2016
Lẹ́hìn Ìfẹ́, Nígbànáà Kí Tún Ni?
OṢù Owewe 2016


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Kínní, Oṣù KẸ́SÀN Ọdún 2016

Lẹ́hìn Ìfẹ́, Nígbànáà Kí Tún Ni?

Àyànfẹ́ Wòlíì wa, Ààrẹ Thomas S. Monson, ti kọ́ni pé ìfẹ́ ní àkójá ìhìnrere.”1

Ìfẹ́ ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀ tí Jésù fi pèé ní àkọ́kọ́ àtí òfin nlá , ó sì sọ pé gbogbo ohun míràn nípa òfin àti ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì ni ó rọ̀ mọ́ ọ.2

Ìfẹ́ ni ààrin gbùngbùn èrò fún gbogbo ohun tí à nṣe nínú Ìjọ. Gbogbo ètò, gbogbo ìpàdé, gbogbo ìṣe tí a jẹ́ apákan rẹ̀ bíi ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì gbọ́dọ̀ wá láti inú ìhùwàsí yí—nítorí láìsí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìfẹ́ àìléérí ti Krístì, a kò jẹ́ nkankan.3

Lẹ́ẹ̀kan tí a bá ti ní òye yí pẹ̀lú iyè inú àti ọkàn wa, lẹ́ẹ̀kan tí a ba ti kéde ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti fún àwọn ọmọnikeji wa—Kí ló tún kù nígbànáà?

Ṣe ìmọ̀lára ìyọ́nú àti ìfẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn tó? Njẹ́ kíkéde ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti àwọn aládúgbò wa kún ojú òsùnwọ̀n ojúṣe wa sí Ọlọ́run?

Òwe àwọn Ọmọkùnrin Méjì

Nínú tẹ́mpìlì ní Jérúsálẹ́mù, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà àwọn Júù dé ọ̀dọ̀ Jésù láti ko O sí panpẹ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Olùgbàlà, bákannáà, yí tábìlì po lé wọn lórí nípa sísọ ìtàn kan.

Ọkùnrin kan ní àwọn ọmọkùnrin méjì, Ó bẹ̀rẹ̀ Bàbá náà lọ bá àkọ́kọ́ ó sì sọ fún láti lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgba ajarà. Ṣùgbọ́n ọmọkùnrin náà kọ̀ jálẹ̀. Ní ìkẹhìn ọmọ náà ronúpìwàdà, ó sì lọ.

Nígbànáà bàbá lọ bá ọmọkùnrin èkejì ó sì sọ fun ki ó lọ̀ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà. Ọmọkùnrin èkejì mu dáa lójú pé òun yíò lọ,ṣùgbọ́n kò lọ rárá.

Nígbànáà Olùgbàlà yípadà sí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà Ó sì bèèrè pé, Èwo nínú àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí ni ó ṣe ìfẹ́ bàbá rẹ̀?

Wọ́n níláti gbà pé ọmọkùnrin àkọ́kọ́ ni—ọ̀kan tó sọ pé òun kò ní lọ ṣùgbọ́n nígbẹ̀hìn ó ronúpìwàdà ó sì lọ láti ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà.4

Olùgbàlà lo ìtàn yí láti ṣe àtẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì kan—àwọn wọnnì tí wọ́n gbọ́ran sí àwọn òfin ní ó nífẹ́ Ọlọ́run nítòótọ́.

Bóyá èyí ni ìdí tí Jésù fi ni kí àwọn ènìyàn ó fetísílẹ̀ sí kí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀ àwọn Pharisee àti agbowóde ṣùgbọ́n kí wọ́n máṣe tẹ̀lé àpẹrẹ.wọn.5 Àwọn olùkọ́ ẹ̀sìn wọ̀nyí kò rìn nínú ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n nífẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn, ṣùgbọ́n ó dunni pé wọ́n ṣìnà àkója rẹ̀.

Àwọn Ìṣe àti Ìgbàlà Wa

Nínú ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ ìgbẹ̀hìn ti Olùgbàlà sí àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀, Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nípa ìdájọ́ ìgbẹ̀hìn. A ó ya àwọn olódodo àti àwọn ènìyàn bubúrú sọ́tọ̀. Àwọn ẹni rere yíò jogún ìyè ayérayé, a ó gbé àwọn ènìyàn búburú sí ìjìyà ayérayé.

Kíni ìyàtọ̀ tí ó ti wà ní àárín àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì?

Àwọn tí wọ́n ṣe àpèjúwe ìfẹ́ wọn nípa ìṣe ni a gbàlà. Àwọn ti kò ṣeé ni a dálẹ́bi.6 Ìyípadà ọkàn tootọ́ sí ìhìnrere Jésù Krístì àti àwọn iyì àti ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀ yíò di jẹ́jẹ́ ẹ́rì sí nípa àwọn ìṣe wa ní ìgbé ayé wa ojojúmọ́.

Ní ìparí, ìkéde lásan ti ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti àwọn ọmọnikejì kì yíò mú wa yege fún ìgbéga. Nítorí, bí Jésù ṣe kọ́ni, “Kìí ṣe gbogbo ẹnití npè mi ní Olúwa Olúwa ni yíò wọlé sínú ìjọba ọrun; bíkòṣe ẹnití nṣe ìfẹ ti Bàbá mi tí nbẹ ní ọrun.”7

Kíni ó Kan lẹ́hìn Ìfẹ́?

Ìdáhùn sí ìbèèrè náà Lẹ́hìn ìfẹ́, nígbànáà kíni? lè jẹ́r írọ̀rùn kí ó sì ṣe tààrà. Tí a bá nífẹ́ Olùgbàlà nítòótọ́, a ó darí ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nígbànáà a ó rìn ní ipá ọ̀nà ti ọmọlẹ́hìn. Nígbàtí a bá ní ìfẹ́ Ọlọ́run, a ó tiraka láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.8

Tí a bá ní ìfẹ́ ọmọnikejì wa, a ó jọ̀wọ́ ara wa láti ṣèrànwọ́ àwọn òtòṣì àti aláìní, aláìsàn àti ẹni tí a pọ́n lójú.”9 Nítorí àwọn tí wọ́n nṣe iṣẹ́ ìjọ̀wọ́araẹnisílẹ̀ ti ìyọ́nú àti iṣẹ́ ìsìn wọ̀nyí,10 àwọn yí kannáà ni ọmọẹ̀hìn ti Jésù Krístì.

Èyí ni ohun tí ó nwá lẹ́hìn ìfẹ́.

Èyí ni àkojá ìhìnrere ti Jésù Krístì.

Ẹkọ láti inú Ọrọ Yí

Ààrẹ Uchtdorf túmọ̀ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì tootọ́ gẹ́gẹ́bí àwọn ẹnití wọ́n nfi ìfẹ́ wọn hàn fún Un àti fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìṣe wọn. Ó kọ́ wa pé tí a bá ni ìfẹ́ Olùgbàlà nítòótọ́, a o darí ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti pé nígbànáà a ó rin ní ipá ọ̀nà ti ọmọlẹ́hìn. Gbèrò bíbèèrè lọ́wọ́ àwọn wọnnì tí ẹ̀ nkọ́ pé àwọn ọ̀nà wo ni ìfẹ́ ti wú wọn lórí láti rìn ní ipá ọ̀nà ti ọmọlẹ́hìn. Ẹ lè ṣe àbápín àwọn ìrírí yín pẹ̀lú wọn bákannáà. Ẹ lè gbèrò pipe wọn láti gbàdúrà fún ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ síi àti okun láti ṣe ìṣe nítorí ìfẹ́.