2016
Pípa àwọn Òfin mọ́ àti Níní Ìfẹ́ àwọn Ẹlòmíràn
OṢù Owewe 2016


Ọ̀dọ́

Pípa àwọn Òfin mọ́ àti Níní Ìfẹ́ àwọn Ẹlòmíràn

Nígbàtí a bá ronú nípa ìfẹ́, nígbàkugbà àwọn ohun àkọ́kọ́ tí ó nwá sí ọkàn ni àwọn eré ìtàgé ìfararora, ohun ìpanu, àti àwọn òdodo. Ṣùgbọn ìfẹ́—òtítọ́ ìfẹ́—jinlẹ̀ gidi ó sì jẹ́ jíjọ̀wọ́ araẹni sílẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Jésù Krístì gbé ìgbé ayé fún wa ó sì kú fún wa nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa. Dájúdájú, òfin méjì tí ó gajù ni láti ní ìfẹ́ Ọlọ́run àti láti ní ìfẹ́ gbogbo ènìyàn tókù (wo matteù 22: 36–40). Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè fihàn sí àwọn ẹlòmíràn pé a ní ìfẹ́ wọn?

Ààrẹ Uchtdorf ṣe àbápín òwe Krístì nípa àwọn ọmọkùnrin méjì, ọ̀kan tí ó ṣiṣẹ́ fún bàbá rẹ̀ àti ọkàn tí kò ṣeé. Olùgbàlà ṣe àmì náà pé ọmọkùnrin tí ó gbọ́ran sí bàbá rẹ ní ìfẹ́ rẹ̀ nítòótọ́. Bákan náà,nígbàtí a bá gbọ́ran sí àwọn òfin Ọlọ́run, à nfihàn pé á ní ìfẹ́ rẹ̀ àti pé a fẹ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè fihàn pé a ní ìfẹ́ gbogbo ènìyàn tó kù? Ààrẹ Uchtdorf ṣe àlàyé èyíinì náà: Tí a bá ní ìfẹ́ ọmọnikejì wa nítòótọ́, a ó fi ara wa sílẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn òtòṣì àti aláìní, àwọn aláìsàn àti àwọn tí pọ́n lójú. Nítorí àwọn tí wọ́n nṣe iṣẹ́ ìjọ̀wọ́araẹnisílẹ̀ ti ìyọ́nú àti iṣẹ́ ìsìn wọ̀nyí, àwọn kannáà ni ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.

Nítorínáà nígbà míràn tí ẹ bá rí òbí yín, àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n, tàbí ọ̀rẹ́ kan, ẹ ronú nípa sísìn wọ́n láti fi ìfẹràn yín hàn fún wọn. Kìí ṣe pé yíò mú inú tiwọn ati tiyín dùn nìkan Ṣùgbọ́n yíò mú kí inú Bàbá yín ní Ọ̀run dùn pẹ̀lú.