“Ọ̀nà Mẹ́rin tí Jésù Krístì Fi Nfún Yín Lókun,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Jan. 2023.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kínní 2023.
Ọ̀nà Mẹ́rin tí Jésù Krístì Fi Nfún Yín Lókun
Mo lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Krístì.
Àwọn Fílípì 4:13
Káàkiri ayé, àwọn krísténì yọ̀ nínú ìwé-mímọ́ yí: “èmi lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Krístì ẹnití ó nfagbára fún mi” (Àwọn Fílípì 4:13).
Nígbàtí àwọn ènìyàn gbọ́ èyí, díẹ̀ lára wọn lè rò pé ó túmọ̀ sí pé wọ́n lè yege nínú ìdánwò eyikeyi, jèrè ìdárayá eyikeyi, kí wọ́n gbogbo ìfẹ́ inú wọn sí wá sí ìmúṣẹ. Ṣùgbọ́n ìyẹn kìí ṣe ohun tí ìwé mímọ́ yí kọ́ni.
A kọọ́ nípasẹ̀ Àpóstélì Páùlù nígbàtí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n. Bí ẹlẹ́wọ̀n kan, àwọn ohun púpọ̀ wà tí Páùlù kò lè ṣe, ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé Jésù Krístì lè fún ohun lókun láti ṣe ohun tí ó pandandan jùlọ.
Ọ̀kannáà jẹ́ òtítọ́ fún yín!
1 Krístì Nfún Yín Lókun láti Mọ̀
Jésù Krístì ti fún yín ní onírurú àwọn ọ̀nà pàtàkì tí ẹ fi lè wá láti mọ óhun tí ó jẹ́ òtítọ́. Òun ti kọ́ gbogbo wa láti gbàdúrà nígbàgbogbo (wo 3 Nefi 18:18) kí a sì bèèrè láti mọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ (wo Moroni 10:4–5). Ẹ lè ri bákannáà kí ẹ sì mọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ yín.
Àdúrà àti àṣàrò ìwé mímọ́ nmú Ẹ̀mí wá sínú ayé yín. Ẹ̀mí lè sọ̀rọ̀ sí “iyè inú yín àti … ọkàn yín” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 8:2), “kún ẹ̀mí yín pẹ̀lú ayọ̀,” tí yíò sì “fi òye fún iye inú yín” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 11:13).
Nínú àwọm ọ̀nà wọ̀nyí, ẹ lè “gbọ́ Tirẹ̀”—gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà kí ẹ sì tẹ̀lé ohun tí Ó ti sọ. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé èyí ni “àwòṣe fún àṣeyege, ìdùnnú, àti ayọ̀ nínú ayé yí.”1
2 Krístì Nfún Yín Lókun láti Ṣe
Okun nwá sọ́dọ̀ yín bí ẹ ti ntiraka láti pa àwọn òfin mọ́ tí ẹ sì nṣe àwọn àṣàyàn rere tí ó ndarí sí àláfíà àti ìdùnnú. Jésù Krístì nfún yín lókun láti ṣe èyí àní nígbàtí àwọn àṣàyàn wọnnì bá le láti ṣe. Nígbàmíràn ẹ lè ṣe àṣàyàn búburú kan. Pẹ̀lú ọpẹ́, Ẹ̀tùtù Olùgbàlà nmú ìrònúpìwàdà ṣeéṣe. Nítorí ti Jésù Krístì, ẹ lè di mímọ́ kí ẹ sì rí ayọ̀. Ó lè fún yín lókun láti “ṣe dáradára si kí ẹ sì di dáradára si”2 ní ojojúmọ́.
3 Krístì Nfún Yín Lókun láti Borí
Nígbàtí ó wà lẹ́wọn, Páùlù kọ wípé: “nítorípé ipòkípò tí mo bá wà, mo ti kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn.
“Mo mọ̀ bí a ti iṣe di rírẹ̀-sílẹ̀, mo mọ̀ bí a ti íṣe di púpọ̀: ní ohunkóhun àti ní ohun gbogbo tí mo tí kọ́” (Àwọn Fílíppì 4:11–12).
Ní ọ̀nà míràn, Páùlù kọ́ pé, nípa Krístì, òun lè ṣẹ́gun kí òun sì kẹkọ látinú àwọn àdánwò àti ìpènijà. Jésù Krístì lè fún yín lókun láti ṣe bákannáà.
Olùgbàlà jìyà “àwọn ìrora àti ìpọ́njú àti àdánwò oníurú.” Ó gbé àwọn àìlera wa lé orí Ararẹ̀ kí “a lè mọ … bí a ó ti tù [èyí tí ó túmọ̀ sí láti ṣèrànwọ́] àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú gẹ́gẹ́bí àwọn àìlera wọn” (Alma 7:11–12). Ohun èyíówù kí ẹ dojúkọ, Jésù Krístì lè fún yín lókun láti faradà kí ẹ sì ṣe àṣeyọrí àwọn ohun tí ẹ kò ní lè ṣe fún ara yín.
4 Krístì Nfún Yín Lókun láti Dàbí
Jésù Krístì ti mú àjínde jẹ́ òdodo fún gbogbo wa, Ó sì mú ìyw` ayérayé ṣeéṣe fún àwọn tí wọ́n bá ronúpìwàdà, tí wọ́n gba àwọn ìlànà pàtàkì, tí wọ́n sì dá tí wọ́n sì pa àwọn májẹ̀mú tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú wọn. Láìsí Krístì, a kò lè mú ohun tí Baba Ọ̀run nfẹ́ jùlọ ṣẹ—fún wa láti dàbí Rẹ̀ àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì si, àti láti gbé pẹ̀lú Wọn ní ayérayé.
Ẹ lè dàbí Jésù Krístì si bí ẹ ti nkọ́ nípa Rẹ̀, gbáralé àti gbẹ́kẹ̀lé E, kí ẹ sì tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀. Èyí yíò darí yín láti gbé pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, sùúrù, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà mímọ́, àti ìgbọràn. Ìwọ̀nyí ni gbogbo ìhùwàsí Olùgbàlà.
Bí ẹ ti ntiraka láti tẹ̀lé Jésù Krístì, Òun yíò jẹ́ ìrètí àti ìmọ́lẹ̀ yí tí yíò tọ́ yín sọ́nà láti di gbogbo ohun tí Òun mọ̀ pé ẹ lè dà. Àti pé, pẹ̀lú Páùlù, ẹ yíò lè wí pé, “Mo lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Krístì.ẹnití o´ nfún mi lókun.”
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2023. Language. 18904 000