Ọdọ
Ṣíṣe àbápín Ìdúnnú Ayérayé
Ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó dára jùlọ nípa ìhìnrere ni òye ti ètò ìgbàlà. A ní ànfàní ọ̀wọ̀ láti wà pẹ̀lú ẹbí wa fún ayé àìlópin. Òye náà nrànwá lọ́wọ́ láti ní ìrètí nígbàkugbà tí a bá ní ìmọ̀lára ìbòmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ayé. Ààrẹ Eyring kọ́ni pé, Olùfẹ́ni Bàbá wa Ọ̀run mọ ọkàn wa. Èrò Rẹ̀ ni láti fún wa ní ìdùnnú (wo 2 Nífáì 2:25). Àti pé nítorínáà Ó fún wa ní ẹ̀bùn Ọmọ Rẹ̀ láti jẹ́ kí ayọ̀ ìsopọ̀ ẹbí tí yíò tẹ̀síwájú títí láé ṣeéṣe. … Ó jẹ́ ìfúnni tí olúkúlùkù ọmọ Ọlọ́run tí ó wá sínú ayé le ní ẹ̀tọ́ sí.
Ìbùkún náà wúlò fún àwọn wọ̃nnì lára wa tí wọ́n ngbé nísisìnyí àti sí àwọn wọ̃nnì tí wọ́n ti kọjá lọ—ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ wa nìkan. Àwọn bàbánlá wa wà ní ayé ẹ̀mí nísisìnyí, wọ́n ndúró fún wa láti pèsè àwọn orúkọ wọn sílẹ̀ láti ṣe àwọn ìlànà tẹ́mpìlì ní ìgbẹnusọ fún wọn. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà míràn ó lè nira láti ṣe iṣẹ́ náà fún wọn. A lè ní iṣẹ́ tí ó pọ̀ jù lọ́wọ́, tàbí a lè máa gbé níbití ó jìnà réré kúrò ní tẹ́mpìlì láti lọ léraléra.
Pẹ̀lú orírere, àwọn ọ̀nà míràn wà tí a fi lè ran àwọn bàbáńlá wa lọ́wọ́, bíi ṣíṣe iṣẹ́ ìwé ìtàn ẹbí, títọ́kasí, tàbí gbígbajókó ọmọ fún àwọn òbí wa nígbàtí wọ́n bá lọ sí tẹ́mpìlì. Nípa rìrànnilọ́wọ́, à nsin Olúwa àti pé à nmú ìrètí àwọn ẹbí ayérayé wá sọ́dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní òdìkejì ìbòjú.