2016
Ayọ̀ Ẹbí Ni À Nrí nínú Ìṣòdodo
OṢù Ọ̀pẹ̀ 2016


Ọrọ Ìbẹniwò Kíkọni Oṣù Kejìlá 2016

Ayọ̀ Ẹbí Ni À Nrí nínú Ìṣòdodo

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín Báwo ni níní óye Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí gbogbo ayé yíò fi mú kí ìgbàgbọ yín nínú Ọlọ́run pọ̀ si kí ẹ sì bùkún àwọn wọnnì tí ẹ nṣe ìtọjú lórí wọn nípa ìbẹniwò kikọni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìrànlọwọ

Ọlọ́run ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ẹbí láti mú ìdùnnú wá fún wa, láti rànwálọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pípé ní àyíká tó ní ìfẹ́, àti láti múra wa sílẹ̀ fún ìyè ayérayé.”1 Nínú ètò ìdùnnú nlá ti Ọlọrun” (Álmà 42:8), Ààrẹ Russell M. Nelson, Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá, sọ pé: Ètò Rẹ̀ kéde pé kí àwọn ọkùnrin àti obìnrin wà kí wọ́n lè ní ayọ̀ [2 Nífáì 2:25]. Ayọ̀ náà nwá nígbàtí a bá yàn láti gbé ìgbé ayé ní ìbámu pẹ̀lú ètò ayérayé ti Ọlọ́run.”2

Àwọn ilé tí Krístì wà ní àrin gbùngbùn rẹ̀ npèsè àwọn ànfàní tó tóbi jùlọ fún àṣeyege. Alàgbà Richard G. Scott (1928–2015) ti iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ṣe àpèjúwe rẹ̀ bí ibì kan níbití à nkọ́ni ní ìhìnrere, tí à npa àwọn májẹ̀mú mọ́, àti tí ìfẹ́ ngbé lọ́pọ̀lọpọ̀, níbití àwọn ẹbí ti lè gbé ìgbé ayé ìgbọràn àti tí wọ́n le di gbòngbò tó múlẹ̀ nínú ìhìnrere ti Jésù Krístì.”3

Ààrẹ Henry B. Eyring, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Aàrẹ Kínní, sọ pé: A lè pinnu pé a ó ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti mú àwọn agbára ọ̀run sọ̀kalẹ̀ sínú ẹbí [wa]. Ó sì ṣeéṣe jùlọ kí a ṣe àgbéga ìfẹ, iṣẹ́ ìsìn, ìgbọ́ràn, àti ìdùnnú nínú ile wa nípa [kí àwọn ọmọ wa] máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nígbà náà gbígbìyànjú rẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwà ẹ̀dá wọn yíò yípadà ní ọ̀nà tí ó ṣe àbájáde ìdùnnú tí wọn nwákiri.’4

Àwọn Ilé tí Krístì wà ní Ààrin Gbùngbùn rẹ̀

A ní àwọn àfijúwe ti àwọn ilé tí Krístì wà ní ààrin gbungbun- wọn nínú àwọn ìwé mímọ́. Lẹ́hìntí bàbá rẹ̀, Lẹ́hì, kú, Nífáì kó àwọn ẹbí rẹ̀ àti àwọn míràn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú àwọn ìkìlọ àti àwọn ìfihàn ti Ọlọ́run àti àwọn tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Lámánì. Ní ibi tuntun yí, àwọn ará Nífáì lè pa àwọn ìdájọ́, àwọn àṣẹ, àti àwọn òfin Olúwa mọ́ nínú ohun gbogbo, ní ìbámu sí òfin Mósè (wo 2 Nífáì 5:6–10) Síbẹ̀síbẹ̀ àní ní àárín àwọn ará Nífáì, àwọn kan nígbẹ̀hìn di aláìgbọràn.

Àti pé nígbàtí àwọn ọmọlẹ́bí wa lè fi ìgbà míràn yẹ̀ kúrò nínú ìṣòdodo bí àwọn ará Nífáì ti ṣe, Alàgbà Scott sọ pé ilé tí Krístì wà ní ààrin gbùngbùn rẹ̀ ṣì npèsè ìdánilójú títóbi jùlọ fún àláfíà àti ààbò nínú ilé wa. Ó jẹ́wọ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ́ àwọn ìpènijà ni yíò ṣì wà tàbí àwọn ìrora ọkàn, ṣùgbọ́n àní ní àárín ìrúkèrúdò, a lè gbádùn àláfíà àtinúwá àti ìdùnnú tó jinlẹ̀.”5

Àfikún àwọn Ìwé Mímọ

3 Jòhánù 1:4; 1 Nífáì 8:12; 2 Nífáì 5:27

Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. WoÌwé Ìléwọ́: Ṣíṣe àmójútó Ìjọ (2010), 1.1.4.

  2. Russell M. Nelson, “Ìgbàlà àti Ìgbéga,” Amọ̀nà, Oṣù Kárún 2008, 92.

  3. RichardG Scott “Fún Àláfíà ní Ilé” Lìàhónà Oṣù Kárún ọdún 2013, 30, 31.

  4. Henry B. Eyring, “Àwọn Ìkọ́ni ti Ẹbí Náà: Ìkéde Kan sí gbogbo Ayé New Era, Sept. 2015, 5, 6.

  5. Richard G. Scott, Fún Àláfíà ní Ilé, 31.

Gbèrò Èyí

Kíni a lè ṣe láti gbé ìgbé ayé olódodo síi nínú ẹbí wa?