Ọ̀dọ́
Ẹrín Kan Lè Mú Ìyàtọ̀ Wá
Ààrẹ Uchtdorf fi àfojúsí méji hàn tí a níláti ní fún àwọn iṣe wa: Ní ìfẹ́ Ọlọ́run àti kí a ní ifẹ́ àwọn ọmọnìkejì. Ṣùgbọ́n ní ìgbà míràn kìí rọrùn bẹ́ẹ̀ láti ní ìfẹ́ àwọn ẹlómíràn. Ní gbogbo ọjọ́ ayé yin, àwọn ìgbà kan lè wà nígbàtí yíò ṣòro láti bá àwọn míran ṣe pọ̀—bóyá ẹnìkan tí mu ọkàn yín gbọgbẹ́ tàbí ẹ ti ní ìgbà líle láti bá ẹnìkan sọ̀rọ̀ tàbí bá a rẹ́. Ní àwọn àsìkò wọ̀nyí, ẹ gbìyànjú láti rántí ìfẹ́ tí ẹ ti ní ìmọ̀lára rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí, Bàbá Ọ̀run, àti Jésù Krístì. Rántí ayọ̀ tí ẹ mọ̀lára nínú àwọn ipò náà kí ẹ sì gbìyànjú láti rò bóyá gbogbo ènìyàn ti ní ànfàní láti ní ìmọ̀ara irú ifẹ́ bẹ́ẹ̀. Rántí pé gbogbo ènìyàn ni ọmọbìnrin tàbí ọmọkùnrin Ọlọ́run tí wọ́n sì ní ẹ̀tọ́ sí méjèejì ìfẹ́ Rẹ̀ àti tiyín.
Ẹ ronú nípa ẹnìkan pàtó nínú ayé yín tí ẹ ní iṣòro láti bárẹ́. Ẹ fi wọn sínú àdúrà yín kí ẹ sì bẹ Bàbá Ọ̀run láti ṣí ọkàn yín sí wọn. Láìpẹ́ ẹ ó bẹ̀rẹ̀ sí rí wọn bí Òun ṣe rí wọn: bíi ọ̀kan lára àwọn ọmọ Rẹ̀ tí ìfẹ́ tọ́ sí.
Lẹ́hìn tí ẹ ti gbàdúrà, ẹ ṣe ohun kan tí ó dára fún wọn! Bóyá kí ẹ pè wọ́n sí ibi ìṣeré Ìbárẹ́ kan tàbí òde pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́. Fi àyè sílẹ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ àmúrelé kan. Ànì ìwọ kàn ṣe hẹ́lòó kí o sì rẹ́rĩn sí wọn. Àwọn ohun kékeré lè mú ìyàtọ̀ nlá wá … nínú ayé ẹ̀yin méjèèjì!