2016
Ìgbeyàwó jẹ́ ìlàna ti Ọlọ́run
OṢù Èrèlè 2016


Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kejì Ọdún 2016

Ìgbeyàwó jẹ́ Ètò ti Ọlọ́run

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yĩ kí ẹ sì lépa lati mọ ohun ti ẹ ó ṣe àbápín rẹ̀ Báwo ni níní òye “Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí Gbogbo Ayé” yíó ṣe mú ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run pọ̀ síi kí ó sì bùkún àwọn wọ̃nnì tí ẹ nbójútó nípasẹ̀ ìbẹniwò kíkọ́ni. Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìrànlọwọ

Àwọn Wòlíì, àwọn àpóstélì, ati àwọn olórí tẹ̀síwájú lati fi tọ̀wọ̀-tọ̀wọ̀ kéde pé ìgbeyàwó láàrin ọkùnrin ati obìnrin jẹ́ ètò Ọlọ́run ati pé ẹbí jẹ́ ohun tí ó wà ní ààrin èrò Ẹlẹ́dàá.”1

Alàgbà D. Todd Christofferson ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá sọ pé: Ẹbí kan tí a gbékalẹ̀ lóríi ìgbeyàwó láàrin ọkùnrin kan ati obìnrin máa npèsè ìpìlẹ̀ tí ó dára jùlọ fún ètò ti Ọlọ́run lati gbilẹ̀. …

“… Kìí ṣe bóyá àwa tàbí ẹ̀dá míràn nínú ara ikú ni ó le yí ètò ìdàpọ̀ àtọ̀runwá yìí padà”2

Bonnie L. Oscarson, ààrẹ gbogbogbòò ti àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, sọ pé: “Olukúlùkù, bí ó ti wù kí ọ̀rọ̀ ìgbeyàwó wọn rí tàbí iye ọmọ wọn, le jẹ́ olùgbèjà ètò Ọlúwa tí a ṣe àpèjúwe rẹ̀ nínú ìkéde ẹbí. Bí ó bá jẹ́ ètò ti Olúwa, ó nílati jẹ́ ètò tiwa bákannáà!”3

Alàgbà Christofferson tẹ̀síwájú: “Díẹ̀ nínú yín ni a fi ìbùkún ìgbeyàwó pọ́n lójú fún àwọn ìdí bíi àìsí ìrètíi ṣíṣeéṣe, fífàmọ́ irú ẹ̀yà-ara kannáà, àléébù àfojúrí tàbí tinú, tàbí nítorí ẹ̀rù ìjákulẹ̀ lásán. … Tàbí o ti lè se ìgbeyàwó, ṣùgbọ́n ìgbeyàwó náà parí. … Díẹ̀ ninu yín tí ó ṣe ìgbeyàwó kò le bí àwọn ọmọ. …

“Àní bẹ́ẹ̀ ni …olukúlùkù le lọ́wọ́ sí ṣíṣe àfihàn ètò àtọ̀runwá ní ìran kọ̀ọ̀kan.”4

Àfikún Àwọn Ìwé Mímọ

Gẹ́nẹ́sísì 2:18-24; Kọrintì Kínní 11:11; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 49:15-17

Àwọn Ìtàn Alààyè

Arákùnrin Larry M. Gibson, olùdámọ̀ràn kínní nínú àjọ ààrẹ ti Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin ní ìgbà kan rí, rantí ìgbà tí Shirley, ìyàwó rẹ̀ nísisìyí, sọ pé:

”Mo ni ìfẹ́ rẹ nítorípé mo mọ̀ pé o ní ìfẹ́ Olúwa ju bí o ṣe ní ìfẹ́ mi. …

Ìdáhùn yìí la ọkàn mi. …

“… [Àti pé] Mo fẹ́ kí ó máa fi ìgbà gbogbo ní ìmọ̀lára pé mo ní ìfẹ́ Olúwa ju gbogbo ohun mìíràn.”5

Alàgbà David A. Bednar ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bèèrè: “Olúwa Jésù Krístì jẹ́ ọ̀gangan pàtàkì nínú ìbáṣepọ̀ ìgbeyàwó onímájẹ̀mú. … [Ẹ ròó pé] a gbé Olùgbàlà sí òkè ténté igun mẹ́ta [kan], pẹ̀lú obìnrin kan ní ìsàlẹ̀ igun kan ati ọkùnrin kan ní ìsàlẹ̀ igun kan tó kù. Nísisìyí gbèrò nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìbáṣepọ̀ láàrin ọkùnrun ati obìnrin náà tí wọ́n nwá sí ọ̀dọ̀ Krístì bí ẹni kọ̀ọ̀kan tí wọ́n sì nwá déédé, tí wọ́n sì nlàkàkà lati jẹ́ pípé nínú Rẹ̀ (Moroni 10:32). Nítorí ti ati nípasẹ̀ Olùràpadà, ọkùnrin àti obìnrin náà yíó túbọ̀ sún mọ́ra papọ̀.”6

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí Gbogbo Ayé, Liahona, Nov. 2010, 129.

  2. D. Todd Christofferson, “Kíni ìdí Ìgbeyàwo,Kíni ìdí Ẹbí,” Amọ̀nà, May 2015, 52.

  3. Bonnie L. Oscarson, Olùdá ààbò bo ti Ìkéde Ẹbí, Liahona, May 2015, 15–15.

  4. D. Todd Christofferson, Kíni ìdí Ìgbeyàwo,Kíni ìdí Ẹbí, 52.

  5. Larry M. Gibson, Ṣíṣe Ojúṣe Àyànmọ́ Ayérayé Wa, Ensign, Feb. 2015, 21-22.

  6. David A. Bednar, Ìgbeyàwó ṣe Pàtàkì sí Ètò Ayérayé Rẹ̀,” Liahona, June 2006, 54.

Gbèrò Èyí

Báwo ni èmi bíi ẹnìkan ṣe ntiraka deedé láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì?

Tẹ̀