2016
Àwọn Ẹbí Wà Títíláé
OṢù Ògún 2016


Àwọn Ọmọdé

Àwọn Ẹbí Wà Títíláé

Nítorí ti Ètùtù Jésù Krístì àti ìmúpadàbọ̀sípò àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà, a lè gbé pẹ̀lú àwọn ẹbí wa títíláé! Kíni ẹ nífẹ́sí nípa ẹbí yín? Tẹ̀lé àwọn ìtọ́ni wọ̀nyí láti ṣe ẹ̀gbà pépà yí láti ṣe ayẹyẹ ẹbí yín.

  1. Ká ẹyọ pépà ní ààbọ̀ léèmejì kí ẹ lè ní ọ̀kan tẹ́ẹ́rẹ́ gígùn.

  2. Ya àwòrán ẹnì kan pẹ̀lú àwọn ọwọ́ tí ó nà dé igun kíká náà.

  3. Gé ẹni náà jade. Máṣe ge níbi tí àwọn ọwọ́ náà ti kan igun kíká náà.

  4. Tú u sílẹ̀ Ẹ kọ tàbí ya àwórán ohun kan tí ẹ nífẹ́sí lára ọmọlẹ́bí kọ̀ọ̀kan.

  5. Lẹ ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀gbà papọ̀ tí ẹ bá ní ẹbí tí ó tóbi jù!

Tẹ̀