2017
Rírántí Olúwa ní Ojoojúmọ́
October 2017


Ọdọ

Rírántí Olúwa ní Ojoojúmọ́

Àwọn Ọ̀rẹ́, iṣẹ́ ṣíṣe, iṣẹ-ilé, Amohùnmáwòrán—ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan ni ó nbèèrè fún àfojúsí wa. Ṣùgbọ́n ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, a ṣe ìlérí fún Bàbá Ọ̀run “pé [a] ó máa rántí [Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì] nígbà gbogbo” (D&C 20:79).

Ààrẹ Eyring sọ pé a lè “ṣe àwọn àṣàyàn ojoojúmọ́” tí yíò ràn wá lọ́wọ́ láti rántí Olùgbàlà. Gbèrò ṣíṣé ìlépa kan ní oṣù yí láti rántí Olùgbàlà síi ní ojoojúmọ́. Ẹ lè ṣe kàlẹ́ndà kan kí ẹ sì fi ara sí ohun kan ní ọjọ́ kan láti gbé ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Rẹ̀ ga. Ààrẹ Eyring to àwọn ohun bíi kíka ìwé mímọ́, gbígbàdúrà nínú ìgbàgbọ́, àti sísin Olùgbàlà àti àwọn ẹlòmíràn sílẹ̀. Ṣíṣe àkọsílẹ̀ bákannáà, lílọ sí àwọn ìpàdé ilé ìjọsìn, fífi etí sílẹ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, lílọ sí tẹ́mpìlì, kíkọ àwọn orin—ìtò náà kò lónkà! Bí a ṣe nrántí Olùgbàlà lójoojúmọ́, Ààrẹ Eyring ṣe ìlérí pé “àwọn ìbùkún … yíò máa wá díẹ̀díẹ̀ àti jẹ́jẹ́jẹ́ … [àti pé] yíò tún wa ṣe láti di ọmọlẹ́hìn Olúwa Jésù Krístì tòótọ́.”

Tẹ̀