2018
Rántí Rẹ̀ Nígbàgbogbo
February 2018


Ọ̀RỌ̀ÀJỌÀÀRẸKÍNNÍ, Oṣù Kejì Ọdún 2018

Rántí Rẹ̀ Nígbàgbogbo

Njẹ́ ẹ lè wo àwòrán wòlíì Mórónì pẹ̀lú mi tí ó nkọ àwọn ọ̀rọ̀ ìparí Ìwé ti Mọ́rmọ́nì sí órí àwọn àwo idẹ? Kò ní owó kankan rárá. Ó ti rí orílẹ̀-èdè rẹ̀, àwọn ènìyàn rẹ̀, àti àwọn ẹbí rẹ̀ tí wọ́n ṣubú. Ilẹ̀ náà jẹ́ “ àyíká yíyípo kan” ti ogun (Mormon 8:8). Síbẹ̀síbẹ̀ ó ní ìrètí, nítorí òun ti rí ọjọ́ wa! Àti pé nínú gbogbo àwọn ohun tí ó lè ti kọ, ó pe wá láti rántí (wo Moroni 10:3).

Ààrẹ Spencer W. Kimball (1895-1985) fẹ́ràn láti kọ́ni pé ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìwé ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ lè jẹ́ rántí. Nítorí a ti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sọ pé, “ ohun tí a nílò tí ó tóbi jùlọ ni láti rántí” wọn.1

Ẹ lè rí ọ̀rọ̀ náà rántí káàkiri inú àwọn ìwé mímọ́. Nígbàtí Nífáì kìlọ̀ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, léraléra ó npè wọ́n láti rántí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa àti láti rántí bí Ọlọ́run ti gba àwọn bàbá wọn ìṣaájú là (wo 1 Nephi 15:11, 25; 17:40).

Nínú ọ̀rọ̀ ìdágbére nlá rẹ̀, Ọba Bẹ́njámínì lo ọ̀rọ̀ náà rántí ní ìgbà méje. Ó ní ìrètí pé àwọn ènìyàn yíò rántí “títóbi Ọlọ́run … àti ìwàrere àti ìrọ́jú rẹ” sí wọn (Mosiah 4:11; bákannáà wo 2:41; 4:28, 30; 5:11–12).

Nígbàtí Olùgbàlà ṣe àgbékalẹ̀ oúnjẹ Olúwa , Ó pe àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ láti ṣe àbápín àwọn àmì “ní ìrántí” ìrúbọ Rẹ (Luke 22:19). Ní gbogbo àdúrà oúnjẹ Olúwa ẹ̀yin àti èmí ngbọ́ ọ̀rọ̀ náà nígbàgbogbo ṣíwájú ọ̀rọ̀ náà rántí (wo D&C 20:77, 79).

Ọ̀rọ̀ mi jẹ́ ìpè kan, àní ẹ̀bẹ̀ kan, láti rántí. Nihin ni àwọn àbá mẹ́ta nípa ohun tí ẹ lè rántí ní ọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbàtí ẹ bá nṣe àbápín àmì mímọ́ ti oúnjẹ Olúwa. Mo ní ìrètí pé wọ́n yíò ṣè ìrànwọ́ fún yín, bí wọ́n ti ṣe fún mi.

Rántí Jésù Krístì

Àkọ́kọ́, ẹ rántí Olùgbàlà Rántí ẹnití Ó jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé, bí Ó ṣe sọ̀rọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, àti bí Òun ṣe fi inúrere hàn nínú ìṣe Rẹ̀. Rántí ẹnití Ó lo àkokò Rẹ̀ pẹ̀lú àti ohun tí Ó kọni. Olùgbàlà” lọ káàkíri ní ṣíṣe rere” (Acts 10:38). Ó bẹ aláìsàn wò Ó fi ẹsẹ̀ ṣíṣé ìfẹ́ Bàbá Rẹ̀ mulẹ̀.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a lè rántí iye nlá tí Ó san, nínú ìfẹ́ Rẹ̀ sí wa, láti mú àbàwọ́n àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò. Bí a ṣe nrántí Rẹ, ìfẹ́ wa láti tẹ̀lé E yíò dàgbà. A ó ní ìfẹ́ láti ní inú rere díẹ̀ síi, ní ìdáríjì síi, kí a sì fẹ́ràn síi láti wá ìfẹ́ Ọlọ́run kí a sì ṣe é.

Rántí Ohun Tí Ẹ Nílò láti Ṣe Dáradára Síi

Ó ṣòrò láti ronú nípa Olùgbàlà—ìwà mímọ́ àti pípé Rẹ̀—láì ronú bákannáà nípa bí a ṣe jẹ́ àlábùkù àti àìpé tó ní àfiwé . A ti dá àwọn májẹ̀mú láti gbọ́ran sí àwọn òfin Rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ a ndínkù lẹmọ́lemọ́ nínú òṣùwọ̀n gíga yí. Ṣùgbọ́n Olùgbàlà mọ pé èyí yíò ṣẹlẹ̀, èyí ni ìdí tí Ó fi fún wa ní ìlànà oúnjẹ Olúwa.

Oúnjẹ Olúwa ní gbòngbò rẹ̀ láti inú ìṣe ìrúbọ ètùtù ti Májẹ̀mú Láéláé, èyí tí ó ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nínú (wo Leviticus 5:5). A kìí ṣe ìrúbọ ẹranko mọ́, ṣùgbọ́n a ṣì lè jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Àwọn ìwé mímọ́ pe èyí ní ìrúbọ “irora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́” (3 Nephi 9:20). Wá sí ibi oúnjẹ Olúwa pẹ̀lú ọkàn ìrònúpìwàdà (wo D&C 59:12; Moroni 6:2). Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti pé ẹ kò ni ṣìnà kúrò ní ipá ọ̀nà tí ó ndarí padà lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Rántí Ilọsíwájú Tí Ẹ Nṣe

Bí ẹ ṣe nyẹ ìgbé ayé yín wò nínú ìlànà oúnjẹ Olúwa, mo ní ìrètí pé èrò yín kò gbé lé orí àwọn ohun tí ẹ ṣìṣe nìkan ṣùgbọ́n bákannáà lórí àwọn ohun tí ẹ ṣe dáradára—àwọn àsìkò ní ìgbàtí ẹ ti ní ìmọ̀lára pé Bàbá Ọ̀run àti Olùgbàlà dunnú síi yín Àní ẹ lè lo àkokò díẹ̀ nínú oúnjẹ Olúwa láti bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti ràn yín lọ́wọ́ láti rí àwọn ohun ìwọ̀nyí. Tí ẹ bá ṣeé, mo ṣe ìlérí pé ẹ ó ní ìmọ̀lára ohun kan. Ẹ ó ní ìmọ̀lára ìrètí

Nígbàtí mo ṣe èyí, Ẹ̀mí náà ti tún múu dámilójú pé bí mo tilẹ̀ ṣì wà ní ọ̀nà jíjìnà sí pípé, mo dára si loni ju bí mo ṣe wà lana lọ. Àti pe èyí fún mi ní ìgboyà pé, nítorí Olùgbàlà, mo lè dára síi ní ọ́jọ́ ọlà.

Nígbàgbogbo jẹ́ ìgbà pípẹ́, ó já sí aápọn àfojúsí púpọ̀ jọjọ. Ẹ mọ̀ nípa ìrírí bí ó ti le tó láti ronú taratara nípa ohun kan ní gbogbo ìgbà. Ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ẹ pa ìlérí yín mọ́ dáradára tó láti rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo, Òun yíò rántí yín nígbàgbogbo.

Olùgbàlà mọ àwọn ìpènijà yín. O mọ bí ó ti rí láti ní àwọn àníyàn ayé tí ó tẹ̀ mọ́ orí yín. Ó mọ̀ bí ó ṣe jẹ́ kánjúkánjú sí tí ẹ nílò ìbùkún tí ó nwá láti inú rírántí Rẹ̀ nígbàgbogbo àti gbígbọ́ran sí I—“kí [ẹ] lè ní Ẹ̀mí rẹ̀ pẹ̀lú [yín] nígbàgbogbo” (D&C 20:77; àfikún àtẹnumọ́).

Nítorínáà, Ó nkíi yín káàbọ̀ padà sí tábìlì oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, ní fífún yín ní ààyè lẹ́ẹ̀kansíi láti jẹ́ ẹ̀rí níwájú Rẹ̀ pé ẹ ó rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo.

Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Spencer W. Kimball, “Agbo Ìgbéga” (address to Church Educational System religious educators, June 28, 1968), 5.