2017
Èrò ti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́
January 2017


Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọni Oṣù, Kìnní 2017

Èrò ti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín

Àwòrán
Relief Society seal

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìranlọwọ

Èrò ti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ni láti múra àwọn obìnrin sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún ti ìyè ayérayé, ni Linda K. Burton, Ààrẹ Gbogboògbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ sọ.1 Ó jẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ẹbí, àti ìrànlọ́wọ́ ni a fi ara wa sí ẹnu iṣẹ́ ní apákan pàtàkì tiwa nínú iṣẹ́ náà.”2

Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ jẹ́ iṣẹ́ ti ara àti ti ẹ̀mí kan, ni Carole M. Stephens, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ààrẹ Gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ sọ. “Èyíinì ni ohun tí àwọn obìnrin ṣe ní ọjọ́ ti Olùgbàlà, ohun náà ni a sì ntẹ̀síwájú láti máa ṣe.”3

Bí a ṣe nwo obìnrin ará Samaríà nibi kànga, ẹnití ó fi ìkòkò omi rẹ̀ sílẹ̀ tí o sì sáré lọ láti sọ fún àwọn míràn pé Jésù jẹ́ wòlíì (wo Jòhánnù 4:6-42), tàbí Phebe, ẹnití ó fi tayọ̀tayọ̀ sin àwọn ẹlòmíràn ní gbogbo ayé rẹ̀ (wo Rómù 16:1-2), a rí àwọn àpẹrẹ ti àwọn obìnrin ní ọjọ́ Olùgbàlà tí wọn kópa ipá aápọn ní wíwá sí ọ̀dọ̀ Krístì. Òun ni ẹnití ó la ọ̀nà wa sílẹ̀ fún ìyè ayérayé (wo Jòhánnù 3:16).

Bí a ṣe nwo àwọn arábìnrin olùlànà ní Nauvoo, Illinois, tí wọ́n kórajọ nínú ilé Sarah Kimball ní 1842 láti dá ìṣètò ti ara wọn sílẹ̀, a rí ètò Ọlọ́run fún mímú Ẹgbẹ̀ Ìrànlọ́wọ́ wá àti ní ilànà pẹ̀lú oyèàlùfáà. Lẹ́hìntí Eliṣa R. Snow kọ òfin kan, Wòlíì Joseph Smith ṣe àtúnyẹ̀wò rẹ̀. Ó damọ̀ pé ìṣètò Ìjọ kò kúnná tó títí tí ìṣètò àwọn obìnrin fi wà. Ó sọ pé Olúwa gba ẹbọ wọn ṣùgbọ́n pé ohun kan tí ó dára jùlọ wà. Èmi ó ṣe ètò àwọn obìnrin lábẹ́ oyèàlùfáà ní ìbámu sí àwòṣe ti oyèàlùfáà náà, ni ó sọ.4

Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ kìí ṣe àkojọ́ àwọn obìnrin míràn lásán tí wọn nlàkàkà láti ṣe rere nínú ayé. Ó yàtọ̀. Ó jẹ́ ohunkan tó dára si nítorí ó jẹ́ ìṣètò lábẹ́ àṣẹ oyèàlùfáà. Ìṣètò rẹ̀ jẹ̀ ìgbésẹ̀ tí kò ṣeémáàní nínú ìfihàn iṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.”5

Àfikún àwọn Ìwé Mímọ́ àti Ìwífúnni

Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 25:2–3, 10; 88:73; reliefsociety.lds.org

Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Linda K. Burton, nínú Sarah Jane Weaver, Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Nṣe ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí àti Púpọ̀ síi March 17,” Àwọn Ìròhìn Ìjọ, Mar. 13, 2015, news.lds.org.

  2. Linda K. Burton, nínú Weaver, Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Nṣe ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí.

  3. Carole M. Stephens, nínú Weaver, Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Nṣe ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí.

  4. Joseph Fielding Smith, nínú Àwọn Ọmọbìrin nínú Ìjọba mi: Ìwé Ìtàn àti Iṣẹ́ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ (2011), 11–12.

  5. Àwọn Ọmọbìrin nínú Ìjọba Mi 16.

Tẹ̀