2016
Ẹ̀bí náà: Ìkéde kan sí Gbogbo Ayé
OṢù ṢẸ́rẹ́ 2016


Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọni Oṣù, Kìnní 2016

Ẹbí náà: Ìkéde kan sí Gbogbo Ayé

Fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yĩ kí o sì lépa lati mọ ohun ti o nílati ṣe àbápín rẹ. Báwo ni níní òye ẹ̀kọ́ nípa ẹbí yíó ṣe bùkún àwọn wọnnì tí ẹ nbójútó nípasẹ̀ ìbẹniwọ kíkọ́ni? Fún ìmọ̀ síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìrànlọwọ

Nípa ti ìpàdé gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ní 1995, nígbàtí Ààrẹ Gordon B. Hinckley (1910–2008) kọ́kọ́ ka Ẹbí náà: Ìkéde kan sí gbogbo ayé, Bonnie L. Oscarson, ààrẹ gbogbogbòò ti àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, sọ pé: A fi ìmoore hàn fún, a sì mọ iyì jíjẹ́ kedere, jíjẹ́ ìrọ̀rùn, àti òtítọ́ ti ìwé onífihàn yìí. … Ìkéde náà lórí ẹbí ti di atọ́nà fún ṣíṣe ìdájọ́ ìhùwàsí ti gbogbo ayé, mo sì jẹ́rìí pé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí a gbé kalẹ̀ … jẹ́ òtítọ́ lóní bí wọ́n ṣe wà nígbàtí wọ́n fún wa láti ọwọ́ wòlíì Ọlọ́run kan ní bíi ogún ọdún sẹ́hìn.1

Láti inú ìkéde ẹbí, Carole M. Stephens, olùdámọ̀ràn kínní nínú àjọ ààrẹ gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣe àfikún, a kọ́wa, Ní ibi ìṣíwájú ayé ikú, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ẹ̀mí mọ̀ wọ́n sì nsin Ọlọ́run bíi Bàbá wọn Ayérayé2 …

“… Ìkọ̀ọ̀kan wa jẹ́ ara, a sì nílò wa nínú, ẹbí ti Ọlọ́run.”3

A ńgbé ní ìgbà kan tí àwọn òbí gbọ́dọ̀ dáàbò bo ilé wọn àti ẹbí wọn. Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí Gbogbo Ayé lè tọ́wa sọ́nà.

Àfikún Àwọn Ìwé Mímọ

Mòsíàh 8:16–17; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 1:38

Àwọn ìtàn Alààyè

Lee Mei Chen Ho láti wọ́ọ̀dù Tao Yuan kẹ́ta, Èèkàn Tao Yuan Taiwan, sọ pé ìkéde náà ti kọ́ òun pé ìbáṣepọ̀ ẹbí máa nṣè ìrànwọ́ láti mú àwọn ìwà ti ọ̀run bíi ìgbàgbọ́, sùúrù, àti ìfẹ́ gbèrú si. ‘Nígbàtí mo bá gbìyànjú láti tún ara mi ṣe ní ìbámu sí ìkéde náà, mo lè ní ìrírí ìdùnnú tootọ́, ni ó sọ.4

Barbara Thompson, ẹni tí ó wà níbẹ̀ nígbàtí a ka ìkéde náà fún ìgbà àkọ́kọ́ tí ó sì sìn gẹ́gẹ́bíi Olùdámọ̀ràn kan nínú àjọ ààrẹ gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, sọ pé: Mo ronú fún àsìkò díẹ̀ pé [ìkéde ẹbí náà] lódodo kò fi bẹ́ẹ̀ nííṣe sí mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò tíì ṣe ìgbeyàwó tí èmi kò sì tíì ní àwọn ọmọ kankan. Ṣùgbọ́n ní ojú ẹsẹ̀ kíákíá mo rò ó, Ṣùgbọ́n ó níí ṣe sí mi. Èmi jẹ́ ọmọ ẹbí kan Èmi jẹ́ ọmọbìnrin kan, arábìnrin kan, auntí kan, ìbátan kan, ọmọ àbúrò tàbí ẹgbọ́n ẹnìkan, àti ọmọ ọmọ kan. … Àní tí èmi bá jẹ́ ọmọ ẹbí mi kanṣoṣo tí ó kù lààyè, síbẹ̀ mo jẹ́ ọmọ ẹbí ti Ọlọ́run.5

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Bonnie L. Oscarson, Olùdá ààbò bo ti Ìkéde Ẹbí, Liahona, May 2015, 14–15.

  2. ẸbíNáà Ìkéde kan sí Gbogbo Ayé, Liahona, Nov. 2010, 129.

  3. Carole M. Stephens, Ẹbí Jẹ́ ti Ọlọ́run, Liahona, May 2015, 11.

  4. Nicole Seymour, Ẹbí náà: Ìkéde kan sí Gbogbo Ayé dé òkúta ìsàmì ọdún mẹ́wá, Liahona, Nov. 2005, 127.

  5. Barbara Thompson, in Àwọn Ọmọbìnrin nínú Ìjọba mi: Ìwé Ìtàn náà àti Iṣẹ́ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ (2011), 148.

GbèròÈyí

Báwo ni Ẹbí náà ṣe jẹ́: Ìkéde kan sí gbogbo ayé ìwé kan fún ọjọ́ wa?