“Wá Òye,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹfà 2023.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹ́jọ 2023
Wá Òye
Láti inú ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ti Oṣù Kẹ́rin 2019.
Èrèdí wa bí a ti nwá òye ìhìnrere Jésù Krístì gbúdọ̀ jẹ́ láti ní àlékún ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti nínú ètò ìdùnnú tọ̀run Rẹ̀ àti nínú Jésù Krístì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ àti láti ṣàṣeyege ìyípadà pípẹ́. Irú àlékún ìgbàgbọ́ àti ìyípadà bẹ́ẹ̀ yíò ràn wá lọ́wọ́ láti dá àti láti pa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, bayi kí a fún ìfẹ́ wa lókun láti tẹ̀lé Jésù àti láti mú iyípòpadà ti-ẹ̀mí rere jáde. Ìyípòpadà yí yíò mú ìdùnnú, àbájáde, àti ayé ìlera wá síi yíò sì ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìwò ayérayé wa dúró.
Láti ṣe àṣeyege èyí, a nílò láti gbé nínú Jésù Krístì nípa ríri ara wá sínú àwọn ìwé-mímọ́, yíyayọ̀ nínú wọn,kíkọ́ ẹ̀kọ́ Rẹ̀, àti títiraka láti gbé ní ọ̀nà tí Ó ti gbé. Nígbànáà nìkan ni a lè mọ̀ Ọ́ kí a sì da ohùn Rẹ̀ mọ̀, ní mímọ̀ pé bí a ti nwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tí a sìn ngbàgbọ́ nínú Rẹ̀, a kò ni pebi tàbí pòhùngbẹ (wo Jòhánnù 6:35).
Èyí kìí ṣẹlẹ̀ lásán. Fífi arawa sí ìbámú sí ipa gígajùlọ ti ìwàbí-Ọlọ́run kìí ṣe ọ̀ràn ìrọ̀rùn; ó gba pípe Ọlọ́run àti kíkọ́ bí a ó ti mú ìhìnrere Jésù Krístì sí gbùngbùn ìgbé ayé wa.
Mo jẹri sí yín pé nígbàtí a bá fi taratara, tọkàntọkàn, gbọingbọin, àti òtítọ́ wá láti ní òye ìhìnrere Jésù Krístì àti láti kọ́ ọ sí ara wa pẹ̀lú èrèdí òdodo àti lábẹ́ ipa Ẹ̀mí, àwọn ìkọ́ni wọ̀nyí lè yí àwọn ọkàn padà kí ó sì mísí ìfẹ́ láti gbé gẹ́gẹ́bí àwọn òtítọ́ Ọlọ́run.
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹjọ 2023 2023. Language. 19046 000