2016
Àláfíà nínú Ayé Yìí
OṢù Ọ̀pẹ̀ 2016


Ọ̀RỌ̀ÀJỌ ÀÀRE KÍNNÍ Oṣù Kejìlá Ọdún 2016

Àláfíà nínú Ayé Yìí

Sí gbogbo wa tí a ti wá sínú ayé ikú, Olùgbàlà sọ pé, Nínú ayé ẹ̀yin yíò rí ìpọ́njú (Jòhánú 16:33). Síbẹ̀síbẹ̀ Ó fi ílérí ìyanu yí fún àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ nígbá iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀: Àláfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín, àláfíà mi ni mo fi fún yín: kìí ṣe gẹ́gẹ́bí ayé ti ífúnni, ni èmi fi fún yín. (Jòhánù 14:27). Ó jẹ ìtùnú láti mọ́ pé ìlérí ti àlàfíà araẹni yí ntẹ̀síwájú fún gbogbo àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ lóní.

Lára wa ngbé ni àwọn àyíká tí ó kún fún àláfíà tí ó sì lẹ́wà, síbẹ̀síbẹ̀ a nní ìrírí ìrúkèrúdò ní inú. Àwọn míràn nní ìmọ̀ara àláfíà àti ìdákẹ́rọ́rọ́ pípé ní àárín àdánù araẹni nlá, àgbákò, àti àwọn àdánwò tó ntẹ̀síwájú.

Ẹ lè ti rí ìyanu ti àláfíà ní ojú ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì kan tàbí gbọ́ ọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Mo ti rí i ní ìgbà púpọ̀. Ní àwọn ìgbà míràn ó ti jẹ́ nínú yàrá ilé ìwòsàn kan níbití ẹbí kan ti kórajọ yíká ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tí ó súnmọ ikú.

Mo rántí bíbẹ obìnrin kan wò ní ilé ìwòsàn ní ọjọ́ díẹ̀ ṣíwájú kí ó tó kú nípasẹ̀ àrùn jẹjẹrẹ. Mo mú àwọn ọmọdébìnrin mi méjì láti tẹ̀lé mi nítorí arábìnrin didára yí ti fi ìgbà kan rí jẹ olùkọ́ni Alákọ́bẹ̀rẹ̀ wọn.

Àwọn ọmọlẹ́bí rẹ̀ kórajọ yíká ibùsùn rẹ̀, ni èrò láti wà pẹ̀lú rẹ ní òpin àsìkò rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó yà mí lẹ́nu bí ó ṣe joko soke lórí ibùsùn. Ó nawọ́ jáde sí àwọn ọmọbìrin mi ó sì fi àwọn méjèjì hàn , ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, sí ọmọlẹ́bí rẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ó sọ̀rọ̀ bii pé àwọn ọmọbìrin mi jẹ́ ọlọ́ba tí wọn gbe kalẹ̀ ní ààfin olorì kan. Ó rí ọ̀nà kan láti sọ ohun kan nípa ọ̀nà ti ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú yàrá náà fi jẹ ọmọẹ̀hìn Olùgbàlà. Mo ṣì rántí okun, ìkẹ́ra, àti ìfẹ́ nínú ohùn rẹ̀. Mo sì rántí níní ìyanu sí ẹ̀rín ìtúraká àní bí ó ṣe mọ̀ pé ọjọ́ òun lorí ilẹ̀ ayé kúrú.

Ó ti gba ìbùkún oyè àlùfáà ti ìtùnú, síbẹ̀síbẹ̀ ó fún gbogbo wa ní ẹ̀rí alààyè pé ìlérí Olúwa ti àláfíà jẹ́ òtítọ́: Àwọn ohun wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, pé nínú mi kí ẹ̀yin lè ní àláfíà. Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé” (Jòhánù 16:33).

Ó ti gba ìfipè Rẹ̀, gẹ́gẹ́bí gbogbo wa ṣe lè gbàá, èyíówù kí àwọn àdánwò àti ìdàmú wa jẹ́:

“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó ńṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.

Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ ẹkọ lọdọ mi, nítorí onínú tútù àti onírẹlẹ ọkàn ni èmí: ẹyin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín. (Matthew 11:28–29).

Nípa títẹ̀lé Olùgbàlà nìkan ni ẹnikẹ́ni lára wa lè rí àláfíà àti ìdákẹ́rọ́rọ́ nínú áwọn àdánwò tí yíò wá sí ọ̀dọ̀ gbogbo wa.

Àdúrà oúnjẹ Olúwa nrànwá lọ́wọ́ láti mọ́ bí a ṣe lè rí àláfíà náà ní àárín àwọn ìpọ́njú ayé. Bí a ṣe nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, à lè pinnu láti jẹ́ olõtọ́ sí àwọn májẹ̀mú wa láti tẹ̀le E.

Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ti ṣèlérí láti rántí Olùgbàlà. Ẹ lè yàn láti rántí Rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti fa ọkàn yín sí I. Ni àwọn ìgbàmíràn fún mi, ó jẹ́ láti rí I nínú mi tó nkúnlẹ̀ nínú Ọgbà Gẹ́tsémánè tàbí láti rí I tí ó npe Lásárù kí ó jáde wá lati inú ibojì. Bí mo ti nṣe bẹ́ẹ̀, mo nni ìmọ̀lára ìsúnmọ́ jùlọ sí I àti ìmooore kan tí ó nmú àláfíà wá sí ọkàn mi.

Ẹ ṣe ìlérí bákannáà láti pà àwọn òfin Rẹ mọ. Ẹ ṣe ìlérí láti gbé orúkọ Rẹ̀ lé orí yín àti láti jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀rí Rẹ̀. Ó ṣe ìlérí pé bí ẹ ṣe npa àwọn májẹ̀mú yín mọ́ pẹ̀lú Òun, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò wà pẹ̀lú yín. (Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77, 79.)

Èyí nmú àláfíà wá o kéréjù ní ọ̀nà méjì. Ẹ̀mí Mímọ́ nwẹ̀ wá nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nítorí Ètùtù ti Jésù Krístì. Àti pé Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún wa ní àláfíà tí ó nwá láti inú níní àṣẹ Ọlọ́run àti ìrètí ìyè ayérayé.

Àpọ́stélì Páùlù sọ̀rọ̀ nipa ìbùkún ìyanu yìí: ”Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àláfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́” (Galatians 5:22).

Nigbàtí àwọn olùránṣẹ́ ọ̀run kéde ìbí Olùgbàlà, Wọ́n polongo pé, Ògo ni fún Ọlọ́run lókè Ọ̀run, àti ní ayé àláfíà” (Lúkù 2:14; ìtẹnumọ́ àfikún). Mo jẹ́ ẹ̀rí mi gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́ẹ̀rí ti Jésù Krístì pé Bàbá àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ lè rán Ẹ̀mí láti fi àyè gbà wá láti rí àláfíà ní ayé yí, èyíówù àwọn ìdánwò tí ó lè wá sí ọ̀dọ̀ wa àti àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn.

Ìkọ́ni láti inú Ọrọ Yí

Ààrẹ Eyring kọ́ni pé àdúrà oúnjẹ Olúwa lè rànwá lọ́wọ́ láti mọ̀ bí a ṣe lè rí àláfíà nínú àwọn àdanwò wa. Wọ́n ránwa létí pé bí a ṣe npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, a ní ìlérí ti Ọlọ́run pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò wà pẹ̀lú wa. Gbèrò bíbèèrè lọ́wọ́ àwọn wọnnì tí ẹ̀ nkọ́ bí níní Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú wa ṣe lè rànwálọ́wọ́ láti ní àláfíà. Bákannáà ẹ lè ṣe àbápín àwọn èrò yín tàbí ìrírí kan nípa bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ara àláfíà nínú àdánwò kan. Ẹ lè gba àwọn wọnnì tí ẹ̀ nkọ́ níyànjú láti jíròrò ọ̀rọ̀ yí ní àkókò oúnjẹ Oluwa ní ọ̀sẹ̀ yí.

Tẹ̀