2021
Ṣe Ohun Kíkọsílẹ̀
Oṣù Kéje 2021


“Ṣe Ohun Kíkọsílẹ̀,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kéje 2021, 18–19.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kéje (Agẹmọ) 2021.

Ṣe Ohun Kíkọsílẹ̀

Kíkọ àwọn èrò yín sílẹ̀ bí ẹ ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ lè ràn yín lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ nítòótọ́.

“Gbogbo ìgbà tí mo bá ti nka àwọn ìwé-mímọ́, ni mo máa nsùn lọ!” ni ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wí fún ààrẹ míṣọ̀n rẹ̀. “Ó dàbíí pé àwọn ìwé-mímọ́ jẹ́ ògùn oorun!”

Ààrẹ rẹ̀ fèsì, “Njẹ́ ìwọ máa nṣe àkọsílẹ̀ nígbàtí ó bá nkàwé?”

“Rárá,” ni ìránṣẹ́ ìhìnrere wí.

Ààrẹ wípé, “Ó rọrùn láti sùn lọ tàbí jẹ́ kí ọkàn rẹ ṣáko nígbàtí o bá nkàwé nìkan,” “ṣùgbọ́n kò ṣeéṣe nígbàtí o bá fi kíkọsílẹ kun!”

Àmọ̀ràn tí ààrẹ míṣọ̀n yí fún ìrànṣẹ́ ìhìnrere rẹ̀ tí ó nlàkàkà mú ìyàtọ̀ nlá wá. Nítorínáà bí ẹ bá nwá ọ̀nà titun kan láti fún àṣàrò ìwé-mímọ́ yín lókun, ẹ ṣe ìtiraka rẹ̀. Bí ẹ ti nkọ nípa ohun tí ẹ kà, bákannáà, ẹ ó rí arayín ní ṣíṣe àti kíkọ́ ẹkọ dáradára si.

Ní ìhín ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí a ti rí tí ó wúlò nítòótọ́.

Arákùnrin Steven Lund:

Steven Lund

Mo nmú ìwé dáni nígbàtí mo bá nkàwé. Bí Ẹ̀mí ṣe nṣí mi létí nígbà àṣàrò mi, ni mo nkọ àwọn ìṣílétí sílẹ̀.

Mó gba èrò náà láti ọwọ́ Alàgbà Richard G. Scott (1928–2015) ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, tí ó wípé: “Ẹ kọ àwọn ohun pàtàkì tí ẹ kọ́ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí sílẹ̀ sí ìbi ààbò. Ẹ ó ri pé bí ẹ ti nkọ àwọn ìtẹ̀mọ́ra iyebíye sílẹ̀, léraléra ní ọ̀pọ̀ yíò wá si. Bákannáà, ni ìmọ̀ tí ẹ jèrè yíò wà ní gbogbo ọjọ́ ayé yín” (“Láti Gba Ìmọ̀ àti Okun láti Lò Ó Pẹ̀lú Ọgbọ́n,” Ensign, Oṣù Kẹfà 2002, 32).

Mo mọ pé àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì jẹ́ òtítọ́. Bí mo ṣe nmúra àwọn ọ̀rọ̀ àti ẹ̀kọ́ sílẹ̀, èmi kò lọ sínú ìwé-mímọ́ nìkàn ṣùgbọ́n bákannáà sínú ohun tí mo ti kọ sílẹ̀ nígbàtí mò nkà wọ́n.

Arákùnrin Ahmad Corbitt:

Ahmad S. Corbitt

Mo fẹràn láti ṣe àṣàrò pẹ̀lú àkórí ọ̀rọ̀. Mo ka àwọn ìwé-mímọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ṣùgbọ́n bákannáà mo fẹ́ràn láti yí káàkiri kí nsì ṣe àṣàrò àwọn àkórí ọ̀rọ̀. Fún àpẹrẹ, èmi yíò lo Ìtọ́nisọ́nà Àkórí-ọ̀rọ̀ láti wá àwọn ìwé-mímọ́ lórí ìgbàgbọ́ tàbí ìkórajọ Ísráẹ́lì. Llẹ́hìnnáà èmi ko kọ àkọsílẹ̀ lásán, ṣùgbọ́n mo nkọ ohun tí mo kọ́ láti mu dájú pé mo ní òye rẹ̀ nítoótọ́. Èmi nfi ìgbàgbogbo ní ìyàlẹ́nu ní ọ̀pọ̀ bí mo ti ní òye àwọn nkan dáradára si nígbàtí mo bá ṣe èyí. Bákannáà mo yan láti kọ́ àwọn ìwé-mímọ́ díẹ̀ sórí.

Arákùnrin Bradley Wilcox:

Bradley Wilcox

Mo tọ́jú ìwé-ìròhìn àṣàrò kan níbití mo kọ àwọn ìwé-mímọ́ sí ní àwọn ọ̀rọ̀ arami. Fún àpẹrẹ, “Nítorí ènìyàn ẹlẹ́ran ara jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run ” (Mosiah 3:19) ó di “Nítorí pé olùgbéraga àti aláìronúpìwàdà ènìyàn yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kìí ṣe ọ̀tá rẹ̀. Ọlọ́run ni ọ̀rẹ́ dídárajùlọ rẹ̀.”

Bákannáà mo kọ àwọn ìbèèrè. Àwọn ìbèèrè tí mò nronú nípa wọn ṣíwájú kí ntó kàá, tàbí wọ́n lè jẹ́ àwọn ìbèèrè tí ó rú jádé nípasẹ̀ ohun tí mo kà. Ọ̀nà èyíówù, ó nmú mi ní ìdojúkọ.

Agbára Kíkọ Àwọn Èrò Yín Sílẹ̀

Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nínú àjọ ààrẹ wa nṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo wa nkọ ọ́ bí a ti ṣe!

Kíkà nràn wá lọ́wọ́ láti fi àwọn èrò àti ìmọ̀lárá sínú. Ìyẹn ṣe pàtàkì. Àti pé nígbàtí a bá sọ̀rọ̀ tàbí kọọ́ sílẹ̀, à nrí a sì nfi àwọn èrò àti ìmọ̀lára hàn láti inú wá sí ìta. A ní ìmọ̀lára tí ó nrànwálọ́wọ́ láti sọ àwọn òtítọ́ ìhìnrere di ti araẹni wa dáradára si.

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ṣe àwárí òtítọ́ yí fún ararẹ̀ nígbàtí a ní kí ó fúnni ní ọ̀rọ̀ kan nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa. Òun gbọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn míràn ti fúnni ní àwọn ọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n kò lè rántí àwọn àlàyé. Àkokò yí ti yàtọ̀. Nígbàtí ó kọ ìlà jáde fún ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, kìí ṣe pé ó ràn án lọ́wọ́ láti gbé ọ̀rọ̀ tó létò kalẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ó rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́.

Ohun kannáà lè ṣẹlẹ̀ nínú àṣàrò ìwé-mímọ́ yín. Bí ẹ bá nsùn lọ nígbàtí ẹ nṣí àwọn ìwé-mímọ́ yín, ó tó àkokò láti jí dìde. Ẹ tiraka láti mú lẹ́ẹ̀dì, pẹ́ẹ̀nì, fóònù, tàbí ayélujára kan jáde kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ kíkọsílẹ̀. Yíò yà yín lẹ́nú ní irú ìyàtọ̀ tí ẹ lè ṣe!