2017
Ìmúṣe Agbára Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀
March 2017


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2017

Ìmúṣe Agbára Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ka ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín Báwo ni níní òye èrò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣe nmúra àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún ìyè ayérayé?

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìranlọwọ

“Èmi lè ṣe ohun gbogbo nínú Krístì ẹnití ó nfi agbára fún mi” (Àwọn ará Fíllípì 4:13). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa ní àwọn àìlera, a lè borí wọn,” ni Ààrẹ̀ Dieter F. Uchtdorf, Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní sọ. Nítòótọ́ nípasẹ̀ oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pé tí a bá rẹ ara wa sílẹ̀ tí a sì ní ìgbàgbọ́, àwọn ohun àìlera lè di alágbára.”1

Olùgbàlà wa sọ nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú pé, “Èmi Ó lọ níwájú yín. “Èmi yíó wà ní ọwọ́ ọ̀tún yín àti ní ọwọ́ òsì, àti Ẹ̀mí mi yíó wà nínú àwọn ọkàn yín, àti àwọn ángẹ́lì mi rọ̀gbà yí i yín ká, láti gbé e yín sókè” (Ẹkọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:88).

“Nífáì ni àpẹrẹ ẹnìkan tí ó mọ̀, tí ó ní òye, tí ó sì gbọ́kàn lé agbára ìmúniṣe ti Olùgbàlà,” ni Alàgbà David A. Bednar ti Iyejú Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ. “Àwọn arákùnrin Nífáì dèé pẹ̀lú okun wọ́n sì ṣètò ìparun rẹ̀. Jọ̀wọ́ ṣe àkíyèsí àdúrà Nífáì: ‘Ah Olúwa, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ mi èyí tí ó wà nínú rẹ, njẹ́ kí ìwọ ó gbà mí lọ́wọ́ àwọn arákùnrin mi; bẹ́ẹ̀ni, àní fún mi ní okun kí èmi lè já ìdè wọ̀ny pẹ̀lú èyí tí a dè mí’ (1 Nífáì 7:17; àfikún àtẹnumọ́).

“… Nífáì kò gbàdúrà kí a yí ipò rẹ̀ padà. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gbàdúrà fún okun láti yí ipò rẹ̀ padà. Mo sì gbàgbọ́ pé ó gbàdúrà ní ọnà yí gan an nítorí ó mọ̀, ó ní òye, ó sì ti ní ìrírí agbára ìmúniṣe ti Ètùtù.

“Èmí kò rò pé ìdè pẹ̀lú èyí tí wọn de Nífáì kàn ṣe bíi idán já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ àti ọrun ọwọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, mo ní ìfura pé a bùkún un rẹ̀ pẹ̀lú méjèèjì ìtẹramọ́ àti okun araẹni tí ó kọjá agbára àdánidá rẹ̀, nígbànáà tí ó mú kí òun ‘nínú agbára ti Olúwa’ (Mòsíàh 9:17) ‘ṣiṣẹ́ tí ó yí tí ó sì ti okùn náà ní ìgbẹ̀hìn àti bi ó ṣe rí ó já àwọn ìdè náà.”2

Àfikún Àwọn Ìwé Mímọ́ àti Ìwífúnni

Ísáíàh 41:10; Ẹtérì 12:27; reliefsociety.lds.org

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. DieterF. Uchtdorf, “Ọ̀nà ti Ọmọ Ẹ̀hìn Náà,” Liahona, Oṣù Káàrún 2015, 108.

  2. DieterF. Uchtdorf, “Ẹ̀bùn ti Oore Òfẹ́ Náà,” Amọ̀nà, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2017, 4.

Tẹ̀