Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọni Oṣù Kẹfà 2016
Àwọn Ìlànà Tẹ́mpìlì ati Àwọn Májẹ̀mú
Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní óye Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí gbogbo ayé yíò fi mú kí ìgbàgbọ yín nínú Ọlọ́run pọ̀ si kí ẹ sì bùkún àwọn wọnnì tí ẹ nṣe ìtọjú lórí wọn nípa ìbẹniwò kikọni? Fún ìwífúnni síi lọ sí reliefsociety.lds.org
Gbogbo àwọn ìlànà tí ó ṣe dandan fún ìgbàlà àti ìgbéga máa nbá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run wá. Ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ túmọ̀ sí yíyàn láti so ara wa papọ̀ mọ́ Bàbá wa ní Ọ̀run àti Jésù Krístì, ni Linda K. Burton, Ààrẹ gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ sọ.1
Alàgbà Neil L. Andersen ti Iyejú Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ pé, Olúwa sọ pé, Nínú àwọn ìlànà … agbára ìwà ọ̀run ńfi ara hàn.
Àwọn àkànṣe ìbùkún wà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún gbogbo ẹni yíyẹ tí a bá rìbọmi, tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọ́n sì ńṣe alábápín oúnjẹ Olúwa déédé.2
Ìgbàtí àwọn ọkùnrin àti obìnrin bá lọ sí tẹ́mpìlì, ni Alàgbà M. Russel Ballard ti Iyejú Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ, àwọn méjèèjì ti gbé ẹ̀bùn wọ̀ pẹ̀lú irú agbára kannáà, tí íṣe agbára oyè àlùfáà …
… Gbogbo àwọn ọkùnrin àti obìnrin ní ẹ̀tọ́ sí agbára yí fún ìrànlọ́wọ́ nínú ìgbé ayé wọn … Gbogbo àwọn tí wọn ti dá májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú Olúwa tí wọ́n sì bu ọlá fún àwọn májẹ̀mú wọ̃nnì, ní ẹ̀tọ́ láti gba ìfihàn ara ẹni, láti jẹ́ alábùkún fún nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn àngẹ́lì, láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, láti gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere, àti, ní ìgbẹ̀hìn, láti jùmọ̀ di ajogún pẹ̀lú Jésù Krístì sí gbogbo ohun ti Bàbá ní.3
ÀwọnÌwéMímọníÀfikún
Àwọn Ìtàn Alààyè
Ní 2007, ọjọ́ kẹ́rin lẹ́hìn ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ ríru títóbi ní Peru, Alàgbà Marcus B. Nash ti àwọn àádọ́rin pàdé Ààrẹ Ẹ̀kà Wenceslao Conde àti ìyàwó rẹ̀, Pamela. “Alàgbà Nash bèèrè lọ́wọ́ Arábìnrin Conde bí àwọn ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe wà. Pẹ̀lú ẹ̀rín, ó fèsì pé nínú ìwàrere Ọlọ́run gbogbo wọn wà ní ìlera àti àìléwu. Ó bèèrè nípa ilé àwọn Conde.
“’Ó ti lọ, ni ó sọ jẹ́jẹ́.
“… Àní síbẹ̀síbẹ̀, Alàgbà Nash ṣe àkíyèsí, o nrẹ́rín bí a ṣe nsọ̀rọ̀.’
“’Bẹ́ẹ̀ni, ó sọ pé, Mo ti gbàdúrà mo sì wà ní àláfíà. A ní gbogbo ohun tí a nílò. A ní ara wa, a ni àwọ̀n ọmọ wa, a sì ti fi èdidì di nínú tẹ́mpìlì, a sì ní Ìjọ Ìyanu yí, a sì ní Olúwa. A lè dìde lẹ́ẹ̀kansi pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa. …
“Kíni ohun náà nípa ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run tí ó nfún wa ní agbára láti rẹ́rín nínú ìnira, láti yí ìpọ́njú padà sí ayọ̀ ìṣẹ́gun …?”
“Orísun náà ni Ọlọ́run. Ẹ̀tọ́ wa sí agbára náà jẹ́ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Rẹ̀.”4
© 2016 by Intellectual Reserve, Inc.All rights reserved. A tẹ̀ẹ́ ní USA Àṣẹ Gẹẹsì 6/15. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/15 Àyípadà Èdè ti Visiting Teaching Message, June 2016. Yoruba 12866 779