2017
Níní Ìfẹ́ láti Bá Ara Wa Gbé Àjàgà
December 2017


Ọrọ Ìbẹniwò Kíkọni Oṣù Kejìlá 2017

Níní Ìfẹ́ láti Bá Ara Wa Gbé Àjàgà

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ṣe àṣàrò ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní òye èrò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣe nmúra àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún ìyè ayérayé?

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìranlọwọ

“Àwọn wọnnì tí wọ́n yí wa ká nílò àkíyèsí wa, ìgbani-níyànjú wa, àtìlẹ́hìn wa, ìtùnú wa, ìwàrere wa,” ni Ààrẹ Thomas S. Monson sọ. … Àwa ni ọwọ́ Olúwa níhĩnyi lórí ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú ìyọ̀nda lati sìnrú ati lati gbé awọn ọmọ Rẹ̀ sókè.” Ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa.”1

Ààrẹ Henry B. Eyring, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, sọ pé: “Ìyípadà nlá kan bẹ̀rẹ̀ nínú ọkàn yín nígbàtí ẹ wá sínú Ìjọ. Ẹ dá májẹ̀mú kan, kí ẹ sì gba ìlérí kan tí ó bẹ̀rẹ̀ sí nyí ìwà ẹ̀dá yín gan an padà …

“… Ẹ ṣe ìlérí pé ẹ ó ran Olúwa lọ́wọ́ láti mú àjàgà [àwọn ẹlòmíràn] fúyẹ́ kí wọ́n sí ní ìtùnú. A fún un yín ní agbára láti ṣe ìranlọ́wọ́ mú àwọn ẹrù wọnnì fúyẹ́ nígbàtí ẹ gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.”2

“A fẹ́ lo ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere láti rí àwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà ti ṣe—pẹ̀lú àánú, ìrètí, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́,: ni Jean B. Bingham, Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Irànlọ́wọ́ sọ. “Ọjọ́ náà nbọ̀ nígbàtí a ó ní òye pípé nípa ọkàn àwọn ẹlòmíràn tí a ó sì fi ìmoore hàn láti gba ìyọ́nú tí a nà sí wa— gẹ́gẹ́bí a ti nfi èrò ìfẹ́ tòótọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ sọwọ́ sí àwọn ẹlòmíràn. …

“Ojúṣe wa àti ànfàní ni láti gba ìtẹ̀síwáju mọ́ra nínú gbogbo ènìyàn bí a ṣe ntiraka láti dàbíi Olùgbàlà wa síi.”3

Bí a ṣe nbá ara wa gbé àjàgà tí a sì npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, à nṣí ọ̀na sílẹ̀ fún Jésù Krístì láti wo àwọn ẹlòmíràn sàn. Alàgbà Jeffrey R. Holland ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá kọ́ni pe: “Ní gbígbèrò iye àìlóye ti Kíkàn mọ́ agbelebu àti Ètùtù, mo ṣe ìlérí fún yín pé Òun kì yíò kọ ẹ̀hin Rẹ̀ sí wa bayii. Nígbàtí Ó sọ fún àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí, ‘Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi,’ Ó túmọ̀ sí pé Ó mọ ọ̀nà àbáyọ Ó sì mọ ọ̀nà sí òkè. Ó mọ̀ ọ́ nítorípé Ó ti rin ìrìn ibẹ̀ Ó mọ ọ̀nà náà nítorípé Òun ni ọ̀nà náà.”4

Àfikún àwọn Ìwé Mímọ

Matthew 25:40; Galatians 6:2; Mosiah 2:17; 18:8–9

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Thomas S. Monson, “Sin Olúwa pẹ̀lú ìfẹ́,” Liahona, Feb. 2014, 4.

  2. Henry B. Eyring, “Olùtùnú Náà,” Liahona, May 2015, 18.

  3. Jean B. Bingham, “Èmi ó mú Ìmọ́lẹ̀ Ìhìnrere wá sínú Ilé Mi,” Liahona, Nov. 2016, 6, 8.

  4. Jeffrey R. Holland, “Àwọn Ohun tí o Fọ́ láti Túnṣe” Liahona, May 2006, 71.