“Àwọn Ìrìnàjò Iṣẹ́-ìránṣẹ́ Páùlù,” Fríẹ̀ndì, Oṣù Kẹ́wàá 2021
“Àwọn Ìrìnàjò Iṣẹ́-ìránṣẹ́ Páùlù”
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ̀ndì, Oṣù Kẹ́wàá 2021
Àwọn Ìrìnàjò Iṣẹ́-ìránṣẹ́ Páùlù
Àpóstélì Páùlù rin ìrìnàjò lọ si àwọn ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti kọ́ àwọn ènìyàn nípa Jésù. Kò sí àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí ọkọ̀ òfúrufú nígbà náà, nítorínáà o rìn lọ́pọ̀lọpọ̀! Nígbàmíràn ó rìn ìrìnàjò pẹ̀lú ọkọ̀ ojú-omi.
Páùlù kọ́ àwọn ènìyàn nínú àwọn ìjọ àti ilé. Ó kọ́ àwọn ènìyàn ní orí òkè àpáta àti òpópónà àwọn ìlú-nla.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn kò fẹ́ràn ohun tí Páùlù kọni. Nígbàmíràn a ti rán Páùlù lọ sí túbú. Nígbàmíràn Páùlù ṣàìsàn.
Ṣùgbọ́n nínú gbogbo àwọn ohun líle wọ̀nyí, Páùlù ní ìgbàgbọ́. Ó wípé, “Mo lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Krístì.” Ó mọ̀ wípé Jésù yio ràn òun lọ́wọ́ láti ní agbára.
Jésù Krístì lè ràn mí lọ́wọ́ láti ní agbára bákanáà. Ó nifẹ mi, àti pé mo nifẹ Rẹ̀!
© 2021 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Fríẹ̀ndì, Oṣù Kẹ́wàá 2021. Yorùbá 17474 000