2021
Iṣẹ́ Tẹ́mpìlì
Oṣù Kẹ́wàá (Ọ̀wàwà) 2021


“Iṣẹ́ Tẹ́mpìlì,” Làìhónà, Oṣù Kẹ́wàá 2021

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹ́wàá (Ọ̀wàwà) 2021

Iṣẹ́ Tẹ́mpìlì

Àwọn Tẹ́mpìlì jẹ́ ilé Olúwa. A lè gba àwọn ìlànà kí a ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ ní àwọn tẹ́mpìlì. A tún lè ṣe àwọn ìlànà ní tẹ́mpìlì fún àwọn bàbánla.

Àwòrán
tẹ́mpìlì

Àwòrán Tẹ́mpìlì Barranquilla Colombia láti ọwọ́ Bruno Lima

Ninu gbogbo àkọsílẹ̀-ìtàn, Olúwa ti pàṣẹ fún àwọn ènìyàn Rẹ lati kọ́ àwọn tẹ́mpílì. Àwọn Tẹ́mpìlì jẹ́ ibi mímọ́ tí a ti lè ní ìmọ̀lara ìfẹ́ Ọlọ́run, gba àwọn ìlànà, àti láti ṣe àwọn ìlérí pẹ̀lú Rẹ. Ìjọ nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì káàkiri àgbáye kí àwọn ènìyàn púpọ̀ àti púpọsi lè ní àwọn ìbùkún wọ̀nyí.

Àwòrán
obìnrin ní iwájú tẹ́mpìlì

Àwòrán obìnrin ní iwájú Tẹ́mpìlì Oquirrh Mountain Utah láti ọwọ́ Nexeo àti Matthew Reier

Ẹ̀bùn Tẹ́mpìlì Náà

Àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n ngbé ìgbé-àyé òdodo lọ sí tẹ́mpìlì láti gba àwọn ìlànà àti láti dá àwọn májẹ̀mú, tàbí ṣe àwọn ìlérí, pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìlànà kan tí a ngbà ní tẹ́mpìlì ni ẹ̀bùn tẹ́mpìlì. Ọ̀rọ̀ nàà ẹ̀bùn tẹ́mpìlì túmọ̀sí “ọrẹ kan.” Ẹ̀bùn tẹ́mpìlì jẹ́ ọrẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nínú ìlànà yí a kọ́ nípa ètò Bàbá Ọ̀run fún ìgbàlà wa, a sì dá àwọn májẹ̀mú láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Bí a bá jẹ́ olóòtọ́ sí àwọn májẹ̀mú tí a dá, Ọlọ́run á bùkún wa.

Àwòrán
tọkọ-taya ní iwájú tẹ́mpìlì

Àwòrán tọkọ-taya ti wọ́n nrìn ni Tẹ́mpìlì Manila Philippines láti ọwọ́ Cristina Smith

Síso Àwọn Ẹbí Papọ̀

Ìgbéyàwó kan ní tẹ́mpìlì bákanáà ni à npè ní èdìdí kan. Nígbàtí tọkọtaya bá ṣe èdìdí ní tẹ́mpìlì tí wọ́n sì pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́, wọn yíò wà papọ̀ láéláé. Bí wọ́n bá ní àwọn ọmọ, àwọn ọmọ náà yio jẹ́ dídí sí wọn. Àwọn òbí tí o ṣe èdìdí lẹ́hìn tí wọ́n ti bí àwọn ọmọ lè ṣe èdìdí pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Bí wọ́n bá gbé ìgbé-ayé òdodo, wọn yio jẹ́ ẹbí títí ayérayé.

Àwòrán
Ibi-ìrìbọmi Tẹ́mpìlì Lisbon Portugal

Àwòrán Ibi-ìrìbọmi Tẹ́mpìlì Lisbon Portugal láti ọwọ́Leslie Nilsson

Iṣẹ́ Tẹ́mpìlì fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run

A nṣe iṣẹ́ àkọsílẹ̀-ìtàn ẹbí láti wadi nípa àwọn bàbánlá wa. Lẹ́hìnnáà a nṣe iṣẹ́ tẹ́mpìlì ní ìtìlẹhìn wọn. A ṣe gbogbo àwọn ìlànà tí àwọn alààyè nílò: ìrìbọmi, ìfẹsẹ̀múlẹ̀, gbígba oyèàlúfà (fún àwọn ọkùnrin), ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, àti èdìdí. Wọ́n lè yàn bóyá wọ́n yio tẹ́wọ́gba àwọn ìlànà wọ̀nyí. Ní ọ̀nà yí, gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run lè gbádùn àwọn ìbùkún ìhìnrere.

Àwòrán
ẹbí ní iwájú tẹ́mpìlì

Àwòrán ẹbí ní iwájú Tẹ́mpìlì Philadelphia Pennsylvania láti ọwọ́ Cody Bell

Àwọn Ìbùkún Iṣẹ́ Tẹ́mpìlì

Bí a bá pa àwọn májẹ̀mú tí a dá nínú tẹ́mpìlì mọ́, a ó bùkún wa, dáàbòbò wá, a o sì fún wa ní okun. A ó ní agbára oyèàlùfáà pẹ̀lú wa. Àwọn ẹbí wa yio wà papọ̀ láéláé.

Tẹ̀mpìlì tún jẹ́ ibi àlàáfíà àti ìfihàn bákannáà. Bí a ti nṣiṣẹ́ tẹ́mpìlì, a lè gba ìtọ́sọ́nà ti-ẹ̀mí kí a sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run.

Tẹ̀