Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹ́wá 2016
Àwọn Ìbúkún ti Ìgbọràn
“Ẹ̀kọ́ tí ó tóbi jùlọ tí a lè kọ́ nínú ayé ikú, Ààrẹ,” Thomas S. Monson ti kọ́ni, “ni pé nígbàtí Ọlọ́run bá sọ̀rọ̀ tí a sì gbọ́ran, a ó máa ṣe èyítí ó tọ́ nígbàgbogbo.”1
Bákannáà a ó di alábùkún. Bí Ààrẹ Monson ṣe sọ nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbòò kan làìpẹ́ yìí: “Nígbàtí a bá pa àwọn òfin mọ́, ìgbésí ayé wa yíò láyọ̀ síi, yío di mímúṣẹ si, àti pé yío dínkù ní lílọ́lù. Àwọn ìpèníjà wa àti àwọn wáhálá yíò rọrùn síi láti gbà mọ́ra, a ó sì gba àwọn ìbùkún tí [Ọlọ́run] ti ṣe ìlérí.”2
Nínú àwọn àyọkúró wọ̀nyí láti inú àwọn ìkọ́ni ti Ààrẹ Monson bíi Ààrẹ Ìjọ, ó rán wa létí pé àwọn òfin ni ìtọ́nisọ́nà tí ó dájú jùlọ sí ìdùnnú àti àláfìá.
Àwọn Ìtọ́nisọ́ǹa fún Ìrìnàjò náà
A kò fi àwọn òfin Ọlọ́run fúnni láti dààmú wa tàbí láti jẹ́ àwọn ìdènà sí ìdùnnú wa. Ìdàkejì gan an ni òtítọ́. Ẹni ti ó dá wa tí ó sì nífẹ́ wa ní pípé mọ bí a ṣe nílò láti gbé ìgbé ayé wa gan an ní èrò láti gba ìdùnnú tí ó tóbi jùlọ tí ó ṣeéṣe. Ó ti pèsè àwọn ìtọ́nisọ́nà fúnwa èyí tí, bí a bá tẹ̀lé wọn, yíò fún wa ní ààbò nínú ìrìnàjò ayé ikú àrékérekè ìgbàkugbà yìí. A rántí àwọn ọ̀rọ̀ orin tí a mọ̀ dáadáa: Pa àwọn òfin mọ́! Nínú èyí ni ààbò wà; nínú èyí ni àláfíà wà [wo “Pa àwọn òfin mọ́,” Àwọn orin, no. 303].”3
Okun àti Ìmọ̀
Ìgbọràn ni àmì ìdánimọ àwọn wòlíì, ó ti pèsè okun àti ìmọ fún wọn nígbogbo ọjọ. Ó ṣe kókó fún wa kí a kíyèsí pé àwa, bákannáà, ní ẹ̀tọ́ sí orísun okun àti ìmọ̀ yí. Ó wà ní síṣetán sí àrọwọtó olúkúlùkù wà ní òní ti a bá ṣegbọ́ràn sí àwọn àṣẹòfin Ọlọ́run. …
Ìmọ tí a nwákiri, àwọn ìdáhùn tí a nlépa, àti okun èyí tí a nfẹ́ lóní láti dojúkọ àwọn ìpeníjà tí ayé síṣòro àti tí ó nyípadà lè jẹ tiwa nígbà tí a bá fí tọkàntọkàn gbọ́ran sí àwọn òfin Olúwa.4
Yàn láti Gbàgbọ́
Ìtumọ̀ ti ìgbà tiwa jẹ́ fífi àyè gbà. Àwọn ìran ìwé ìròhìn àti amóhùnmáwòrán nṣe àfihàn àwọn ìràwọ̀ nínú eré ìtàgé, àwọn akọni eré ìje orí pápá—àwọn wọ̃nnì tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́mọdé nfẹ́ láti fiṣe àwòkọ́ṣe—bí àìka àwọn òfin Ọlọ́run sí àti àṣehàn àwọn ìṣe ẹ̀ṣẹ̀, ṣe dàbíí pé kò ní àbájáde tí kò dára. Ṣé ẹ kò gbà á gbọ́ ni! Àkókò ìṣirò kan wà—àní ti mímú ìwé ìṣirò dọ́gba. Gbogbo Cinderéllà ni ó ní òru ààjìn rẹ—bí kò ṣe ní ayé yí, nígbànáà ni èyí tí ó nbọ̀. Ọjọ́ Ìdájọ́ yíò wá fún gbogbo ènìyàn. … Mo bẹ́bẹ́ pẹ̀lú yín láti yan láti gbọ́ran.5
Ayọ̀ àti Àláfíà
Ó lè farahàn síi yín ní áwọn ìgbàmíràn pé àwọn wọ̃nnì tí wọ́n wà níta nínú ayé nní ìdárayá púpọ̀ ju bí ẹ ṣe wà lọ. Ọ̀pọ̀ nínú yín lè ní ìmọ̀lára ìdíwọ́ nípa ẹ̀nà ìhùwàsí èyí tí àwa nínú Ìjọ fi aramọ́. Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, mo kéde síi yín, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, pé kò sí ohunkóhun èyí tí ó lè mú ayọ̀ púpọ̀ síi wá sínú ayé wa tàbí àláfíà púpọ̀ sínú ẹ̀mí wa ju àwọn Ẹ̀mí èyítí ó lè wá sí ọ̀dọ̀ wa bí a ṣe ntẹ̀lé Olùgbàlà tí a sì npa àwọn òfin mọ́.”6
Rìn Ní Títọ́
Mo jẹ́rìí síi yín pé àwọn ìbùkún tí a ṣe ìlérí fúnwa kọjá òṣùwọ̀n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkuùkù ìjì lè kórajọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òjò lè rọ̀ lé wa lórí, ìmọ̀ wa nípa ìhìnrere àti ìfẹ wa sí Bàbá wa Ọrun àti ti Olùgbàlà wa yíò tù wá nínú yíò sì mú wa dúró yíò sì mú ayọ wá sí ọkàn wa bí a ṣe nrìn ní títọ́ tí a sì npa àwọn òfin mọ. Kì yíò sí ohunkóhùn nínú ayé yí tí ó lè ṣẹgun wa.7
Tẹlé Olùgbàlà
Tani Ọkùnrin oníròbìnújẹ́ yí, tí ó di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú ẹ̀dùn? Ẹni tí ó jẹ́ Ọba ògo, Olúwa àwọn ọmọ ogun yí? Òun ni Ọ̀gá wa. Òun ni Olùgbàlà wa. Òun ni Ọmọ Ọlọ́run. Òun ni Olùpilẹ̀ṣẹ̀ Ìgbàlà wa. Ó npè, Tẹ̀lé mi. Ó pàṣẹ, Lọ, kí o sì ṣe bákannáà. Ó nbẹ̀bẹ̀, Pa àwọn òfin mi mọ́.
“Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé E. Ẹ jẹ́ kí a dọ́gba pẹ̀lú àpẹrẹ Rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a gbọ́ran sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, à n fun Un ni ẹ̀bùn ọ̀run ti ìmoore.”8
© 2016 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹẹ ní USA Àṣẹ Gẹẹsì: 6/16. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/16. Ìyírọ̀padà ti First Presidency Message, October 2016. Yoruba. 12866 779