Ọ̀dọ́
Ìpìlẹ̀ Kan fún Ẹ̀rí Mi
Olùkọwé ńgbé ní Idaho, USA
Nígbàtí mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún, ọ̀rẹ́ kan fi ara hàn ní ibùgbé wa pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Láàrin oṣù kan ti ìbánisọ̀rọ̀ àkọ́kọ́, gbogbo ìbéèrè mi ti jẹ́ dídáhùn ní yékéyéké. Mo ní ìmọ̀lára ti Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó jẹ́rìí sí jíjẹ́ òtítọ́ ti àwọn ọ̀rọ̀ náà nípa Ìmúpadà bọ̀ sípò. Kò dàbíi ohunkóhun tí mo ti ní ìmọ̀lára rẹ̀ rí tẹ́lẹ̀, mo sì mọ̀ pé gbogbo rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní ìrírí ìkọ̀sílẹ̀ àti àtakò ju ti àtẹ̀hìnwa lọ. Mo ní ìmọ̀lára ànìkanwà, àárẹ̀, ati ìdààmú. Bí mo bá nṣe ohun tí ó tọ́, kíníṣe ti mo fi nní ìdojúkọ ìpọ́njú púpọ̀ bẹ́ẹ̀? Èmi kò ní òye bí àwọn àdánwò mi ṣe jẹ́ fún rere mi. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kọ́mi lati gba ààwẹ̀ àti àdúrà, àní ní ààrin méjì ọjọ́ ilé ìwe kan. Nígbàtí àwọn nkan bá kọ́já àfaradà èmi a tú ọkàn mi jáde ati pé ní ojú ẹsẹ̀ emi a sì ní ìmọ̀lára ìtùnú ti Ẹ̀mí.
Ọ̀sẹ̀ ìrìbọmi mi kún fún àwọn àdánwò. Ọ̀gá mi halẹ̀ lati dámi dúró bí èmi kò bá pa ìrìbọmi tì lati dí ààyè fún ẹnikan, mo bá ara mi ní ilé ìwòsàn pẹ̀lú òkúta inú kindìnrín, àwọn òbí mi sì ní kí nfi ilé wa sílẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ohun púpọ̀ tí ó kọ́já agbára mi, ohun kan, ṣoṣo ti mo le ṣe ni lati yí sí Olúwa.
Olukúlùkù àwọn àdánwò náà ni ó yí padà fún ànfààní mi. Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ lati kọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìhìnrere, èyítí ó pèsè ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ fúnmi fún ẹ̀rí mi.