2016
Títọ́jú Àwọn Ẹbí Papọ̀
OṢù Ògún 2016


Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́jọ Ọdún 2016

Títọ́jú Àwọn Ẹbí Papọ̀

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní óye Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí gbogbo ayé yíò fi mú kí ìgbàgbọ yín nínú Ọlọ́run pọ̀ si kí ẹ sì bùkún àwọn wọnnì tí ẹ nṣe ìtọjú lórí wọn nípa ìbẹniwò kikọni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìrànlọwọ

Ọkọ kan àti ìyàwó ní ojúṣe ọ̀wọ̀ láti nífẹ́ àti láti bojútó ara wọn àti àwọn ọmọ wọn. ”1 “Ilé ní láti jẹ́ ibi àyẹ̀wò ti Ọlọ́run fún ìfẹ́ àti iṣẹ́ ìsìn,” ni Ààrẹ Russell M. Nelson, Ààrẹ ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ.

“Bàbá wa Ọ̀run fẹ́ kí àwọn ọkọ àti àwọn ìyàwó jẹ́ olóótọ́ sí ara wọn àti láti ṣe àkàsí kí wọn ó sì tọ́jú àwọn ọmọ wọn bíi ohun ìní kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa.”2

Nínú Ìwé Mọ́rmọ́nì, Jákọ́bù sọ pé ìfẹ́ tí àwọn ọkọ ní fún àwọn ìyàwó wọn, ìfẹ́ tí àwọn ìyàwó ní fún àwọn ọkọ wọn, àti ìfẹ́ tí àwọn méjèèjì ní fún àwọn ọmọ wọn wà ní àárín àwọn ìdí tí àwọn ará Lámánì ṣe jẹ́ olódodo ní ìgbà kan ju àwọn ará Nífáì lọ (wo Jákọ́bù 3:7).

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí ó dárajùlọ láti pe ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ wá sínú ilé wa ni nípa sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú inúrere sí àwọn ọmọlẹ́bí wa. Sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú inúrere nmú Ẹ̀mí Mímọ́ wá. Arábìnrin Linda K. Burton, Ààrẹ Gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, ni kí a gbèrò: “Báwo ni a ṣe nmọ̀ọ́mọ̀ sọ̀rọ̀ rere sí ara wa léraléra tó?”3

Àwọn ìtàn Alààyè

Àwọn Ará Rómù 12:10; Mòsíàh 4:15; Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 25:5

Àwọn Ìtàn Alààyè

Alàgbà D. Todd Christofferson ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ṣe àbápín ìrírí ìgbà èwe kan tí ó mú kí pàtàkì ìfẹ́ni ẹbí wọ̀ọ́ lọ́kan. Nígbàtí Òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wà ní ọmọdékùnrin, ìyá wọn se iṣẹ́ abẹ àrùn jẹjẹrẹ tí ó mú kí ó jẹ́ ìrora gidi fún un láti lo apá ọ̀tun rẹ̀. Pẹ̀lú ẹbíi kìkì àwọn ọmọdékùnrin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ ló wà fún lílọ̀, ṣùgbọ́n bí ìyà rẹ̀ ṣe nlọṣọ, ó ndúró lemọ́lemọ́ yío sì lọ sí yàrá ibùsùn láti sọkún títí tí ìrora náà yíò fi rọlẹ̀.

Nígbàtí bàbá Alàgbà Christofferson mọ ohun tí ó nṣẹlẹ̀, ó fi ìkọ̀kọ̀ wà láì jẹ oúnjẹ ọ̀sán fún bí ọdún kan láti fi owó pamọ́ láti ra ẹ̀rọ tí ó mú kí aṣọ lílọ̀ rọrùn síi. Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ sí ìyàwó rẹ̀, ó fi àpẹrẹ ṣíṣe ìtọ́jú ní àárín àwọn ẹbí lélẹ̀ fún àwọn ọmọdékùnrin rẹ̀. Nípa ìbáṣepọ̀ ìrọ̀rùn yí, Alàgbà Christofferson sọ pé, “Èmi kò mọ̀ nípa ìrúbọ ti bàbá mi àti ìṣe ìfẹ́ fún ìyá mi ni ìgbà náà, ṣùgbọ́n nísisìnyí tí mo mọ̀, mo sọ fún ara mi pé, ọkùnrin kan wà.’”4

Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. “Ẹbí náà: Ìkéde kan sí gbogbo Àgbáyé,” Amọ̀nà, Oṣù Kọkànlá. 2010, 129.

  2. Russell M. Nelson, “Ìgbàlà àti Ìgbéga,” Amọ̀nà, Oṣù Kárún 2008, 8.

  3. Linda K. Burton, “A Ó Gòkè Papọ̀,” Amọ̀nà, Oṣù Kárún 2015, 31.

  4. D. Todd Christofferson, “Ẹ Jẹ́ Kí A Jẹ́ Ọkùnrin,” Amọ̀nà, Oṣù Kọkànlá. 2006, 46.

Gbèrò Èyí

Báwo ni ìfẹ́ni àti ìbojúto fún ara wa ṣe npe Ẹ̀mí wá sínú ilé wa?

Tẹ̀