2017
Kíká àwọn tí wọ́n Ṣáko Lọ̀ Mọ́ra Nínu Ìfẹ́
October 2017


Ọrọ Ìbẹniwò Kíkọni oṣ ù Kẹwaa 2017

Kíká àwọn tí wọ́n Ṣáko Lọ̀ Mọ́ra Nínu Ìfẹ́

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ṣe àṣàrò ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní òye èrò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣe nmúra àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún ìyè ayérayé?

Àwòrán
Relief Society seal

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìranlọwọ

“Òdodo náà ni pé kò sí ẹ̀bí tí ó dára tán … ,” ni Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf sọ, Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní. Àwọn whàhálà èyíówù kí ó dojúkọ ẹbí yín, èyíówù ohun tí ẹ bá gbọ́dọ̀ ṣe láti yanjú wọn, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ìyanjú rẹ̀ ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìfẹ́ àìléérí ti Krístì.”1

Nípa àwọn wọnnì tí wọn kò kópa ní kíkún nínú ìhìnrere, Linda K. Burton, Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ tẹ́lẹ̀rí, sọ pe: “Bàbá Ọ̀run fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀. … Ibi kíbi tí wọ́n lè wà—wíwà tàbí kíkúrò ní ipá ọ̀nà—Ó fẹ́ kí wọn ó padà sílé.”2

“Bí ó ti wù kí [àwọn ọmọ yín] lè ya ìpánle tó, … nígbàtí ẹ bá sọ̀rọ̀ tàbí bá wọn sọ̀rọ̀ , ẹ máṣe ṣe é nínú ìbínú, ẹ máṣe ṣe é pẹ̀lú ìkanra, nínú ẹ̀mí kíkọnisílẹ̀,” ni Ààrẹ Joseph F. Smith kọ́ni (1838-1918). “Sọ̀rọ̀ sí wọn pẹ̀lú inú rere.”3

Alàgbà Brent H. Nielson ti Àádọ́rin tún àṣẹ Olùgbàlà sọ fún àwọn wọnnì tí wọ́n ní ẹ̀là fàdákà mẹwàá tí wọ́n sọ ọ̀kan nù: “Wáa kiri títí tí ẹ ó fi ri i. Nígbàtí ọ̀kàn tí ó sọnù bá jẹ́ ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin, arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ, … lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe, a fẹràn ẹni náà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa. …

Njẹ́ kí ẹ̀yin àti èmi le gba ìfihàn láti mọ̀ bí ó ṣe dára láti lè dé ọ̀dọ̀ àwọn wọnnì nínú ayé wa tí wọ́n ti sọnù àti pé, ní ìgbà tí ó ba ṣeéṣe, láti ní sùúrù àti ìfẹ́ Bàbá wa ní Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ, Jesu Krístì, bí a ti nní ìfẹ́, nwò, tí a sì ndúró fún ọmọ onínakúná.”4

Ààrẹ Henry B. Eyring, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, sọ pe: “Mo ti gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé ẹnìkan tí mo fẹ́ràn yíò ṣe ìwákiri àti ní ìmọ̀lára agbára ti Ètùtù náà. Mo ti gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé àwọn ángẹ́lì ẹlẹ́ran ara yíò wá sí ìrànlọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wá.

“Ọlọ́run ti la àwọn ọ̀nà sílẹ̀ láti gba ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Rẹ̀ là.”5

Àfikún àwọn Ìwé Mímọ́ àti Ìwífúnni

Máttéù 18:12; Álmà 31:35; 3 Nephi 13:32; D&C 121:41–42

reliefsociety.lds.org

ÀWỌN ÀKỌSÍLẸ̀ RÁŃPẸ́

  1. Dieter F. Uchtdorf, “Nínú Ìyìn Àwọn Wọnnì tí Ó Gbàlà,” Liahona, May 2016, 79, 80.

  2. Linda K. Burton, ni Sarah Jane Weaver, “Arábìnrin Burton, Arábìnrin Wixom bẹ Ìjọ ni Agbègbè Pacific wò,” Àwọn Ìròhìn Ìjọ, Apr. 2, 2013, lds.org/church/news.

  3. >Ìdánilẹ́kọ́ ti Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph F. Smith (1998), 254.

  4. Brent H. Nielson, “Waiting for the Prodigal,” Liahona, May 2015, 103.

  5. Henry B. Eyring, “To My Grandchildren,” Liahona, Nov. 2013, 71.

Tẹ̀