2016
Báwo ni Ẹ̀yin yíò Ṣe Rántí Olùgbàlà Ní Ọ̀sẹ̀ Yí?
OṢù Ọ̀pẹ̀ 2016


Ọ̀dọ̀ Ọ̀dọ́

Báwo ni Ẹ̀yin yíò Ṣe Rántí Olùgbàlà Ní Ọ̀sẹ̀ Yí?

Ààrẹ Eyring gbà wá níyànjú láti yan láti rántí [Olùgbàlà] ní ọ̀nà tí ó dára jùlọ ní fífa ọkàn yín sí ọdọ̀ Rẹ̀.

Báwo ni ẹ ṣe nfi ìgbà gbogbo rántí Rẹ̀ jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ (wo Májẹ̀mú 20:77, 79)?

Njẹ́ ẹ ní àwọn ìwé mímọ́ tí ẹ fẹ́ràn jùlọ nípa Olùgbàlà? Ẹ lè fi àmì sí ìwé mímọ́ kan tí ó yàtọ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀sẹ̀ yí kí ẹ sì ṣe àbápín rẹ̀ pẹ̀lú ẹnìkan.

Njẹ́ ẹ̀ nkọ orin ìsìn kan tàbí orin ìwúrí míràn ninú yín nígbàtí ẹ̀ nní ìrẹ̀wẹ̀sì? Bóyá kí ẹ yan ọ̀kan tí ó jẹ́ pàtàkì nípa Olùgbàlà ní ọ̀sẹ̀ yí.

Ṣe ẹ njíròrò ìgbé ayé Olùgbàlà àti ẹbọ ètùtù ní ìgbà oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀? Ẹ lè múrasílẹ̀ fún oúnjẹ Olúwa nípa rírántí àwọn àṣàyàn yín jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ láti rántí Olùgbàlà nígbà gbogbo àti ríronúpìwàdà àwọn àsìkò nígbàtí ẹ̀ nlàkàkà láti ṣeé.

Ṣe ẹ̀ ngbàdúrà fún àwọn ààyè láti ṣe àbápín ìhìnrere ní ojojúmọ́? Ẹ tiraka láti ní ìsọ̀rọ̀ ìhìnrere ní ọ̀sẹ̀ yí tó dá lórí Olùgbàlà. Ẹ lè jẹ́ ẹ̀rí nípa Olùgbàlà ní àsìkò ìpàdé ẹbí ilé ìrọ̀lẹ́ tàbí sọ̀rọ̀ sí ọ̀rẹ́ kan ní ilé ìwé nípa ìrírí kan tí ẹ ní ní ilé ìjọsìn.

Ṣe ìfojúsí kan láti rántí Olùgbàlà ní ọ̀nà àrà ní ọ̀sẹ̀ yí. Sọ fún òbí kan, arákùnrin tàbí arábìnrin kan, tàbí ọ̀rẹ́ kan nípa ìfojúsí rẹ. Ní òpin ọ̀sẹ̀ náà, sọ fún wọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀.Ní ìparí àwọn olùbínú ènìyàn-kénìyàn gba ẹ̀mí Rẹ̀. Ẹyin méjèèjì yíò ní ìmọ̀ara àláfíà àti ìdùnnú tí Ààrẹ Eyring sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Tẹ̀