2016
Bíbalẹ̀ Láìléwu nínú Ìjì Líle
OṢù Èrèlè 2016


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kejì Ọdún 2016

Bíbalẹ̀ Láìléwunínú Ìjì Líle

Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf

Ní ìgbà díẹ̀ sẹ́hìn, Ìyáwó mi, Harriet, àti èmi, wà ní pápá ọkọ̀ òfurufú kan tí a nwo awọn ọkọ̀ òfurufú nlá-nlá bí wọn ti nbalẹ̀. Ó jẹ́ ọjọ atẹ́gùn púpọ̀, ìyàngbò afẹ́fẹ́ líle nfi ìbínú kọlu ọkọ̀ òfurufú tó nbọ̀, èyítí ó nmú kí ikọ̀ọ̀kan wọn fì kí ó sì gbọ̀nrìrì nígbà bíbọ̀ náà.

Bí a ṣe nṣe àkíyèsí yìí láàrin ìṣẹ̀dá ati ẹ̀rọ, ọ̀kàn mi padà lọ sí ibi ìkẹ́kọ̀ọ́ fífò tèmi ati àwọn ẹ̀kọ́ ti mo kọ́ níbẹ̀—ati pé lẹ́hìnnáà tí mo tún kọ́ àwọn awakọ̀ òfurufú mìíràn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́.

Maṣe bá àwọn ohun ìdarí jà ní ìgbà ìjì líle, ni mo máa nsọ fún wọn. Dúró jẹ́ẹ́; maṣe ṣe àṣejù. Jẹ́kí ojú rẹ tẹ̀ mọ́ orí ìlà ààrin pápákọ̀ òfurufu. Bí o bá yẹ̀ kúrò ní ipa ọ̀nà tí o fẹ́ gbà wá, ṣe àwọn àtúnṣe kíákíá ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìwọ̀n àtúnṣe Gbẹ́kẹ̀lé agbára ọkọ̀ òfurufú rẹ. Wakọ̀ jáde kúrò nínú ìjì líle náà.

Àwọn onírírí awakọ̀ òfurufú ní òye pé wọn kò le fi gbogbo ìgbà ní ìdarí lórí àwọn ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní àyíká wọn. Wọn kò lè dá ìjì líle dúró ṣáá ni. Wọn kò le mú kí òjò tàbí yìnyín pòórá. Wọn kò le mú kí afẹ́fẹ́ dáwọ́ fífẹ́ dúró tàbí kí wọn ó yí ibití ó nfẹ́ sí padà.

Ṣùgbọ́n bákannáà wọ́n ní òye pé ó jẹ́ àṣìṣe láti bẹ̀rù ìjì líle tàbí àwọn afẹ́fẹ́ tó lágbára---ati pàápàá lati di jínní-jínní nípa wọn. Ọ̀nà lati balẹ̀ láìléwu nígbàtí àwọn ipò kò bá dára tó ni láti dúró lóríi ọ̀nà tí ó tọ́ àti ipa ọ̀nà rírìn geere bí ó ti ṣeéṣe tí ó sì dára tó.

Bí mo ṣe nwo ọkọ̀ òfurufú kan lẹ́hìn òmíràn tí ó nṣe ìgbaradì ìparí tí mo sì nrántí àwọn ẹ̀kọ́ tí a kọ́ latí inú àwọn ọdún mi bíi awakọ̀ òfurufú, mo ròó bóyá kò sí ẹ̀kọ́ nínú èyí fún ìgbé ayé wa ojoojúmọ́.

Nígbàmíràn nkan kìí lọ ní ọ̀nà tiwa. Nígbàmíràn nkan kìí lọ ní ọ̀nà tiwa. A lè ní ìmọ̀lára ìjọlójú ati títì kiri nípa ìjì líle ti ìjákulẹ̀, iyèméjì, ẹ̀rù, ìbànújẹ́, tàbí ìdààmú.

Láàrin àwọn àkókò wọ̃nnì, ó rọrùn lati há sínú gbogbo ohun tí ó nlòdì ati lati fi àwọn ìdààmú wa sí ààrin àwọn ìrònú wa. Ìdánwò náà jẹ́ lati tẹjúmọ́ àwọn àdánwò tí a ndojúkọ dípò títẹjúmọ́ Olùgbàla ati ẹ̀rí wa nípa òtítọ́.

Ṣùgbọ́n èyíinì kìí ṣe ọ̀nà tí ó dára jùlọ lati tukọ̀ láàrin àwọn ìpèníjà wa ninú ayé.

Gẹ́gẹ́bí awakọ̀ òfurufú tí ó ní ìrírí kìí ṣe tẹ ojú rẹ̀ mọ́ ìjí ṣùgbọ́n mọ́ ààrin ọ̀na ìsáré ati ọ̀gangan ibi dídára láti balẹ̀ìbalẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni a níláti fi ìtẹjúmọ́ wa sí orí ààrin ìgbàgbọ́ wa—Olùgbàla wa, ìhìnrere Rẹ̀, ati ètò Baba wa Ọ̀run —ati ní oríi ìfọjúsí wa dé ìparí—lati padà láìléwu sí òpin ìrin wa ti ọ̀run A níláti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run kí a sì fi dídúró ní ọ̀nà jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn ṣe ìtẹjúmọ́ àwọn ìgbìyànjú wa. A níláti tẹ ojú, ọkàn, ati iyè inú wa mọ́ orí gbigbé ìgbé ayé lọ́nà tí a mọ̀ pé ó yẹ.

Fífi ìgbàgbọ́ ati ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Baba Ọ̀run hàn nípa fífi tayọ̀tayọ̀ pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ yíó mú ìdùnnú wá fún wa ati ògo. Àti pé bí a bá dúró sí ipa ọ̀nà náà, a ó la èyíkéyìí ìjì líle já—bí ó ti wù kí ó dàbí ẹnipé ó le tó–a ó sì padà láìléwu sí ibùgbé wa ọ̀run.

Bóyá àwọn ojú ọ̀run ní àyíká wa ṣe kedere tàbí ó kún fún ìkuukuù tí ó nhalẹ́, bíi ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì, a kọ́kọ́ nlépa ìjọba Ọlọ́run ati òdodo Rẹ̀, ní mímọ̀ pé bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo ohun yòókù tí a bá nílò ni a ó pésé nípari (wo Matthew 6:33).

Irú ẹ̀kọ́ pàtàkì ti ìgbe ayé wo ni èyí!

Bí a bá ṣe tara sí nipa àwọn ìṣòro wa, àwọn ìtiraka wa, àwọn iyèméjì wa, ati àwọn ẹ̀rù wa, bẹ́ẹ̀ ni àwọn nkan lè di líle sí. Ṣùgbọ́n bí a bá ṣe tẹjúmọ́ òpin ìrìn wa ti ọ̀run sí ati ní orí àwọn ayọ̀ ti títẹ̀lé ipa ọ̀nà ti ọmọ ẹ̀hìn–níní ìfẹ́ Ọlọ́run, sísìn àwọn aládùúgbò wa—bẹ́ẹ̀ ní yíò fi ṣeéṣe fúnwa sí lati ṣe àṣeyọrí títukọ̀ láàrin àwọn àkókò ìdààmú ati ìjì líle.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, bí ó ti wù kí líle afẹ́fẹ́ ti wíwà ní ayé ikú wa ṣe lè kígbe tó ní àyíká wa, ìhìnrere Jésù Krístì yío pèsè ipa ọ̀nà tí ó dára jùlọ sí bíbalẹ̀ láìléwu sínú ìjọba Bàbá wa Ọ̀run.

Ìkọ́ni láti inú Ọrọ yí

Ààrẹ Uchtdorf gbàwá nímọ̀ràn lati gbẹ́kẹlé Ọlọ́run kí a sì fi dídúró ní ọ̀nà jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn ṣe ìtẹjúmọ́ àwọn ìyànjú wa. Ẹ gbèrò lati béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ẹ nkọ́ bí wọ́n ṣe ti dúró ní títẹjúmọ́ òpin ìrìn wa tí ọ̀run ati ní orí àwọn ayọ̀ ti títẹ̀lé ipa ọ̀nà ti ọmọ ẹ̀hìn ní àwọn ìgbà tí wọ́n tí dojúkọ àwọn àdánwò. Ẹ le pè wọ́n lati ronú nípa àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi le tẹjú mọ́ ẹ̀rí wọn ati ní orí Krístì ní àkókò ìṣòro àti lati fi tàdúrà-tàdúrà pinnu bí wọn ó ṣe ṣe àmúlò ìkan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn èrò wọ̃nnì nínú ìgbé ayé wọn.