2021
Ìtẹ̀síwájú Ìfihàn
Oṣù Kẹ́ta 2021


“Ìtẹ̀síwájú Ìfihàn,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹta 2021, 16.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹta 2021.

Ìtẹ̀síwájú Ìfihàn

Láti inú ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò kan ti Oṣù Kẹ́rin 2020.

Wòlíì Joseph Smith gba ìfihàn lẹ́yìn ìfihàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfihàn nípasẹ̀ Wòlíì Josèph ni a ti fi pamọ́ fún wa nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú.

Ní àfikún, a di alábùkúnfún pẹ̀lú ìfihàn tó ń tẹ̀síwájú sí àwọn wòlíì alààyè tí a “fifun wọ́n jẹ́ aṣojú Olúwa, tí wọ́n sì láṣẹ láti sọ̀rọ̀ fún Un.”1

Ìfihàn araẹni bákannáà wà fún gbogbo àwọn tí wọ́n ńfi ìrẹ̀lẹ̀ wá ìtọ́nisọ́nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Ó ṣe pàtàkì bíi ti ìfìhàn wòlíì.

Ìfihàn ti ara ẹni dá lórí àwọn òtítọ́ ti ẹ̀mí tí a gbà láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí Mímọ́ ni olùfihàn àti olùjẹ́ri gbogbo òtítọ́, ní pàtàkì èyí ti Olùgbàlà. Láìsí Ẹ̀mí Mímọ́, a kò lè mọ̀ dájúdájú pé Jésù ni Krístì. Ojúṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ̀ Rẹ ni láti jẹ́ ẹ̀rí nípa Bàbá àti Ọmọ àti àwọn Àkórí Wọn àti ògo Wọn.

Mo mu dá yín lójú pé a lè gba ìtọ́nisọ́nà ti ìfihàn nípasẹ̀ bí ẹnì kọ̀ọkan wa bá ṣe ń fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà Olúwa.

Ẹ̀bẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀ mi ni pé kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yíò wá ìtẹ̀síwájú ìfihàn láti darí ayé wa, kí á sì tẹ̀lé Ẹ̀mí bí a ṣe ń sin Ọlọ́run Baba àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.

Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Hugh B. Brown, “Joseph Smith ní àárín àwọn Wòlíì” (Ìwàásù Ìrántí Ọlọ́dọọdún Joseph Smith Kẹrìndínlógún, Logan Institute of Religion, Dec. 7, 1958), 7.

Tẹ̀