“Jésù Ṣe Ìrìbọmi,” Fríẹ́ndì, Oṣù Ìkejì (Èrèlé) 2021
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Frẹ́ndì, Oṣù Ìkejì (Èrèlé) 2021
Jésù Ṣe Ìrìbọmi
Jòhánù Onírìbọmi jẹ́ wòlíì nlá kan. Ó kọ́ àwọn ènìyàn láti ronúpìwàdà kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi wọn.
Ní ọjọ́ kan Jòhánù nṣe ìrìbọmi fún àwọn ènìyàn nínú Odò Jọ́dánì. Jésù wá ó sì ni kí Jòhanù ṣe ìrìbọmi fún Òun. Jòhánù mọ̀ pé Jésù kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Nítorínáà kínìdí tí Jésù fi fẹ́ ṣe ìrìbọmi?
Jésù wípé Òun nílò láti gbọ́ran sí gbogbo àwọn òfin. Ṣíṣe ìrìbọmi jẹ́ òfin kan.
Lẹ́hìn tí Jòhánù ṣe ìrìbọmi fún Jésù, ẹyẹ-àdàbà kan wá láti fihàn pé Ẹ̀mí Mímọ́ wà níbẹ̀. Ohùn Bàbá Ọ̀rún wá láti ọ̀run, ó wípé, “Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi” (Máttéù 3:17).
A lè gbọ́ran sí àwọn òfin kí a sì yàn láti ṣe ìrìbọmi, bíiti Jésù. Lẹ́hìnáà a le gba ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú.
© 2020 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Ìkínní (Èrèlé) 2021. Yoruba. 17464 000