2017
Ètùtù ti Krístì Ni Ẹ̀rí Ìfẹ́ ti Ọlọ́run
OṢù Èrèlè 2017


Ọ̀RỌ̀ ÌBẸNIWÒ KÍKỌNI, OṢÙ Kejì 2017

Ètùtù ti Krístì Ni Ẹ̀rí Ìfẹ́ ti Ọlọ́run

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín

Àwòrán
Èdidì Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́

Ìgbàgbọ́, Ẹbí, Ìrànlọ́wọ́

Níní òye pé Bàbá wa Ọ̀run fúnni ní Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Nìkanṣoṣo kí a lè ní ayé àìkú àti agbára fún ìyè ayérayé nrànwá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ àìníye àti àìlópin ti Ọlọ́run fún wa. Bákannáà Olùgbàlà wa ní ìfẹ́ wa.

“Tani ó lè yà wa kúrò nínú ìfẹ́ Krístì? …

“Nítorí mo mọ̀, pé kìí ṣe ikú, tàbí iyè, tàbí àwọn ángẹ́lì, tàbí ẹmí òkùnkùn, tàbí àwọn agbára, tàbí àwọn ohun tí ó wa nísisìnyí, tàbí àwọn ohun tí ó nbọ̀,

“Tàbí gíga, tàbí ìbú, tàbí ẹ̀dá ohunkóhun míràn, ni yíò lè yà wa kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí ó wà nínú Krístì Jésù Olúwa wa” (Romans 8:35, 38–39).

Nípa Ètùtù Jésù Krístì, Alàgbà D. Todd Christofferson ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ pé: “Ìjìyà Olùgbàlà nínú ọgbà Gẹ́tsémánè àti ìrora Rẹ̀ lórí igi àgbélèbú rà wá padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nípa ṣíṣe ìtẹ́lọ́rùn fún ìbèèrè tí ìdáláre ní lórí wa. Ó nawọ́ àánú Ó sì ndáríji àwọn wọnnì tí ó ronúpìwàdà. Ètùtù Jésù Krístì bákannáà ṣe ìtẹ́lọ́rùn fún gbèsè tí ìdáláre jẹ wa nípa ìwòsàn àti ìsanpadà fún wa fún ìjìyàkíjìyà tí à nfaradà láìmọ̀. ‘Nítorí kíyèsĩ i, òun jìyà àwọn ìrora gbogbo ènìyàn, bẹ̃ni, àwọn ìrora ẹ̀dá alãyè gbogbo, àti àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé, tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Ádámù’ (2 Nífáì 9:21; bákannáà wo Alma 7:11–12).”1

Krístì ti “yà [wá] sí órí àtẹ́lẹwọ́ [Rẹ̀]” (Ìsàíàh 49:16). Linda K. Burton, Ààrẹ̀ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, sọ pé, “Ìṣe ìfẹ́ tí ó ga jùlọ yẹ kí ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lọ sí órí eékún wa nínú àdúrà ìrẹ̀lẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Bàbá Ọ̀run fún fífẹ́ wá tó tí Ó fi rán Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Nìkanṣoṣo àti pípé láti jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwọn ìrora ọkàn wa, àti gbogbo àwọn ohun tí ó dàbíì pé kò dára nínú ìgbé ayé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.”2

Àfikún àwọn Ìwé Mímọ́ àti Ìwífúnni

Jòhánù 3:16; 2 Nífáì 2:6–7, 9; reliefsociety.lds.org

Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. D. Todd Christofferson ”Ìràpadà,” Liahona, May 2013, 110.

  2. Linda K. Burton, “Njẹ́ a kọ Ìgbàgbọ́ nínú Ètùtù ti Jésù Krístì sí inú Àwọn Ọkàn Wa?” Liahona, Nov. 2012, 114.

Gbèrò Èyí

Báwo ni a ṣe lè fi ìmoore wa hàn àti ìfẹ́ sí Ọlọ́run àti sí Jésù Krístì fún ẹ̀bùn Ètùtù ti Olùgbàlà wa?

Tẹ̀