2022
Àwọn Májẹ̀mú Sowápọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run
Oṣù Kejì (Erele) 2022


“Àwọn Májẹ̀mú Sowápọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,” Làìhónà, Oṣù Kejì (Èrèlé) 2022

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà Oṣù Kejì (Èrèlé) 2022

Àwọn Májẹ̀mú Sowápọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run

Ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ nmú àwọn ìbùkún wa.

Májẹ̀mú ni ìlérí ní àárín Baba Ọ̀run àti àwọn ọmọ Rẹ̀. Ó ṣètò àwọn ipò fun àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Rẹ̀. Nígbàtí a bá ṣe ohun tí Ó béèrè, a ngba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún. Àti pe a kìí dédé gba àwọn ìbùkún ní ayé—nígbàtí a ba ṣe ti a sì pa àwọn majẹmu mọ, a ó padà láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn ẹbí wa ní ọ̀run ní ọjọ́ kan.

Àwòrán
ìrìbọmi

Àwọn Májẹ̀mú àti àwọn Ìlànà

A ṣe àwọn májẹ̀mú lákokò àwọn ìlànà kan. A ní láti gba àwọn ìlànà wọnnì kí a sì pa àwọn májẹ̀mú wọnnì mọ́ láti lè padà láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwọn ìlànà náà ní a ṣe nípasẹ̀ àṣẹ oyèàlùfáà. Àwọn ìlànà wọnnì pẹ̀lú ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀, gbígba Oyèàlùfáà ti Mẹlkisédékì (fun àwọn Ọkùnrin), àti àwọn ìlànà tí a gbà nínú tẹ́mpìlì. Lákokò oúnjẹ Olúwa, àwọn ọmọ ìjọ tún àwọn ìlérí tí wọ́n ti ṣe fún Ọlọ́run ṣe (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77, 79).

Àwòrán
oúnjẹ Olúwa

Àwọn Májẹ̀mú Ràn Wá Lọ́wọ́ láti Gbé Ìgbé-ayé Òdodo

Lákokò ìrìbọmi, a ṣe ìlérí láti tẹ̀lé Jésù Krístì, rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo, àti láti pa àwọn òfin mọ (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:37). Ọlọ́run ṣèlérí pé Ẹ̀mí Mímọ́ lè ma fi ìgbàgbogbo wà pẹ̀lú wa.

Nígbàtí àwọn ènìyàn bá gba oyèàlùfáà, wọ́n ṣèlérí láti gbé ní yíyẹ fún agbára oyèàlùfáà Ọlọ́run. Ọlọ́run ṣèlérí láti bùkún wọn. (Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:33–40.)

Àwòrán
Tẹ́mpìlì Brazil Recife

Ìjúwe Tẹ́mpìlì Brazil Recife nípasẹ̀ James Porter

Àwọn Májẹ̀mú ti A Ṣe ní tẹ́mpìlì

Nígbàtí àwọn ọmọ ìjọ bá gba ẹ̀bùn wọn nínú tẹ́mpìlì, wọ́n ṣèlérí láti gbé ní òdodo àti láti rúbọ fún ìhìnrere. Wọ́n jẹ́ agbára ìlérí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 38:32; 109:22).

Ní àkokò èdìdì tẹ́mpìlì, ọkọ àti aya ṣe ìgbéyàwó fún ayérayé wọ́n sì ṣèlérí láti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn àti sí Ọlọ́run. Ọlọ́run ṣèlérí pé wọ́n lè padà sọ́dọ̀ Rẹ̀ láti gbé bí àwọn ẹbí títíláé. (Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 132:19–20.)

Àwòrán
àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere

A jẹ́ Ènìyàn Májẹ́mu kan.

Àwọn ti wọ́n darapọ̀ mọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn di àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run. Bákannáà wọ́n jogún àwọn ìbùkún àti ojúṣe májẹ̀mú Ábráhámù (wo Gàlátíà 3:27–29). Jíjẹ́ ara àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run túmọ̀ sí pé a nran ara wa lọ́wọ́ bí a ti nsúnmọ́ Krístì. Bákannáà ó túmọ̀ sí pé a nṣiṣẹ́ láti fún Ìjọ Ọlọ́run lókun ní ilẹ̀-ayé. Nígbàtí a bá pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, a lè rí agbára àti okun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Tẹ̀