2021
Baba Wa Ọ̀run Nfẹ́ Kí A Ní Ìdùnnú
Oṣù Kéje 2021


“Baba Wa Ọ̀run Nfẹ́ Kí A Ní Inúdídùn,” Liahona, Oṣù Kéje 2021

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kéje (Agẹmọ) 2021

Baba Wa Ọ̀run Nfẹ́ Kí A Ní Ìdùnnú

Bí a ti nrántí ètò ìdùnnú Ọlọ́run, a lè rí ayọ̀ àní nígbàtí ìgbé ayé bá le.

Krístì pẹ̀lú àwọn ọmọ

Ṣíwájú kí a tó bí wa sí orí ilẹ̀-ayé, gbogbo wa gbé pẹ̀lú Baba Ọ̀run bí àwọn ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀. Ó gbé ètò kan kalẹ̀ láti ran àwọn ọmọ Rẹ̀ lọ́wọ́ láti kẹkọ àti láti dàgbà. Nípasẹ̀ ètò Rẹ̀, a lè dà bíi Tirẹ̀ kí a sì jẹ́ yíyẹ láti gbádùn ìyè ayérayé. Ètò yí ṣeéṣe nítorí Ọmọ Ọlọ́run, Jésù Krìstì, wá sí ilẹ̀-ayé láti jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìrúbọ kan tí a pè ní Ètùtù.

Ètò Baba Ọ̀run ni a pè ní ètò

Bí àwọn ìwọ̀nyí àti ìwé-mímọ́ míràn ti fihàn pé, Baba Ọ̀run nfẹ́ kí a dàbíi Tirẹ̀, padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, kí a sì ní ìdùnnú nítoótọ́ (wo Mose 1:39).

A Wá sí Ilẹ̀-ayé láti Kẹkọ àti láti Dàgbà

Ọlọ́run rán wa wá sí ilẹ̀-ayé, níbití a ti lè ní ara àfojúrí (wo Genesis 1:26–27). A nílò àwọn ara láti ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìrírí ìgbé ayé ní orí ilẹ̀-ayé.

Ọlọ́run mọ̀ pé a kò ní ní ìmọ̀lára ìdùnnú ní gbogbo ìgbà. A nní ìrírí àwọn ìjákulẹ̀, ìrora, àní àti ikú. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ àwọn ìpènijà ti ayé, Baba Ọ̀run nràn wá lọ́wọ́ láti kẹkọ àti láti dàgbà.

Ọlọ́run fún wa ní ìṣojuẹni, agbára láti yàn ní àárín ire àti ibi. Òun njẹ́ kí a yàn ohun tí a bá ro àti tí a ṣe fún arawa. Ó ti fún wa ní àwọn ìwé-mímọ́ àti àwọn wòlíì àlàyè láti ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ láti yan ohun tí ó tọ́ (wo Abraham 3:25).

igi ìyè

Tiraka làti Dàbíi Jésù Krístì

Ọlọ́run kò rán wá wá sí ilẹ̀-ayé láìsí àpẹrẹ kan láti tẹ̀lé (wo Johannu 13:15). Ó rán Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, láti fi ọ̀nà hàn wá. Láti kọ́ bí a ó ti tẹ̀le É, a lè ka àwọn ìwé-mímọ́ láti kọ́ ẹní tí Ó jẹ́ àti ohun tí Ó ṣe ní ìgbà ìgbé ayé Rẹ̀ ní orí ilẹ̀-ayé. Bákannáà a lè ṣe dídára si láti dàbíi Krístì nípa gbígbọ́ran sí Ọlọ́run àti fífẹ́ àwọn ẹlòmíràn.

Nígbàtí a bá ṣe àwọn àṣìṣe, à nbèèrè fún ìdáríjì a sì nfà lórí agbára ètùtù Jésù Krístì láti ràn wá lọ́wọ́ láti yípadà. A lè ní ìdùnnú bí a ṣe ntiraka lojojúmọ́ láti dàbíi Tirẹ̀ Síi.

Ikú Kìí Ṣe Òpin

Nígbàtí a bá kú, àwọn ẹ̀mí wa lọ sí ayé ẹ̀mí. Níbẹ̀ a ó tẹ̀síwájú láti kọ́ bí a ó ti múrasílẹ̀ fún Àjínde.

Ní ìgbà Àjínde, àwọn ara àti ẹ̀mí wa yíò darapọ̀. Àwọn ara wa yíò jẹ́ pípé, a kò sì ní jìyà ikú àti àìsàn mọ́ láéláé (wo Alma 11:44–45). Gẹ́gẹ́ bí Jésù Krístì ti kú tí ó sì wá sí ayé lẹ́ẹ̀kansi, gbogbo wa yíò gbé lẹ́ẹ̀kansi.

Nígbàtí Ọlọ́run bá ṣe ìdájọ́ wa, Òun yíò yẹ àwọn ìṣe wa àti ìfẹ́ wa wò. Bí a bá tiraka láti pa àwọn òfin mọ́ àti àwọn ìlérí tí a ṣe sí Baba Ọ̀run, lẹ́hìnáà a lè gbé pẹ̀lú Rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi.

Ìgbé-ayé pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn Ẹbí Wa ní Ọ̀run

Nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà, a ó gbé pẹ̀lú Ọlọ́run àti Jésù Krístì. Bákannáà a ó lè gbé níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbí wa títíláé bí a bá ṣe èdidì pẹ̀lú wọn. A lè rí àláfíà, ìdùnnú, àti ìsinmi (wo Mosiah 2:41).

Ìgbé ayé wa ní orí ilẹ̀-ayé lè nira nígbàmíràn, ṣùgbọ́n bí a bá tẹ̀lé Jésù Krístì, a lè rí ayọ̀ ní ayé yí àti ìdùnnú ayérayé ní ayé tí ó nbọ̀.

Kínni Àwọn Ìwé Mímọ́ Sọ nipa Ètò Ìdùnnú?

Ọ̀nà tí a fi ngbé ìgbé ayé wa ṣe pàtàkì. Ọlọ́run yíò dájọ́ àti fún wa lérè gẹ́gẹ́bí àwọn èrò àti ìṣe wa (wo Alma 41:3).

Sátánì ni ọ̀tá sí ìdùnnú wa. Ó ndán wa wò láti ṣi ìgbé ayé wa ní orí ilẹ̀-ayé lo àti láti dẹ́ṣẹ̀. Ó nfẹ́ kí a di oníbànújẹ́ bíi tirẹ̀ (wo 2 Néfìi 2:27).

Nígbàtí a bá ní ìgbàgbọ́ nínú ètò Ọlọ́run fún wa, a lè ní àláfíà èyíówù àwọn àdánwò tí a lè dojúkọ. A lè wo iwájú sí gbígbé pẹ̀lú Ọlọ́run títíláé (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 59:23).

Gbogbo iṣẹ́-ọnà nípasẹ̀ J. Kirk Richards