Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Kínní, Oṣù Kínní 2017
Fífi ọkàn sí Ààrin Gbùngbùn
Láìpẹ́, mo wo àwọn ènìyàn kan tí wọ́n nṣeré títa ọfà. Nípa wíwò lásán, ó mọ́lẹ̀ kedere sí mi pé tí ẹ bá fẹ́di ọ̀gá ọfà àti ọrún ní tòótọ́, ó máa ngba àsìkò àti ìṣe.
Èmi kò rò pé ẹ lè ṣe ìmúdàgbà nínú òkìkí fún jíjẹ́ aláṣeyọrí olùtafà nípa títa ọfà sí ògiri lásán àti pé nígbànáà yíya àwọn ohun àfojúsùn yíká àwọn ọfà. Ẹ níláti kọ́ eré ti wíwá ibi àfọjúsùn kí ẹ sì taọ̀gangan ojú rẹ̀.
Kíkun àwọn Àfọjúsùn
Títa ní àkọ́kọ́ àti yíya àfọjúsùn lẹ́hìnnáà lè dàbí àìtọ́ díẹ̀, ṣùgbọ́n nígbàmíràn àwa fúnra wa nṣe àwòṣe irú ìwà bẹ́ẹ̀ gan nínú àwọn ipò míràn láyé.
Gẹ́gẹ́bí bí ọmọ Ìjọ, a ní ìdarísí láti lẹ ara wa mọ́ àwọn ètò ìhìnrere, àwọn àbájáde, àní àti àwọn ẹ̀kọ́ tí ó dàbí ẹnipé ó dára, ṣe pàtàkì, tàbíjẹ́ ìgbádùn sí wa. A ngbìdánwò látiya àwọn àfọjúsùn yíká wọn, ó nmú wa gbàgbọ́ pé à nfọkànsí ní kókó ìhìnrere.
Èyí rọrùn láti ṣe.
Ní gbogbo ìgbà a ti gba ìmọ̀ràn tí ó péye àti ìmísí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Ọlọ́run. Bákannáà a gba ìdarí àti ìsọdimímọ̀ láti inú àwọn onírurú àtẹ̀jáde, àwọn ìwé ìléwọ́, àti àwọn ìwé kíkà Ìjọ. A lè fì ìrọ̀rùn yan àkọlé ìhìnrere tí a fẹ́ràn jùlọ, kí a ya àwòrán ojúkojú yíká rẹ̀, kí a sì ṣe ẹjọ́ pé a ti mọ kókó ìhìnrere dájú.
OlùgbàlàSọdi Mímọ̀
Èyí kìí ṣe wàhálà tí ó jẹmọ́ ọjọ́ wa nìkan. Ní àtijọ́, àwọn olórí ẹ̀sìn nlo àsìkò púpọ̀ gidi láti ṣe ìpolówó, ṣe ipò, ṣe ìjíròrò èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ọgọọgọ́rũn àwọn òfin.
Ní ọjọ́ kan àkojọ àwọn ọ̀kàwé ẹ̀sìn gbìyànjú láti fi etí Olùgbàlà kọ́ àríyànjiyàn náà. Wọ́n ní kí Òun ó ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀ràn kan lórí èyí tí àwọn díẹ̀ lè faramọ́.
Olùkọ́ni, wọn bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀, èwo ni àṣẹ nlá nínú òfin?
“Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.
“Èyí ni èkínní àti òfin ńlá.
“Èkejì sì dàbíi rẹ̀, Ìwọ yíò fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”
“Lórí àwọn òfin méjì wọ̀nyí ni gbogbo àṣẹ àti wòlíì rọ̀ mọ́.”1
Jọ̀wọ́ ṣe àkíyèsí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tó kẹ́hìn: “Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo òfin àti wòlíì rọ̀ mọ́.”
Olùgbàlà ko fi àfọjúsùn náà hàn wá nìkan, ṣùgbọ́n bákannáà Ó dá ojúkojú náà mọ̀.
Títa Àfojúsùn náà
Gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ, a dá májẹ̀mú láti gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí ara wa. Ohun tó hàn nínú májẹ̀mú náà ni níní òye pé à ntiraka láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run, ní ifẹ́ Rẹ̀, mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀ pọ̀ si, bu ọlá fún Un, rìn ní ọ̀nà Rẹ̀, àti pé kí a dúróṣinṣin bíi ẹlẹ́rìí Rẹ̀.
Bí a ṣe nkọ́ nípa Ọlọ́run si tí a sì nní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa, bẹ́ẹ̀ náà ní à ó ṣe damọ̀ pé ẹbọ àìlópin ti Jésù Krísti jẹ́ ẹ̀bùn ọ̀run láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àti pé Ìfẹ́ Ọlọ́run nmí sí wa láti lo ipa ọ̀nà ìrònúpìwàdà tòótọ́, èyítí yíò darí wa sí ìyanu ti ìdáríjì. Ètò yí fún wa láàyè láti ní ìfẹ́ tí ó ga jù àti ìyọ́nú fún àwọn wọnnì tí wón wà ní àyíká wa. Àwa ó kọ́ láti rí kọjá ìsàmì sí. Àwa ó tako àdánwò láti fi ẹ̀sùn kàn tàbí dájọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àwọn àìlera, àwọn àṣìṣe, ìfaratì òṣèlú, ìdánilójú ẹ̀sìn, àwọn ará orílẹ̀ èdè, tàbí àwọ̀ ara.
Àwa ó rí gbogbo àwọn tí a pàdé bi ọmọ Bàbá wa Ọ̀run—arákùnrin wa tàbí arábìnrin wa.
Àwa ó nawọ́ jáde sí àwọn ẹlòmíràn nínú òye àti ìfẹ́—àní àwọn wọnnì tí wọ́n lè ṣòro láti nawọ́ ìfẹ́ sí nípàtàkì. Àwa ó ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó nṣọ̀fọ̀ a ó sì tu àwọn tí ó nílò ìtùnú nínú.2
Àwa ó sì damọ̀ pé kò sí ìnílò fún wa láti nira nípa ìfọjúsùn ìhìnrere pípé.
Àwọn òfin nlá méjì náà ni ìfọjúsùn. Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́.3 Bí a ṣe ntẹ́wọ́gba èyí, gbogbo àwọn ohun rere míràn yíò bọ́ si ipò.
Tí kókó ìdojúkọ wa, àwọn èrò, àti àwọn ìlàkàkà bá dálé mímú ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run Alágbára Jùlọ pọ̀ si àti mímú ọkàn wa gbòòrò sí àwọn ẹlòmíràn, a lè mọ̀ pé a ti rí ìfọjúsùn òdodo àti ìfọkànsí ojúkojú—ní dída ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì tòótọ́.
© 2017 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹ̀ ẹ́ ní USA. Àṣẹ Gẹẹsì 6/16. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/16. Àyípadà Èdè ti First Presidency Message, January 2017. Yoruba. 97921 779