2023
Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni Nfún Wa Lókun
Oṣù Kẹ́jọ 2023


“Ìgbẹ́kẹ̀lé-Araẹni Nfún Wa Lókun,” Liahona, Aug. 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹ́jọ 2023

Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni Nfún Wa Lókun

Àwòrán
àwọn ènìyàn méjì nfọ àwo

Jíjẹ́ olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni túmọ̀ sí pé a lè ṣètọ́jú fún àwọn àìní ti arawa àti àwọn ẹbí wa. Nígbàtí a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni, bákannáà a ó lè sin Olúwa kí a sì tọ́jú àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni kò túmọ̀ sí pé a nílò láti dá kojú àwọn ìpènijà wa. A lè bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí, wọ́ọ̀dù tàbí àwọn ọmọ ẹ̀ka, àti àwọn amòye nígbàtí a bá nílò rẹ̀.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìgbẹ́kẹ̀lé-Araẹni

Dída olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni nílò ẹ̀kọ́, ìgbọ́ran, àti ìṣẹ́ àṣekára. À ó sa ipá wa láti tọ́jú arawa, a sì lè bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn fún ìrànlọ́wọ́ nígbàtí a bá nìlò. Láti di olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni nítòótọ́, bákannáà, a gbọ́dọ̀ kọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Nígbànáà bí a ti nṣiṣẹ́ láti ran arawa lọ́wọ́, Òun ó fún wa lókun.

Àwòrán
ọwọ́ méjì tí a ká pọ̀

Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni Ti-ẹ̀mí

A lè gbé ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ti-ẹ̀mí wa ga nípa ṣíṣe iṣẹ́ láti fún ẹ̀rí wa lókun ti Jésù Krístì. À nṣe èyí bí a ti ngbàdúrà, ṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́, lọ sílé ìjọsìn, gbọ́ran sí àwọn òfin, kí a sì ṣe àwọn ohun míràn tí ó nmú wa súnmọ́ Krístì. Mímọ́ pé Òun nfẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ yíò fún wa ní ìgbàgbọ́ láti dúró pẹ̀lú agbára àní nígbàtí ìgbé-ayé bà nira.

Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni Ti-ara

Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ti-ara pẹ̀lú lílè tọ́jú àwọn àìní àfojúrí ti arawa àti ẹbí wa. Èyí pẹ̀lú oúnjẹ, òrùlé, ìlera, àti àwọn àìní míràn. À nṣe èyí nípa gbigba ẹ̀kọ́ rere, ikẹkọ tàbí gbígbòòrò àwọn iṣẹ́ tí a nílò, ṣíṣe iṣẹ́ kára, lílo àkókò wa pẹ̀lú ọgbọ́n, àti ṣíṣe àkóso owó wa dáadáa.

Àwòrán
àwọn obìnrin mẹta nrìn papọ̀

Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni Ẹ̀dùn-ọ̀kàn

Ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni Ẹ̀dùn-ọ̀kàn ni agbára láti gba àwọn ìpènijà ẹ̀dùn-ọkàn mọ́ra pẹ̀lú ìgboyà àti ìgbàgbọ́. Gbogbo wa ní àwọn ìpènijà àti ìfàsẹhìn. Ọpẹ́ fún ìhìnrere, a mọ̀ pé a lè yàn bí a ó ti fèsì sí wọn. Fífèsì pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Olúwa nmú agbára wa láti kojú àwọn nínira míràn pẹ̀lú ìrètí síi.

Ẹ̀kọ́

A níláti máa kọ́ ẹ̀kọ́ nígbàgbogbo. Ọlọ́run nfẹ́ kí a kọ́ iye-inú wa lẹ́kọ́ kí a sì gbèrú àwọn iṣẹ́ wa ní gbogbo ìgbé-ayé yí àti sí èyí tó nbọ̀. Bí a ti nkẹkọ síi, bẹ́ẹ̀ni a lè ní ipa dídára fún rere si kí a sì pèsè fún arawa, ẹbí wa, àti àwọn wọnnì nínú àìní.

Àwòrán
Ọ̀dọ́mọkùnrin ngbé àpò kan

Àwọn ìbùkún ti Jíjẹ́ Olùgbẹ́kẹ̀lé-araẹni

Àwọn wòlíì ti kọ́ni pé bí a ti ngbèrú ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni wa, a ó di alábùkún pẹ̀lú ìrètí àti àláfíà pùpọ̀si. A ó le ran àwọn ẹbí wa lọ́wọ́ àti àwọn ẹlòmíràn nínú àìní. A ó sì di alábùnkúnfún pẹ̀lú àwọn ànfàní àti pẹ̀lú ìlèṣe láti tẹ̀síwájú láti ní ìlọsíwájú.

Àwọn Ohun-èlò Ìjọ

Èèkan yín lè fúnni ní àwọn ẹgbẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni. Ìwọ̀nyí lè kọ́ yín ní àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni àti àwọn iṣẹ́ bíi ṣíṣe àkóso owó yín tàbí wíwá iṣẹ́ dídárajù. Ẹ lè rí àwọn ìbámu ohun-èlò nínú Yàrá Ìkàwé Ìhìnrere. Yan “Àwọn Ìwé àti Ẹ̀kọ́” àti nígbànáà “Ìgbẹ́kẹ̀lé-Araẹni.”

Tẹ̀