2016
Ipò Òbí Jẹ́ Ojúṣe Mímọ́
OṢù Owewe 2016


Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù KẸ́SÀN Ọdún 2016

Ipò Òbí Jẹ́ Ojúṣe Mímọ́

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yĩ kí ẹ sì wákiri lati mọ ohun ti ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní óye Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí gbogbo ayé yíò fi mú kí ìgbàgbọ yín nínú Ọlọ́run pọ̀ si kí ẹ sì bùkún àwọn wọnnì tí ẹ nṣe ìtọjú lórí wọn nípa ìbẹniwò kikọni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Èdidì Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìranlọwọ

Bàbá wa Ọ̀run gbé àwọn ẹbí dìde láti ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tó péye nínú àyíká tó ní ìfẹ́ni. Ààrẹ Thomas S. Monson sọ pé: Fún ọmọ rẹ ní oríyìn àti ìgbámọ́ra; sọ pé, mo ní ìfẹ́ rẹ̀ síi; nígbàgbogbo fi ọpẹ́ rẹ hàn. Máṣe jẹ́ kí wàhálà kan lati yanjú di pàtàkì síi ju ènìyàn kan lati fẹ́ràn.”1

Susan W. Tanner, Ààrẹ gbogbogbòò àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin tẹ́lẹ̀, kọ́ni pé: Bàbá wa ní Ọ̀run ṣe àpẹrẹ àwòṣe tí a nílati tẹ̀lé. Ó ní ìfẹ́ wa, Ó nkọ́ wa, Ó ní sùúrù pẹ̀lú wa, Ó sì gbé agbára láti yàn wa lé wa lọ́wọ́. … Ní àwọn ìgbà míràn ìbáwí, èyí tí ó túmọ̀ sí láti kọ́ni, ni à ndàpọ̀ pẹ̀lú ìṣọ̀fíntótó. Àwọn ọmọdé—ati àwọn ènìyàn ọlọ́jọ́ orí gbogbo bákannáà—ntún ìhùwàsí wọn ṣe láti inú ìfẹ́ àti ìgbaniníyànjú síi ju nínú wíwá-àṣìṣe.”2

Tí a bá fi òtítọ́ ní àdúrà ẹbí, àṣàrò ìwé mímọ́, ìpàdé ilé ẹbí ìrọ̀lẹ́, àwọn ìbùkún oyèàlùfáà, àti ṣíṣé àkíyèsí ọjọ́ ìsinmi, ni Alàgbà Quentin L. Cook ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ, àwọn ọmọ wa … yíò múrasílẹ̀ fún ilé ayérayé kan ní ọ̀run, láìka ohunkóhun tó wù kó ṣẹlẹ̀ sí wọ́n nínú ayé líle kan sí.”3

Àfikún Àwọn Ìwé Mímọ

1 Nífáì 8:37; 3 Nífáì 22:13; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 93:40; 121:41

Àwọn Ìtàn Alààyè

Mò nka ìwé ìròhìn nígbàtí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọmọ mi kékeré rọra wá sọ́dọ̀ mi, ni Alàgbà Robert D. Hales ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ. Bí mo ṣe nkàwé, inú mi dùn láti gbọ́ ohùn dídùn rẹ̀ tí ó ndọ́wẹ́kẹ̀ ní abẹ́nú. Ẹ fi ojú inú wo ìyàlẹ́nu mi nígbàtí, ní àsìkò díẹ̀ lẹ́hìn náà, ó ti ara rẹ̀ sí àárín èmi àti ìwé. Ní gbígbé ojú mi sí ọwọ́ rẹ̀ àti títẹ imú rẹ̀ sókè sí tèmi, ó bèèrè pé, Bàbá àgbà! Ṣe o wà níbẹ̀?

…Wíwà níbẹ̀ túmọ̀ sí níní òye ọkàn àwọn ọ̀dọ́ wa àti sísopọ̀ pẹ̀lú wọn. Àti sísopọ̀ pẹ̀lú wọn kò túmọ̀ sí bíbá wọn sọ̀rọ̀ lásán ṣùgbọ́n ṣíṣe àwọn ohun kan pẹ̀lú wọn bákannáà. …

A gbọ́dọ̀ ṣètò kí a sì lo ànfàní àwọn àsìkò ìkọ́ni. …

… Bí mo ṣe ngbé ìgbé ayé síi, bẹ́ẹ̀ náà ni mò ndá àwọn àsìkò ìkọ́ni ní ìgbà èwe mi mọ̀ síi, nípàtàkì àwọn wọnnì tí àwọn òbí mi pèsè, ti tún ìgbé ayé mi ṣe tí ó sì sọ mi dí ẹni tí mò jẹ́.”4

Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Thomas S. Monson,Ìfẹ́ ní Ilé—Ìmọ̀ràn láti ẹnu Wòlíì Wa,” Amọ̀nà, Oṣù Kẹ́jọ, 2011, 4.

  2. Susan W. Tanner, Ṣé Mo Sọ Fún Ọ … ? Amọ̀nà, O ṣù Karun 2003, 74

  3. Quentin L. Cook, “Olúwa Ni Ìmọ́lẹ̀ Mi,” Amọ̀nà, O ṣù Karun 2015, 64.

  4. Robert D. Hales, “Ojúṣe Wa Sí Ọlọ́run: Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Àwọn Òbí àti Àwọn Olórí sí Ìran tí ó Ndìde,” Amọ̀nà, Oṣù Karun 2010, 96, 95

Gbèrò Èyí

Kínìdí tí kíkò ìhìnrere fi dára jùlọ nípa èdè nàà ati àpẹrẹ ìfẹ́?