Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2016
Di Ìhámọ́ra pẹ̀lú Òdodo
Wòlíì Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, Ààrẹ Thomas S. Monson, ti kéde pé, “Ní òní, a wà ní ìpàgọ́ dídojúkọ àkójọ ẹ̀ṣẹ̀, ìbájẹ́, ati ibi títóbi jùlọ láyé tí wọ́n kórajọ sí iwájú wa.”1
Njẹ́ yíó yà yín lẹ́nu láti kọ́ pé Ààrẹ Monson sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì ní àádọ́ta ọdún sẹ́hìn? Bí a bá wà ní ìpàgọ́ ìlòdì sí àkójọ ìwà búburú tí kò sí irú rẹ̀ rí ní ìgbà náà, báwo ni èṣù ṣe nhalẹ̀ mọ́ wa tó ní òní? Fún ìdí rere, Olúwa ti kéde nípa ìgbà tiwa, “Kíyèsi, àwọn ọ̀tá dìmọ̀ pọ̀” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 38:12).
Ogun nínú èyí “tí a ti pe gbogbo wa sí”2 bẹ̀rẹ̀ ṣíwájú kí wọ́n tó bí wa sí orí ilẹ̀ ayé. Ó bẹ̀rẹ̀ àní ṣíwájú kí wọ́n tó dá ayé. Ó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́hìn ní ìjọba ìṣíwájú ayé àìkú, níbití Sátánì ti ṣọ̀tẹ̀ tí ”òun sì lépa láti ṣe ìparun òmìnira ènìyàn lati yàn” (Mósè 4:3)
Sátánì pàdánù ogun náà “wọ́n sì jùú síta sí orí ilẹ̀ ayé” (Ìfihàn 12:9), níbití ó ti ntẹ̀síwájú nínú ogun rẹ̀ ní òní. Ní ìhín lórí ilẹ̀ ayé “ó nja ogun pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run, ó sì yí gbogbo wọn káàkiri” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 76:29) pẹ̀lú àwọn irọ́, ẹ̀tàn, àti àwọn àdánwò.
Ó njagun ní ìlòdì sí àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́stélì. Ó njagun ní ìlòdì sí òfin ìpa ara ẹni mọ́ àti ìwànímímọ́ ìgbeyàwó. Ó njagun ní ìlòdì sí ẹbí àti tẹ́mpìlì. Ó njagun ní ìlòdì sí ohun tí ó jẹ́ rere, mímọ́, àti yíyàsọ́tọ̀.
Báwo ni a ṣe lè kó ogun ja irú ọ̀tá náà? Báwo ni a ṣe lè ja ní ìlòdì sí ibi tí ó nfarahàn bí ẹnipé ó ngbé ayé wa mi? Kíni ìhámọ́ra wa? Àwọn wo ni ojúgbà wa
Agbára Ọ̀dọ́ Àgùtàn Náà
Wòlíì Joseph Smith kọ́ni pé Sátánì ní agbára lórí wa dé ibití a bá gbàá láàyè dé nìkan.3
Ní wíwo ọjọ́ tiwa, Nífáì, “kíyèsí agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, pé ó sọ̀kalẹ̀ sí orí àwọn ènìyàn mímọ́ ti ìjọ Ọ̀dọ́-àgùtàn, àti sí orí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa, àwọn tí a túká sórí gbogbo ojú àgbáyé; wọ́n sì gbáradì pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá” (1 Nífáì 14:14; àfikún àtẹnumọ́).
Báwo ni a ṣe lè di ara wa ní ìhámọ́ra pẹ̀lú òdodo àti agbára? À nya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́ a sì nbu ọlá fún oyèàlùfáà. À ndá a sì npa májẹ̀mú mímọ́ mọ́, a nṣiṣẹ́ lórí ìwé ìtàn ẹbí, a sì nlọ̀ sí tẹ́mpìlì. À ntiraka lemọ́lemọ́ láti ronúpìwàdà kí a sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa láti “ṣe àmúlo ètùtù ẹ̀jẹ̀ Krísti kí a lè gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa” (Mosiah 4:2) A ngbàdúrà a sì nsìn a sì njẹ́ ẹ̀rí a sì nlo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì.
Bákannáà à ngba ara wa dì pẹ̀lú òdodo àti agbára bí a ti “nfi àwọn ọ̀rọ̀ ìyè ṣe ìṣura lemọ́lemọ́ nínú wa” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:85). À nfi àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì ṣe ìsura nípa ríri ara wa sínú àwọn ìwé mímọ́ àti sínú àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa tí a yàn, àwọn tí yíò ṣe àbápín ìfẹ́, inú, àti ohùn Rẹ̀ (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 68:4) ní ìgbà ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbòò ní oṣù tó nbọ̀.
Nínú ogun jíjà wa ní ìlòdì sí èṣù, a gbọ́dọ̀ máa rántí nígbàgbogbo pé a ní ìrànlọ́wọ́ ní àwọn ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ti ìbòjú. Nínú àwọn ojúgbà wa ni Ọlọ́run Bàbá Ayérayé, Olúwa Jésù Krísti, àti Ẹ̀mí Mímọ́.
Nínú àwọn ojúgbà wa bákannáà ni àwọn ológun àìrí ti ọ̀run. “Má bẹ̀rù,” Èlíshà sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó kún fún ìbẹ̀rù bí wọ́n ṣe dojúkọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti èṣù kan, “nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ” (wo 2 Àwọn Ọba 6:15–16).
A kó níláti bẹ̀rù. Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn Ènìyàn Mímọ́ Rẹ̀. Kò ní fi wá sílẹ̀ láéláé.
Mo mọ̀ pé Ọlọ́run, ní ìdáhùn sí àdúrà, ti mú àwọn ìbèèrè mi ṣẹ láti gbà mí kúrò lọ́wọ́ èṣù. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run Bàbá, Olùgbàlà aráyé, àti Ẹ̀mí Mímọ́, a lè ní ìdánilójú pé a ó gba agbára tí ó ju ànító lọ láti kojú èyíkéyìí àwọn agbára èṣù tí a lè dojúkọ.
Njẹ́ ki a lè fi ìgbàgbogbo di ìhámọ́ra pẹ̀lú òdodo kí a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú íṣẹ́gun ní ìgbẹ̀hìn.
© 2017 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹẹ ní USA Àṣẹ Gẹẹsì 6/16. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/16. Ìyírọ̀padà ti First Presidency Message, March 2017. Yoruba. 97923 779