2017
Ìfẹ́ Pípé Nlé Ẹ̀rù Jáde
May 2017


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Kínní, Oṣù Kárún Ọdún 2017

Ìfẹ́ Pípé Nlé Ẹ̀rù Jáde

Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ẹ̀rù wa sí ẹ̀gbẹ́ kí a sì gbé pẹ̀lú ayọ̀, ìrẹ̀lẹ̀, ìrètí, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ìgboyà pé Olúwa wà pẹ̀lú wa dípò rẹ̀.

Ẹ̀yin olólùfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, irú ànfàní àti ayọ̀ tí ó jẹ́ láti pàdé gẹ́gẹ́bí Ijọ gbogbo àgbáyé tí wọ́n wà nínú ìrẹ́pọ̀ ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀.

Mo fi ìmoore hàn nípàtàkì sí olólùfẹ́ wòlíì wa, Thomas S. Monson. Ààrẹ, a ó máa fi ìgbàgbogbo fi ọ̀rọ̀ ìdarí, ìmọ̀ràn, àti ọgbọ́n yín sọ́kàn. A ní ìfẹ́ rẹ, Ààrẹ Monson à ngbàdúrà nígbà gbogbo fún un ọ.

Àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, nígbàtí mò nsìn bi ààrẹ èèkàn ní Frankfurt, Germany, arábìnrin ọ̀wọ́n kan ṣùgbọ́n tí inú rẹ̀ kò dùn dé ọ̀dọ̀ mi ní òpin ọ̀kan lára àwọn ìpàdé èèkàn wa.

“Ṣé èyí kò burú jáì?” ó wipe. “O gbọ́dọ̀ ti jẹ́ ènìyàn mẹ́rin tàbí marun to ti sùn lọ gidi ní àárín ọ̀rọ̀ rẹ!”

Mo ronú fún àsìkò díẹ̀ mo sì dáhùn, “mo mọ̀ dájú dáadáa pe oorun ìjọ wà lára àwọn tí ó nílera jù lọ lára àwọn oorun.”

Ìyàwó mi oníyanu, Harriet, gbọ́ ìbánisọ̀rọ̀ ránpẹ́ yí ó sì sọ pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdáhùn tó dára jùlọ tí mo ti fúnni.

Ìtagìrì Nlá

Bí ọgọ́ọ̀rún ọdún sẹ́hìn ní Àríwá America, ìrìn kan tí à npè ní “Ìtagìrì Nlá” tẹ́ rẹrẹ káàkiri ẹ̀gbẹ́ orílẹ̀ èdè. Ọ̀kan lára àwọn kókó ìfojúsùn àkọ́kọ́ ni jíjí àwọn ènìyàn gìrì tí ó fi ara hàn láti ma sùn ní .kàsí ti àwọn ọ̀ràn ẹ̀mí.

Joseph Smith Kékeré gba agbára nípa àwọn ohun tí ó gbọ́ láti ẹnu àwọn oníwààsù tí ó jẹ́ apákan ti ìtagìrì ẹ̀sìn yí. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èrèdí tí ó fi pinnu pẹ̀lú ìtara láti wá ìfẹ́ Olúwa nínú àdúrà àdáni.

Àwọn oníwàásù wọ̀nyí ní ọ̀nà eré, ẹ̀dùn ọkàn ìwàásù, pẹ̀lú àwọn ìkìlọ̀ tí a mọ̀ fún àtẹnumọ́ tó wúwo lórí àwọn ẹ̀rù líle ti àpáàdì tí ó ndúró de ẹlẹ́ṣẹ̀.1 Àwọn ọ̀rọ̀ wọn kò fi àwọn ènìyàn sí ipò oorun—ṣùgbọ́n wọ́n lè dá àwọn ẹ̀rù ti òru díẹ̀ sílẹ̀. Èrò wọn àti àwòṣe dàbí èyí tó ndẹ́rù ba àwọn ènìyàn wá sí ìjọ.

Ẹ̀rù gẹ́gẹ́bí Olùyínipadà

Ní ti ìwé ìtàn, ẹ̀rù ni à nlò léraléra gẹ́gẹ́bí ọ̀nà kan láti mú àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́. Àwọn òbí ti lòó pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, agbanisíṣẹ́ pẹ̀lú òṣìṣẹ́, àti òṣèlú pẹ̀lú àwọn olùdìbò.

Àwọn amòye nínú ìtajà ní òye agbára ẹ̀rù wọ́n sì nlòó lemọ́lemọ́. Èyí ni ìdí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpolówó fi dabí ẹnipé ó ngbé ọ̀rọ̀ tí ó yéni tí a kò kọ sílẹ̀ yékéyéké tí ó fi jẹ́ pé tí a bá kùnà láti ra irú ọṣẹ ìfọnu tó peye tàbí jẹ oúnjẹ àárọ̀ tó yẹ, a nsáré nínú ewu gbígbé ìgbé ayé búburú àti àdánìkankú àti àìní ìdùnnú.

A rẹrin lórí èyí a sì ronú pé a kò ní ṣubú láéláé fún iru àyípo náà, ṣùgbọ́n à nṣeé ní ìgbà míràn. Ó burújù, a nfi ìgbàmíràn lo irú ìlànà bákannáà láti mú kí àwọn míràn ṣe ohun tí a fẹ́.

Awọn ọ̀rọ̀ mi ní èrò mejì ní òní: Àkọ́kọ́ ni láti rọ̀ yín kí ẹ gbeyẹwò kí ẹ sì gbèrò dé ibi èyí tí a ó ti lo ẹ̀rù láti mú àwọn míràn ṣerànwọ́—pẹ̀lú ara wọn. Èkejì ni láti dá àbá ọ̀nà kan tó dára si.

Wàhálà pẹ̀lú Ìbẹ̀rù

Ìkínní, ẹ jẹ́ kí a yanjú wàhálà ti ẹ̀rù. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, tani lára wa tí ẹ̀rù kò fi ipá mú láti jẹun dáadáa, wọ bẹ́líìtì kan, ṣe eré ìdárayá si, fi owó pamọ́, tàbí kí a ronúpìwàdà nípa ẹ̀ṣẹ̀?

Òótọ́ ni pé ẹ̀rù ní ipá agbára lórí awọn ìṣe wa àti ìwà. Ṣùgbọ́n ipá náà máa nwà fún ìgbà díẹ̀ àti fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Ẹ̀rù ṣọ̀wọ́n sí agbára láti yí ọkàn wa padà, àti pé kò ní yí wa pàda sí àwọn ènìyàn tí ó ní ìfẹ́ sí ohun tí ó tọ́ tí wọ́n sì fẹ́ láti gbọ́nran sí Bàbá Ọ̀run.

Àwọn ènìyàn tí ó níbẹ̀rú lè sọ̀rọ̀ wọ́n sì nṣe ohun tó tọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lè ní ìmọ̀lára àwọn ohun tó tọ́. Wọ́n nní ìmọ̀lára àìnírànwọ́ lemọ́lemọ́ àti ìrunú, àní ìbínú. Ní ìgbà tó bá yá àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí yíò darí sí àíṣòótọ́, àìgbọ́ran, àní ìṣọ̀tẹ̀.

Láìlóríre, àìní ìtọ́sọ́nà yí dé ipò olórí àti ìgbé ayé ko dópin sí ẹ̀kọ́ ayé. Ó nbà mí nínú jẹ́ láti gbọ́ nípa àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n nlo ìjọba àìṣòdodo—bóyá nínú ilé wọn, nínú ìpè Ìjọ wọn, ibi iṣẹ́, tàbí nínú ìbáṣepọ̀ ojojúmọ́ pẹ̀lú àwọn míràn.

Lemọ́lemọ́, àwọn ènìyàn yí kannáà lè bá ìwá ìfìyàjẹni wí nínú àwọn ẹlòmíràn, síbẹ̀síbẹ̀ wọn kò lè rí i nínú ara wọn. Wọ́n bèèrè fún ìbámu pẹ̀lú òfin ìlàjà ti ara wọn. Nígbàtí àwọn míràn kò bá tẹ̀lé àwọn òfin àìròtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí, irú àwọn ènìyàn náà nbá wọn wí pẹ̀lú ẹnu, ẹ̀dùn ọkàn, àní nígbà míràn níti ara.

Olúwa ti sọ pé “nígbàtí a bá … lo agbára tàbí ìjọba tàbí ipá lórí àwọn ẹ̀mí ọmọ ènìyàn, ní ipòkípó ti àìṣòdodo, … àwọn ọ̀run nfa ara wọn kúrò [àti pé] Ẹ̀mí Olúwa banújẹ́.”2

Àwọn àsìkò lè wà nígbàtí a bá ní àdánwò láti dá àwọn ìṣe wa láre ní gbígbàgbọ́ pé òpin rẹ̀ jẹ́ ìdáláre fún àbájáde. Àní a lè ronú pé dídarí, yíyípo, àti ohùn líle yíò jẹ́ rere fún àwọn ẹlòmíràn. Kìí ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí Olúwa mu mọ́lẹ̀ kedere pé, “èso Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àláfíà, ìjìyà pípẹ́, ìwà pẹ̀lẹ́, ìwàrere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, [àti] ìpamọ́ra.”3

Ọ̀nà Kan Tó Dára Jù

Bí mo bá ṣe nmọ Bàbá mi Ọ̀run sí, bẹ́ẹ̀ni mo ṣe nrí I bí onímísí tí ó sì ndarí àwọn ọmọ Rẹ̀. Òun kò bínú, olùgbẹ̀san, tàbí olùdápadà.4 Èrò Rẹ̀ gan an—Iṣẹ́ Rẹ̀ àti ògo Rẹ̀—ni láti tọ́ wa sọ́nà, gbé wa ga, àti láti dari wa sí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Rẹ̀.”5

Ọlọ́run ṣe àpejúwe ara Rẹ̀ fún Mósè gẹ́gẹ́bí “olùyọ́nú àti oloore-ọ̀fẹ́, ìjìyà pípẹ́, àti ọ̀pọ̀ inúrere àti òtítọ́.”6

Ìfẹ́ Bàbá wa ní Ọ̀run fún wa, àwa ọmọ Rẹ̀, kọjá agbára wa láti ní òye rẹ̀.7

Njẹ́ èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run gbàá mọ́ra tàbí fi ojú fo àwọn ìwà tí ó tako àwọn òfin Rẹ̀? Rárá, kìí ṣe bẹ́ẹ̀!

Ṣùgbọ́n Ó nfẹ́ láti yí wa padà jù àwọn ìwà wa lọ. Ó nfẹ́ láti yí ìwà ẹ̀dá wa gan an padà. Ó nfẹ́ lati yí ọkàn wa padà.

Ó nfẹ́ kí a nawọ́ jáde kí a sì di ọ̀pá irin mú ṣinṣin, dojúkọ àwọn ẹ̀rù wa, kí a fi tìgboyàtìgboyà ṣísẹ̀ síwájú àti sókè ní ipá ọ̀nà tààrà àti tìnrin. Ó nfẹ́ èyí fún wa nítorí Ó fẹ́ràn wa, àti pé nítorí èyí ni ọ̀nà sí ìdùnnú.

Nítorínáà, báwo ni Ọlọ́run ṣe nran àwa ọmọ Rẹ̀ lọ́wọ́ láti tẹ̀lé E ní ọjọ́ wa?

Ó Rán Ọmọkùnrin Rẹ̀

Ọlọ́run rán Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Nìkanṣoṣo sí wa, Jésù Krístì, láti fi ọ̀nà tó tọ́ hàn wá.

Ọlọ́run nmu wa ṣe nkan nípa ìyílọ́kàn padà, ìjìyà-pípẹ́, ìwà pẹ̀lẹ́, ìwàtútù àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn.8 Ọlọ́run wà ní ọ̀dọ̀ wa. Ó fẹ́ràn wa, àti pé nígbatí a bá ṣubú, Ó nfẹ́ kí a dide sókè, kí a gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansi, kí a di alágbára si.

Òun ni Olùgbàlà wa.

Òun ni ìrètí nlá àti ìṣìkẹ́ wa.

Ó nfẹ́ láti ta wá jí pẹ̀lú ìgbàgbọ́.

Ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú wa láti kọ́ ẹ̀kọ́ nínú àṣìṣe wa kí a sì ṣe àwọn àṣàyàn tó tọ́.

Ọ̀nà tí ó dára jù nì èyí!9

Àwọn Ibi ti Ayé nkọ́?

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí a fi nyí àwọn ẹlòmíràn padà ni nípa dídúró lorí àní pípọ́n ibi lé nínú ayé.

Dájúdájú ilé ayé wa ti fi ìgbàgbogbo rí bẹ́ẹ̀, yíò tẹ̀síwájú lati rí bẹ́ẹ̀, àìpé. Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìmọ̀kan ti jìyà nítorí ipò ìwà ẹ̀dá bákanáà gẹ́gẹ́bí ìwà ìkà ti ènìyàn. Ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà búburú ní ọjọ́ wa tayọ ó sì nbanilẹ́rù.

Ṣùgbọ́n nínú gbogbo èyí, èmi kò ni fi ìgbé ayé ní àsìkò yi pààrọ̀ èyíkeyí ninú ìwé ìtàn ayé. A di alábùkún fún kọjá ìwọn láti gbé ni ọjọ́ ìgbéga áìro tẹ́lẹ̀, òye, àti ànfàní. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a di alábùkún láti ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Jésù Keístì, èyí tí ó nfún wa ní ìwò tó tayọ lórí àwọn ẹwu ayé tí ó sì nfi bí a ó ṣe yẹra tàbí kojúu wọn.

Nígbàtí mo ronú nípa àwọn ìbùkún wọ̀nyí, mo fẹ́ gbé orókún mi sílẹ̀ kí n gbé ohùn mi sókè nínú ìyìn tí kò lè yẹ̀ láéláé àti ìmoore sí Bàbá wa Ọ̀run fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀.

Èmi ko gbàgbọ́ pé Ọlọ́run nfẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ ní ìbẹ̀rù tàbí gbé lé orí àwọn ibi ti ayé. “Nítorí Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù, ṣùgbọ́n ti agbára, àti ìfẹ́, àti ọkàn mímọ́.”10

Ó ti fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrèdí láti yọ̀ A kàn nílò láti wárí kí a sì da wọn mọ̀ ni. Olúwa sì máa nránwa létí léraléra láti “máṣe bẹ̀rù,” àti láti tújúká,”11 àti láti máṣe “bẹ̀rù, ọ̀dọ́àgùtàn kékeré.12

Olúwa Yíò Ja àwọn Ogun Wa

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àwa ni “ọ̀dọ́–àgùtàn kékeré.” Àwa ni àwọn Ènìyàn Mímọ́ ọjọ́ ìkẹhìn. Wíwà nínu orúkọ wa ni ìfarasìn láti fi ojú sọ́nà sí ipadàbọ̀ Olùgbàlà àti ìmúrasílẹ̀ ayé láti gbà Á. Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí a sin Ọlọ́run kí a sì fẹ́ràn ọmọnìkejì wa. Ẹ jẹ́ kí a ṣe èyí pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé ẹ̀dá, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, kí a máṣe fi ojú pa ẹ̀sìn kankan míràn rẹ́ tàbí ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn. Arákùnrin àti arábìnrin, a gba àṣẹ kí a ṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti gbígbọ́ ohùn ti Ẹ̀mí, kí a lè “mọ àwọn àmì àkokò, àti àwọn àmì bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn.”13

Nítorínáà, àwà, kò ṣàìmọ àwọn ìpèníjà ayé, tàbí a kò ṣàìmọ àwọn ìṣòro ìgbà tiwa. Ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ gbé àjàgà lé ara wa tàbí àwọn míràn pẹlú ẹ̀rù lemọ́lemọ́. Dípò gbígbé lórí okun àwọn ìpèníjà wa, njẹ́ kò ní dára si láti fojú sí títóbi àìlópin, inúrere, àti agbára Ọlọ́run tó tóbi jùlọ, gbígbẹ́kẹ̀le E àti mímúrasílẹ̀ pẹ̀lú ọkàn ayọ̀ fún ìpadà bọ̀ ti Jésù Krístì?

Gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀, a kò ní láti di aláàárẹ̀ nítorí ohun tí à nbẹ̀rù pé ó lè ṣẹlẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, a lè tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ìgboyà, ìpinnu, àti ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ nínú Ọlọ́run bí a ṣe ndé ibi ìpènijà àti ànfàní níwájú.14

A kò dá rìn ní ipá ọ̀nà ọmọẹ̀hìn. “Olúwa Ọlọ́run yín … nlọ pẹ̀lú yín; òun kò ní múu yín kùnà, tàbí pa yín ti.”15

“Olúwa yíò jà fún un yín, ẹ̀yin ó sì di àláfíà yín mú.”16

Ní ojú ẹ̀rú, ẹ jẹ́ kí a rí ìgboyà wa, ní ìgbàgbọ́, kí a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí pé “kò sí ohun ìjà kan tí wọ́n gbé kò yín lójú tí yíò yege.”17

Njẹ́ à ngbé ní ìgbà ewu àti ìdàmú kan? Bẹ́ẹ̀ni à ngbée.

Ọlọ́run Funrarẹ̀ ti sọ wipé, “Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé”18

Ṣé a lè lo ìgbàgbọ́ láti gbàgbọ́ àti láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́? ṣe a lè gbé nípa àwọn ìfẹsẹ̀múlẹ̀ wa àti àwọn májẹ̀mú mímọ́? Ṣe a lè pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ àní nínú àwọn ipò ìpènijà? Bẹ́ẹ̀ni a lè ṣé!

A lè ṣé nítorí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé, “ohun gbogbo yíò ṣiṣẹ́ fún rere wa, tí [a] bá rìn ní ọ̀nà tótọ́.”19 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ẹ̀rù wa sẹgbẹ kí a gbé ìgbé ayé ayọ̀, ìrẹ̀lẹ̀, ìrètí, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ìgboyà pé Olúwa wà pẹ̀lú wa dípò bẹ́ẹ̀.

Ìfẹ́ Pípé Nlé Ẹ̀rù Jáde

Ẹ̀yin olólùfẹ́ ọ̀rẹ̀ mi, ẹ̀yin arákùnrin àtí arábìnrin mi ọ̀wọ́n nínú Krístì, tí ẹ bá rí ara yín ní gbígbé inú ìbẹ̀rù tàbí àníyàn, tàbí tí a bá ri pé àwọn ọ̀rọ̀ ti ara wa, ìwà, tàbí ìṣe nfa ẹ̀rù nínú àwọn míràn, mo gbàdúrà pẹ̀lú gbogbo okun ọkàn mi kí a lè di òmìnira kúrò nínú ẹ̀rù yí nípa òògùn ti ọ̀run tí a yàn sí ẹ̀rù: ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ti Krístì, nítorí “ifẹ́ pípé nlé ẹ̀rù jáde.”20

Ìfẹ́ pípé Krísti nnu àwọn àdánwò kúrò láti pa wá lára, dẹ́rùbà, fìyàjẹ, tàbí tẹ̀ wá mọ́lẹ̀

Ìfẹ́ pípé ti Krístì nfi àyè gbà wá láti rìn pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, ipò ọlá, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ìgboyà kan gẹ́gẹ́bí àwọn olólùfẹ́ ọmọẹ̀hìn Olùgbàlà. Ìfẹ́ pípé Krístì nfún wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé ìgboyà láti kọjá nínú àwọn ẹ̀rù wa àti láti gbé ìgbẹ́kẹ̀lé wa tó pé sí inú agbára àti inúrere Bàbá wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì.

Nínú àwọn ilé wa, ní ibi okùn òwò wa, nínú àwọn ìpè Ìjọ wa, nínú ọkàn wa, ẹ jẹ́ kí a rọ́pò ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìfẹ́ pípé Krístì. Ìfẹ́ Krístì yíò rọ́pò ẹ̀rù wa pẹ̀lú ìgbàgbọ́!

Ìfẹ́ Rẹ̀ yíò mú wa damọ̀, gbẹ́kẹ̀lé, kí a sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìwàrere Bàbá wa Ọ̀run, ètò tí ọ̀run Rẹ̀, ìhìnrere Rẹ̀, àti àwọn òfin Rẹ̀.21 Olùfẹ́ni Ọlọ́run àti àwọn ọmọlàkejì wa yíò yí ìgbọràn wa sí àwọn òfin Ọlọ́run padà sí ìbùkún ju àjàgà lọ. Ìfẹ́ Krístì yíò ràn wá lọ́wọ́ láti di dídára díẹ̀ si, olùdáríjì si, olùtọ́jú si, àti olùfọkànsìn sí iṣẹ́ Rẹ̀.

Bí a ṣe nkún ọkàn wa pẹ̀lú ìfẹ́ ti Krístì, a ó jí gìrì pẹ̀lú àtunṣe ẹ̀mí tí ọ̀tun a ó sì rìn tayọ̀tayọ̀, tìgboyàtígboyà, títají, àti ní ààyè nínú ìmọ́lẹ̀ àti ògo ti olólùfẹ́ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.

Mo jẹ́ ẹ̀rí, pẹ̀lú Àpọ́stélì John pé, “kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́ [Krístì].”22 Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, Ọlọ́run mọ̀ yín tán pátápátá. Ó fẹ́ràn yín. Ó mọ ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la Ó nfẹ́ kí a “máṣe bẹ̀rù, kí a gbàgbọ́ nìkan”23 kí a “gbé nínú ìfẹ́ [pípé] rẹ̀.”24 Èyí ni àdúrà àti ìbùkún mi ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́

  1. George Whitefield àti Jonathan Edwards ni àpẹrẹ méjì tó tayọ nípa irú oníwàásù yí.

  2. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:37

  3. Galatians 5:22–23.

  4. Ní ìgbà kan, Olùgbàlà fẹ́ wọnú ìletò ti àwọn ará Samáríà kan, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ Jésù wọn kò sì gbà Á sínú ìletò wọn. Wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí méjì lára àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ nípa èyí, wọ́n sì bèèrè, “Olúwa, ìwọ kò jẹ́ kí àwa kí ó pe iná láti ọ̀run wá, kí a sun wọ́n lúúlú?” Jésù dáhùn pẹ̀lú ìkìlọ̀ yí: “Ẹ̀yin kò mọ irú ẹ̀mí tí nbẹ nínú yín. Nítorí Ọmọ Ènìyàn kò wá láti pa ẹ̀mí ènìyàn run, bíkòṣe láti gbà á là” (wo Lúkù 9:51–56, New King James Version [1982]).

  5. Moses 1:39; bákannáà wo Ephesians 3:19.

  6. Exodus 34:6

  7. Wo Ephesians 3:19.

  8. Wo Doctrine and Covenants 121:41 Dájúdájú Ọlọ́run nretí, àwa ọmọ Rẹ̀ ayé ikú, láti hùwà ní ọ̀nà yí sí ara wọn, Òun—ẹni pipe tí ó ní gbogbo ìwàrere—yíò jẹ́ àwòṣe fún irú ìwà bẹ́ẹ̀.

  9. Ìgbìmọ̀ ìṣíwájú ayé ní Ọrun jẹ́ àgbéyẹ̀wò tó tayọ tí ó júwe ìwà Ọlọ́run. Níbẹ̀ Bàbá wa Ọ̀run gbé ètò Rẹ̀ kalẹ̀ fún ìlọsíwájú ayérayé wa. Kókó àwọn ohun èlò ti ètò náà wà pẹ̀lú agbára láti yàn, ìgbọràn, àti ìgbàlà nípa Ètùtù Krístì. Lúsífà, bákannáà, gbé ọ̀ná kan tó yàtọ̀ dìde. Ó ṣe ìgbọ̀wọ́ pé gbogbo ènìyàn yíò ní ìgbọràn—kò si ẹni tí yío sọnù. Ọnà kanṣoṣo láti ṣe àṣeyege èyí yíò jẹ́ nípa ìwà líle àti ipá. Ṣùgbọ́n olùfẹ́ni wa Bàbá Ọ̀run kò ní fi àyè gba irú ètò bẹ́ẹ̀. Ó mọ iyì agbára láti yàn àwọn ọmọ Rẹ̀. Ó mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ ṣe àṣìṣe ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà bí a ṣe nkọ́ ẹ̀kọ́ nítòótọ́. Ìdí èyí ni Ó fi pèsè Olùgbàlà kan, ẹnití irúbọ ayérayé rẹ̀ yíò wẹ ẹ̀ṣẹ̀ wa nù tí yíò sì gbà wá ní àyè láti wọlé padà sínú ìjọba Ọlọ́run.

    Nígbàtí Bàbá wa ní Ọ̀run ri pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ ọmọ Rẹ̀ ni Lúsífà ti kó wọ̀ inú wọn, ṣe ó fi ipá mú wọn láti tẹ̀lé ètò Rẹ̀? Ṣe Ó ndẹ̀rùbà tàbí halẹ̀ mọ́ àwọn wọnnì tí wọn nṣe irú àṣàyàn burúkú kan? Rárá. Ọlọ́run alágbára-gbogbo wa dájúdájú lè dáwọ́ ìṣọ̀tẹ̀ yí dúró. Ó lè fi ipá fi ìfẹ́ Tirẹ̀ lé orí àwọn olùyapa náà kí ó sì mú wọn faramọ. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, Ó fi àyè gba àwọn ọmọ Rẹ̀ láti yàn fun ara wọn.

  10. 2 Timothy 1:7.

  11. Fun àpẹrẹ, wo, Joshua 1:9; Isaiah 41:13; Luke 12:32; John 16:33; 1 Peter 3:14; Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 6:36; 50:41; 61:36; 78:18.

  12. Luke 12:32

  13. Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 68:11

  14. Àmọ̀ràn Mósè sí àwọn ènìyàn ọjọ́ tirẹ̀ ṣì jẹ́ lílò sí wa: “Máṣe Bẹ̀rù. … Wo ìgbàlà ti Olúwa, èyí tí Òun ti ṣetán fún un yín loni” (Exodus 14:13, New King James Version).

  15. Deuteronomy 31:6

  16. Exodus 14:14, New King James Version.

  17. Isaiah 54:17

  18. John 16:33

  19. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 90:24bákannáà wo; 2 Corinthians 2:14 Owuro; Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 105:14.

  20. 1 Jòhánù 4:21

  21. Ẹ jẹ́ kí a rántí pé Olùgbàlà kò wá “sínú ayé láti dá ayé lẹ́bi; ṣùgbọ́n pé kí ayé nípa rẹ̀ lè ní ìgbàlà” (John 3:17). Nítòọ́tọ́, “òun kò ṣe ohunkóhun láì jẹ́ fún èrè gbogbo ayé; nítorí ó fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ̀, tí ó fi fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kí òun lè mú gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀” (2 Nephi 26:24).

  22. 1 John 4:18; bákannáà wo 1 John 4:16.

  23. Mark 5:36

  24. John 15:10

Tẹ̀