Ọ̀dọ́
Gbígbàdúrà fún Àláfíà
Olùkọwé ńgbé ní Arizona, USA
Àwọn òbí mi máa nṣe ìpàdé nígbàkugbà lẹ́hìn ìjọsìn, èmi ó sì bojútó àwọn arákùnrin mi kékeré, èmi ó sì ṣe oúnjẹ ọ̀sán fún wọn—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn máa nbínú kíákíá tí ebi sì máa ntètè pa wọn. Bí ìṣe wọn, tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìjà, mo lè dáwọ́ wàhálà kékeré náà dúró kíákíá. Ṣùgbọ́n ní ìgbàmíràn ó máa nle láti mú àláfíà wá nígbàtí ìjà bá ti bẹ̀rẹ̀ nítorí ìrunú mi.
Ní ọ̀sán ọjọ́ kan, àwọn arákùnrin mi nní ìgbà líle nípàtàkì láti bára mu. Mo ri pé àwọn ìlàkàkà mi láti mú àláfíà wá tún mú nkan burú si nítorí inú ti bí mi. Nítorínáà mo kàn ṣe oúnjẹ ọ̀sán tèmi nìkan mo sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ. Nígbẹ̀hìn, mo kéde pé, “èmi nlọ láti gbàdúrà. Ẹ jọ̀wọ́ ṣé a lè dákẹ́ fún ìṣẹ́jú kan? Nígbàtí wọ́n ti jóòkó jẹ́ẹ́, mo bèèrè fún ìbùkún lórí oúnjẹ náà. Kí ntó parí àdúrà, mo fikun pé,”Jọ̀wọ́ rànwá lọ́wọ́ láti jẹ́ onílàjà.”
Ní àkọ́kọ́, ó dàbíì pé wọn kò gbọ́ wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjà lẹ́ẹ̀kansi. Inú bí mi ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé mo nílò láti jẹ́ olùfẹ́ni kí nsì ní sùúrù bí mo ti lè ṣe tó nítorípé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà fún àláfíà ni. Lẹ́hìn ìṣẹ́jú kan, mo ní ìmọ̀ara sùúrù gidi. Mo jẹun láì sọ ohunkóhun, àwọn arákùnrin náà sì dáwọ́ ìjà dúró ní ìparí. Mo wá mọ pé àláfíà tí mo ní ìmọ̀lára rẹ̀ ni ìdáhùn sí àdúrà jẹ́jẹ́ kan. Mo ti gbàdúrà láti jẹ́ onílàjà kan, Bàbá mi Ọ̀run sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti ní sùúrù nígbàtí àdánwò láti pariwo wáyé. Mo mọ̀ pé Òun lè fúnwa ní àláfíà nítòótọ́.