2016
Àwọn Ìgbóná àti àwọn Ẹ̀kọ́ ti Ìgbọràn
OṢù Ọ̀wàrà 2016


Ọdọ

Àwọn Ìgbóná àti àwọn Ẹ̀kọ́ ti Ìgbọràn

Ààrẹ Thomas S. Monson nígbà kan rí sọ nípa àsìkò kan nígbàtí òun kọ́ ẹ́kọ̀ nípa pàtàkì ìgbọràn. Nígbàtí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ, ẹbí rẹ̀ ṣe àbẹ̀wó sí ilé kekeré wọn ní orí ókè. Òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ fẹ́ gé ewéko ní ibìkan fún iná-àgọ́. Wọn tiraka láti gé ewéko náà pẹ̀lú ọwọ́, ní títu àti fífà bí wọ́n ṣe lè ṣe tó, ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí wọ́n ri ni èpò díẹ̀. Ààrẹ Monson ṣe àlàyé pé, Nígbànáà ohun tí mo rò wípé ó jẹ ọ̀nà àbáyọ pípé wá sínú ọkàn ọmọ-ọdún-mẹjọ mi. Mo wí fún Danny pé, Gbogbo ohun tí a nílò ni láti dáná sun àwọn èpò wọ̀nyìí. À ó kàn ibi róbótó kan nínú àwọn èpò náà.

Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́pé ó mọ̀ pé a kò gba òun ní ààyè láti lo ìṣána, ó sáré padà sínú ilé kékeré fún díẹ̀, òun àti Danny sì fi iná kékeré sí inú ibi ewéko náà. Wọ́n lérò pé yíò kú fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ ó bẹ́ sí iná nlá tí ó sì léwu. Òun àti Danny sáré fún ìrànlọ́wọ́, láìpẹ́ àwọn àgbàlagbà nsáré bọ láti pa iná náà kí ó tó de ibi àwọn igi.

Ààrẹ Monson tẹ̀síwájú, “Danny àti èmí kọ́ àwọn ẹkọ líle ṣùgbọn pàtàkì ní ọjọ náà—tí kókó rẹ jẹ pàtàkì ìgbọràn.” (Wo Ìgbọràn Nmú Àwọn Ìbùkún Wá,” Amọ̀ná, Oṣù Kárũn 2013, 89–90.)

Bíi ti Ààrẹ Monson, njẹ́ ẹ ti ní láti kọ́ ẹ̀kọ́ kan nípa ìgbọràn ní ọ̀nà líle bí? Kíni àwọn ìfojúsùn tí ẹ lè ṣe láti pa ara yín mọ́ ní ààbò nípasẹ̀ ìgbọràn ní ọjọ́ iwájú?

Tẹ̀