2023
Àwọn Ẹbí Wà Títíláé
Oṣù Kínní 2023


“Àwọn Ẹbí Wà Títíláé,” Làìhónà, Oṣù Kínní 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kínní 2023

Àwọn Ẹbí Wà Títíláé

Àwòrán
Ẹbí tó nrẹrin

Ẹbí ni kókó ẹ̀yà àwùjọ àti Ìjọ. Àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn gbàgbọ́ pé àwọn ẹbí wà títíláé. À nṣiṣẹ́ láti fún àwọn ẹbí wa lókun lórí ilẹ̀ ayé. Bákannáà a ní ìgbàgbọ́ pé a lè gba ìbùkún ẹbí ayérayé.

Ẹbí Jẹ ti Ọlọ́run

Gbogbo ènìyàn jẹ́ ọkùnrin àti obìnrin ẹ̀mí ti àwọn òbí ọ̀run. Gbogbo wa jẹ́ ara ẹbí Ọlọ́run. Gbogbo wa ní ìwà-ẹ̀dá tọ̀run àti àyànmọ́. Bí a bá gbé pẹ̀lú òdodo, a lè padà láti gbé pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run bí ara ẹbí Rẹ̀ títíláé.

Àwòrán
tọkọ-taya àṣẹ̀ṣẹ̀-gbéyàwó ní òde tẹ́mpìlì

Àwòrán ìgbeyàwó nípasẹ̀Joseph Kaluba

Àwọn Ẹbí Ayérayé

Nígbàtí ọkùnrin kan àti obìnrin ba ṣe ìgbeyàwó nínú tẹ́mpìlì tí wọ́n sì pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́, ìgbeyàwó wọn yíò wa títí ayérayé. Ìlànà tẹ́mpìlì yí ni à npè ní èdidì. Àwọn ọmọ tí a bí lẹ́hìn tí a bá ti ṣe èdidì fún àwọn òbí wọn ni a bí sínú májẹ̀mú náà. Àwọn ọmọ tí a bí ṣíwájú kí a tó ṣe èdidì fún àwọn òbí wọn ni a lè ṣe èdidì sí wọn nínú tẹ́mpìlì kí wọ́n lè jẹ́ ẹbí títíláé. Àwọn ọmọ ìjọ nṣe àkọọ́lẹ̀ ìtàn ẹbí àti iṣẹ́ tẹ́mpìlì kí wọ́n lè ṣe èdidì àwọn ẹbí wọn papọ̀ nínú gbogbo ìran. Ìbùkún ẹbí ayérayé kan ni a mú ṣeéṣe nítorí Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀.

Ìgbéyàwó

Ìgbeyàwó ní àárín ọkùnrin kan àti obìnrin ni a yàn láti ọwọ́ Ọlọ́run. Ìhìnrere Jésù Krístì nkọ́ àwọn ọkọ àti ìyàwó láti jẹ́ olótítọ́ sí ara wọn àti olódodo nínú ìgbeyàwó wọn. Wọ́n níláti jẹ́ òtítọ́ nínú èrò, ọ̀rọ̀, àti ìṣe. Ìgbeyàwó jẹ́ ìbáṣepọ̀ ọgbọọgbà, àti pé tọkọtaya níláti gbaníyànjú, tùnínú, àti ran arawọn lọ́wọ́.

Àwòrán
àwọn òbí pẹ̀lú ọmọ-ọwọ́

Àwọn Òbí àti Àwọn Ọmọ

Ọlọ́run páṣẹ fún Ádámù àti Éfà láti bí àwọn ọmọ. Àwọn olórí Ìjọ ti kọ́ni pé òfin yí ṣì ní ipá. Àwọn ìyá àti baba nṣiṣẹ́ papọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ nínú ìfẹ́ àti òdodo (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 68:25–28). Àwọn ọmọ ni à nkọ́ láti bú-ọlá àti láti gbọ́ran sí àwọn òbí wọn (wo Eksodu 20:12).

Kíkọ́ni àti Ikẹkọ

Àwọn òbí nkọ́ àwọn ọmọ wọn láti fẹ́ràn Ọlọ́run kí wọ́n sì gbọ́ran sí àwọn òfin Rẹ̀. Ìgbé ayé ẹbí nfún wa ní àwọn ànfàní láti ní ìmọ̀lára ayọ̀ àti láti kọ́ sùúrù àti àìnímọtaraẹni-nìkan. Àwọn ìwà wọ̀nyí nṣèrànwọ́ fún wa láti dà bíi ti Ọlọ́run si àti láti múra wa sílẹ̀ láti gbé pẹ̀lú ìdùnnú bí áwọn ẹbí títíláé.

Fífún Àwọn Ẹbí Lókun

Ó gba iṣẹ́, ìfọkànsì, àti sùúrù láti gbé ẹbí yíyege dìde. Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere bí irú ìgbàgbọ́, àdúrà, ìdáríjì, ìfẹ́, iṣẹ́, àti eré dídára lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ nínú ìgbé ayé ẹbí. Bákannáà a lè gba ìfihàn araẹni láti mọ̀ bí a ó ti fún àwọn ẹbí wa lókun.

Àwòrán
àwòrán ti Jésù Krístì

Àwòrán Krístì, nípasẹ̀ Heinrich Hofmann

Àwọn Ìbùkún Wà Fún Gbogbo Ènìyàn

Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni ó ní ànfàní láti jẹ́ ara ìbójúmu ẹbí nihin ní orí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣe ìlérí pé gbogbo ẹni tí ó bá pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ yíò gba gbogbo àwọn ìbùkún ẹbí ayérayé. A lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ kí a sì ní ìgbàgbọ́ nínú àkokò Rẹ̀.

Tẹ̀