamọ́, ó wá ó ńgbọ̀n, ó sì ṣubú níwájú rẹ̀, ó sọ fun un níwájú gbogbo àwọn ènìyàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tí òun ṣe fi ọwọ́ kan an, àti bí a ṣe wo òun sàn lọ́gán.
“Ó sì sọ fún wípé, Ọmọbìnrin, tújúká: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá; máa lọ ní àláfíà” (Luke 8:43–48).
Bíi tirẹ̀, a lè rí àwọn ìbùkún àti ìtùnú, àti ìwòsàn pàápàá, bí a ṣe ńnawọ́ jáde sí Jésù Krístì—ẹnití Ètùtù rẹ̀ lè wò wá sàn.
© 2015 Láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/14. Àṣẹ ìyírọ̀padà: 6/14. Ìyírọ̀padà ti Visiting Teaching Message, March 2015. Yoruba. 12583 779