”Jésù Krístì Ní Kí Á Má a Jẹ Oúnjẹ Olúwa”, Làìhónà, Oṣù Kẹta 2021
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà Oṣù Kẹta 2021
Jésù Krístì Ní Kí Á Má a Jẹ Oúnjẹ Olúwa
À ńní ìwòsàn àti ìwẹ̀númọ́ bí a ṣe ńrántí Olùgbàlà wa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.
Ṣíwájú ikú Rẹ̀, Jésù Krístì jẹ oúnjẹ kan tó kẹ́hìn tí à pè ní Oúnjẹ alẹ́ Olúwa. Ní òpín oúnjẹ náà, Ó fi oúnjẹ Olúwa hàn sí áwọn àtẹ̀lẹ́ Rẹ̀. Ó ja búrẹ́dì ó sì súre sí i. “Ṣe èyí ní ìrántí mi,” ni O wí (Luku 22:19). Lẹ́hin rẹ̀ Ó súre sí i, ó sì pín ife wáìnì fún wọn.
Ara àwọn Ìjọsìn Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀
Nígbà tí wọ́n ṣe ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Jésù Krístì sí ayé, oúnjẹ Olúwa di ara ìjọ́sìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ní ákokò ìjọsìn, àwọn tí ó di oyèàlúfà mú yíò bùkún oúnjẹ Olúwa, wọn yíò sì ṣe àbápín rẹ̀. Wọ́n gbàdúrà pẹ̀lú lílo àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé-mímọ́ (wo Moroni 4; 5). Lẹ́hìn èyí ni ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ìjọ yíó jẹ búrẹ́dí tí wọn yíò sì mu omi láti rántí Jésù Krístì àti ìrúbọ Rẹ̀ fún wa, gẹ́gẹ́ bí Ó ti wí fún wa láti ṣe.
Múrasílẹ̀ láti ṣe Àbápín
Láti gbáradì fún oúnjẹ alẹ́ Olúwa, a gbọ́dọ̀ ronú nípa àwọn ìgbé ayé wa àti àṣàyàn wa lódodo. A gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ wa ti ọ̀sẹ̀ tó kọjá, pẹ̀lú bíbèèrè ìdáríjì lọ́wọ́ Ọlọ́run. A kò níláti jẹ́ pípé kí a tó jẹ oúnjẹ Olúwa, sùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.
Jú Búrẹ́dì àti Omi lọ
Jíjẹ oúnjẹ Olúwa jẹ́ àkókò ọ̀wọ̀, mímọ́ kan. Àwọn àdúrà oúnjẹ Olúwa rán wa létí pé bí a ṣe ńjẹ́ búrẹ́dì, tí à ńmú omi, à ńrántí ara àti ẹ̀jẹ̀ tí Jésù Krístì fi fún wa. A ṣèlérí láti tẹ̀lé E kí á sì gbé ìgbé-ayé krìstẹ́nì. A ṣèlérí láti gbìyànjú láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Ní àbábọ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ yíó ma tùwá nínú, tọ́wa sọ́nà, àti wò wá sàn.
Àtúnṣe àwọn Májẹ̀mú
Nígbà tí àwa tí a ti ṣe ìrìbọmi bá jẹ oúnjẹ Olúwa pẹ̀lú ọkàn mímọ́, à ńtú àwọn májẹ̀mú tí a dá ní àkókò ìrìbọmi ṣe. Nínú èyí ní gbígba Ẹ̀mí Mímọ́ àti jíjẹ́ ìwẹ̀númọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni wípé a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ìrìbọmi ṣe lẹ́ẹ̀kansi. Èyí ni ìrètí àti àánú tí Jésù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Kò tí ì pẹ́jù rárá láti ronúpìwàdà kí á sì gba ìdáríjì.
Kínni Àwọn Ìwé Mímọ́ Sọ nipa Oúnjẹ Olúwa?
Kí á se àyẹ̀wò ara wa níti ẹ̀mí, kí a wo ara wa dénú pẹ̀lú òdodo, kí á tó jẹ oúnjẹ Olúwa (wo 1 Corinthians 11:28).
Lẹ́hìn tí Ó jíǹde, Jésù fi àwọn ènìyàn Rẹ̀ hàn ní àwọn Amẹ́ríkà bí wọn ó ti máa jẹ́ oúnjẹ Olúwa (wo 3 Néfì 18).
Àwọn wòlíì òde-òní sọ fún wa wípé kí á lo búrẹ́dì àti omi fún oúnjẹ Olúwa, ṣùgbọ́n ohun tí à ńjẹ tàbí mu kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ nkan (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 27:2). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbá àwọn tó ní ẹ̀hún ara nílò láti lo ohun míràn tó dàbí búrẹ́dì.
© 2020 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà Oṣù Kẹta 2021. Yoruba. 17466 000