2021
Ọlọ̀run Wí Fún Wa Kí a Ṣe Ìrìbọmi
Oṣù Kejì (Èrèlé) 2021


“Ọlọ́run Wí Fún Wa Kí A Ṣe Ìribọmi,” Làìhónà, Ọṣù Ìkejì (Èrèlè) 2021

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Ìkejì (Èrèlé) 2021

Ọlọ̀run Wí Fún Wa Kí A Ṣe Ìrìbọmi

Jésù Krístì fi àpẹrẹ kan lélẹ̀ nípa ṣíṣe ìrìbọmi nípasẹ̀ ẹnìkan pẹ̀lú àṣẹ Ọlọ́run.

Nígbàtí ti a kò ní àpèjúwe kíníkíní púpọ̀ nípa igbé-ayé araẹni ti Jésù Krístì, a mọ̀ pé Ó ṣe ìrìbọmi nígbàtí ó wá ní ọmọ ọjọ̀-orí ọgbọ̀n ọdún (wo Lúkù 3:23). Nihin ni àwọn ohun tí a kọ́ nípa ìrìbọmi látinú àpẹrẹ Rẹ̀.

Fún Gbogbo Ènìyàn

Tí a bá dàgbà tó láti sọ ìyàtọ̀ ní àárín ẹ̀tọ́ àti àṣìṣe, Baba Ọ̀run nfẹ́ kí a ṣe ìrìbọmi (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:42). Jésù jẹ́ pípé, ṣùgbọ́n síbẹ̀ Ó yàn láti ṣe ìrìbọmi láti tẹ̀lé àwọn òfin Ọlọ́run (wo Máttéù 3:13–17; 2 Néfì 31:7). Àní kí àwọn ẹni tí ó ti kú lè tẹ́wọ́gba ìrìbọmi. A fi fún wọn nípa ṣíṣe ìrìbọmi fún wọn nínú tẹ́mpìlì. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 128:15–18.)

Àwòrán
ìrìbọmi

Ṣeé nípa Àṣẹ

Jésù kò ṣe ìrìbọmi nípasẹ̀ ẹnìkan lásán. Nípàtàkì Ó lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin Rẹ̀ Jòhánù, ẹni tí ó ní àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Lẹ́hìn tí Jésù kú àti tí a pa àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀, ni àṣẹ oyè-àlùfáà ti sọnù kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Lẹ́hìnnáà, ní 1829, Jòhánù Onírìbọmi farahàn sí Joseph Smith ó sì fún ní àṣẹ láti ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Ọlọ́run. Nítorí ìmúpadàbọ̀sípò náà, a lè ṣe ìrìbọmi pẹ̀lú irú àṣẹ kannáà ní òní.

Àwòrán
ìmúpadàbọ̀sípò Oyèàlùfáà ti Árọ́nì

Ìlérí Ọ̀nà-Méjì Kan

Ìrìbọmi pẹ̀lú ìlérí ọ̀nà-méjì kan, tàbí májẹ̀mú, ní àárín wa àti Ọlọ́run. A ṣe ìlérí.

  1. Láti gbé orúkọ Krístì lé orí ara wa.

  2. Láti rántí Rẹ̀ nígbà-gbogbo.

  3. Láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.

Ní àbábọ̀, Ọlọ́run ṣe ìlérí pé Ẹ̀mí Rẹ̀ yíò wà pẹ̀lú wa nígbà-gbogbo. Àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà oúnjẹ-Olúwa rán wá létí nípa májẹ́mú yí ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. (Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77, 79.)

Àwòrán
ẹbí nínú ìpàdé oúnjẹ-Olúwa

Gbígba Ẹ̀mì Mímọ́ Jẹ́ Apákan pàtàkì ti Ìrìbọmi.

Lẹ́hìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, Ẹ̀mí Mímọ́ fafahàn ní ara àdàbà (wo 2 Néfì 31:8). Ní òní, lẹ́hìn tí àwọn ẹ̀nìyàn bá ṣe ìrìbọmi, wọ́n ṣe ìfẹsẹ̀múlẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n gba ìbùkún pàtàkì kan nínú èyí tí a pè wọ́n láti gba ìwẹ̀nùmọ́ ti ẹ̀bùn ẹ̀mí (wo 2 Néfì 31:17). Ẹ̀mí Mímọ́ lè kìlọ̀ fún wa nípa ewu, tù wá nínú, tọ́ wa sọ́nà láti ṣe àwọn ìpinnu rere, àti láti ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 39:6).

Àwòrán
Obìnrin tí ó nṣe ìfẹsẹ̀múlẹ̀

A Lè Ronúpìwàdà Nígbà-gbogbo

Ọlọ́run mọ̀ pé a ó ṣe àwọn àṣìṣe. Pẹ̀lú àwọn ìtiraka dídarajùlọ wa, a ó dẹ́ṣẹ̀ a ó sì kùnà gbígbé déédé sí àwọn ìlérí ìrìbọmi wa. Nítorínáà Ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ààyè láti ronúpìwàdà. (Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:13.) Ojojúmọ́ a lè sa ipá wa láti bẹ̀bẹ̀ kí a sì ṣe àtúnṣe àwọn àṣìṣe wa. A lè gbàdúra kí a sì bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìdáríjì. Lẹ́hìnnáà, nígbàtí a ba jẹ oúnjẹ-Olúwa pẹ̀lú ọkàn ìrẹ̀lẹ̀, a lè ní Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú wa (wo 3 Néfì 18:11).

Àwòrán
obìnrin ngbàdúra ní ẹ̀gbẹ́ bẹ́ẹ̀dì

Kíni àwọn Ìwé-mímọ́ Wí Nípa Ìrìbọmi?

Àwọn òbí gbọ́dọ̀ ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún ìrìbọmi (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 68:25).

Àwọn tí ó kéré ju ọmọ ọdún mẹ́jọ kò nílò ìrìbọmi (wo Moroni 8).

Nígbàtí a bá ṣe ìrìbọmi, a ṣe ìlérí láti “sọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tí nṣọ̀fọ̀; … tu àwọn tí ó fẹ́ ìtùnú nínú, àti láti dúró gẹgẹbí àwọn ẹlẹri Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo àti nibi gbogbo” (Mosiah 18:9).

Tẹ̀